Sunday Igboho: Mi ò lè ṣe àkọlù sí bàbá mi Alake nítorí wọ́n jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn èèyan tí a kò fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nílẹ̀ Yoruba

egba

Oríṣun àwòrán, @TheReal_Hafeez

Gbajugbaja ajafẹtọ ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti gbogbo eeyan mọ si "Sunday Igboho" ti ṣalaye pe oun ko le ri awọn agbaagba fin, ki a tọ sọ pe awọn Ọba alade nilẹ Yoruba.

Ọrọ yii ni ẹsi ti Igboho fọ lori ẹsun ti awọn eeyan kan fi kan an wi pe o n gbero lati ṣe ikọlu si aafin Alake nilu Abẹokuta.

O ni ki ẹnikẹni ma ṣe ṣi oun gbọ nitori ko si ninu aṣa oun lati maa ri awọn agbalagba ati Ọba alade ilẹ Yoruba fin, nitori a ko gbudọ fi ọwọ yẹpẹrẹ mu aṣa ilẹ wa.

Ninu atẹjade to fi ranṣẹ si awọn oniroyin lati ọwọ alamọran rẹ lori iroyin, Dapo Salami, Igboho ni, "Emi Sunday Igboho, mi o le ri awọn agbaagba ati Ọba ilẹ Yoruba fin."

Oríṣun àwòrán, @TheNationNews

"Baba ni Alake jẹ si mi, o si jẹ ẹnikan ti mo bu iyi fun gan an. Mi o le ṣe ikọlu si baba mi nitori wọn jẹ ọkan ninu awọn eeyan ti a ko le fi ọwọ rọ sẹyin ninu ẹya Yoruba".

"Mo si mọ wi pe baba naa yoo ṣe atilẹyin fun wa lati de ibi ilepa wa".

Atẹjade naa ṣalaye ni kikun pe ko si otitọ kankan ninu ẹsun ti wọn fi kan oun wi pe Igboho n gbero lati ṣe ikọlu si aafin Alake ti ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ.

Sunday Igboho rọ gbogbo eeyan lati kọ eti ọgbọin si awọn iroyin to n tọka rẹ wi pe oun n gbero lati ri agbalagba kan tabi Ọba alade fin, nitori ifojusun gbogbo ilẹ Yoruba ni lati da duro.

Àkọlé fídíò,

Omi iké kan, l'èèyàn kan lè mu f'ọ́jọ́ mẹ́ta láì ro ti ekòló inú rẹ̀ - Ìlú Elega, Kwara

Ẹ̀yìn taa ni Alake ti Egba tò sí lórí ọ̀rọ̀ Oduduwa Nation tí Sunday Igboho sọ?

Oríṣun àwòrán, Alake of Egba land

Alake ti ilẹ Egba, Oba Adedokun Aremu Gbadebo Okukenu kẹrin ti fi ọrọ lede pe ohun ti awọn iwe iroyin kan to lorukọ lorilẹede Naijiria n gbe nipa iha ti oun kọ si Sunday Igboho lori ọrọ Oduduwa Republic ko ri bi wọn ṣe n kọ ọ rara.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun Kabiyesi fi sita, Oloye Zents Kunle Sowumi to jẹ Baba Tayese ti ilẹ Egba ṣalaye pe awọn iwe iroyin kan n kọ iroyin kiri pe lasiko ti ẹgbẹ awọn awakọ Naijiria, NTREAN ṣe abẹwo si aafin Ake ni Abeokuta ni oun kẹnu ọrọ si ajafẹtọ ilẹ Yoruba, Sunday igboho lori ọna ti iran n tọ bayii.

"Kabiyesi n fẹ lati fi to gbogbo eeyan leti wipe iru ọrọ bayii ko jẹ jade rara nigba ti NTREAN wa bẹ afin mi wo mo si fẹ ki gbogbo ara Egba ati ilẹ Yoruba kọ eti ikun si iru iroyin bayii eyi tawọn iwe iroyin Punch, Sahara Reporters atawọn mii n gbe".

Kabiyesi ni iṣẹ̀ awọn ọta Egba leyii lori ohun to jẹ pe awọn baba nla baba wọn gan duro fun latayedaye nigba ti Lisabi Agbogbo Akala ja fitafita lati gba ilẹ Egba lọwọ ijọba Oyo.

Atẹjade naa ni "bi Kabiyesi ba tilẹ wa fẹ sọrọ si iru nkan to ṣe pataki si imọlara awọn eeyan rẹ, kii ṣe ni iru apejọpọ pẹlu ẹgbẹ awọn awakọ ni yoo ti sọ ọ".

Oríṣun àwòrán, Zents Oyekunle Sowumi

O ni Kabiyesi yoo kọkọ tọ awọn igbimọ alaṣẹ ilẹ Egba lọ, awọn Ogboni to fi mọ awọn oriṣa atawọn alalẹ ilẹ gbogbo ni ilana aṣa ilẹ Egba ko to ṣe iru nkan bẹẹ.

Alake ti Egba wa n rọ gbogbo ara Egba nile ati lẹ́yìn odi pe ki wọn mọ ọmọ ẹni ti wọn n ṣe paapaa nipa pe ki wọn ma gbagbe itan wọn ki wọn si kọ eti ọgbọin si awọn alahesọ tabi ileeṣẹ iroyin to ba ri Ọba Alake ti ilẹ Egba fin lọna ti wọn n gba kọ iroyin wọn.

Àkọlé fídíò,

Taooma: Ìbáṣepọ̀ mi pẹ̀lú àwọn òbí mi yàtọ̀ sí bí mó ṣé n polongo nínú fídíò mi