Oba Tajudeen Omotayo ti Imope gbà ìtúsíẹ̀ lọ́dọ̀ ajínigbé amò wọ́n gba owó wọ́n tún fìyà jẹ ẹ́

Ọba Imope

Oríṣun àwòrán, Oba Tajudeen Omotayo

Kabiyesi Ọba Tajudeen Omotayo, ori ade ti ilu Imope ti gba itusilẹ lọdọ awọn ajinigbe ṣugbọn ko ba ọfẹ de.

Olori Omotayo Adesola iyawo Kabiyesi to fidi ọrọ yi mulẹ fun ileeṣe BBC sọ pe lalẹ ọjọ Iṣegun ni Kabiyesi de ati pe awọn san owo idoola ẹmi.

Ninu alaye ti wọn ṣe olori ni lootọ ni Kabiyesi gba itusilẹ ṣugbọn awọn ajinigbe yi fi iya jẹ wọn ki wọn to tu wọn silẹ.

Yatọ si iya ti wọn fi jẹ Kabiyesi o ni wọn tun bere owo idoola ọgọrun miliọnu Naira lọwọ awọn amọ gbogbo ohun tawọn ri ko jọ ni wọn gba.

''Wahala wa o, Kabiyesi o le da rin bi wọn ṣe de. Wọn na wọn gaan koda ile iwosan ni wọn wa bayi''

O fi kun pe owo tawọn ṣa jọ pada pe perepere ki awọn ajinigbe naa to pada tu Kabiyesi silẹ

''Wọn gba owo lọ. Wọn gba owo naa to pe. Wọn gba owo lọ''

Lati ọjọ Abamẹta to kọja lawọn ajinigbepawo ti gbe Kabiyesi ti wọn si ni ki mọlẹbi wọn mu igba miliọnu Naira wa.

Lẹyin idunadura wọn ni ki wọn mu ọgọrun miliọnu Naira wa.

Ọlọpaa lawọn ko mọ si boya mọlẹbi san owo idoola fun ajinigbe

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun arakunrin Abimbola Oyeyemi sọ pe lootọ ni wọn tu Kabiyesi silẹ ati pe awọn lawọn ṣe to itusilẹ rẹ.

Oyeyemi ni ọga ọlọpaa iyẹn Kọmisana ipinlẹ Ogun fun ara rẹ ko dakẹ lori itusilẹ Oba ki wọn to pada gba idande.

Nigba ti BBC beere boya awọn ọlọpaa doju ija kọ awọn ajinigbe naa ni ki wọn to tu Kabiyesi silẹ, o ni ''a ko le tu aṣiri baa ti ṣe n ṣiṣẹ wa''.

Bakan naa lo sọ pe ohun ko le dahun si ibeere nipa boya awọn ajinigbe naa gba owo lọdọ mọlẹbi Kabiyesi.

O ni ohun to ṣe pataki ni pe awọn ti doola ẹmi ẹni ti wọn jigbe ati pe iṣẹ ṣi ku tawọn yoo ṣe lẹyin igba yi.

''Nitori pe a ti ribi doola ẹni ti wọn jigbe ko tunmọ si pe a ko ni ṣapa lati wa awọn to hu iwa yii.''

''Arọwa wa si awọn mọlẹbi kàn ni pe ki wọn ma ṣe san owo idoola fawọn ọdaran wọnyii mọ''.