Penis size by Dr Shanna Swan: Kí ló ń fa kí ǹkan ọmọkùnrin yorò?

Ki lo n jẹ ki nkan ọmọkunrin kere?

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Onimọ Sayẹnsi nipa ọrọ ayika ti fi hande pe nkan ọmọ ọkunrin eeyan maa n yoro ti awọn agbegbe rẹ ko si ni ṣara jọ nitori ti ayika eeyan.

Dokita Shanna Swan sọ ninu iwe tuntun rẹ to kọ ti akọle rẹ n jẹ "Count Down" sọ pe ọmọ eniyan n doju kọ iṣoro iloyun ati ibimọ latari kẹmika kan ti wọn n pe ni "phthalates" to n fa ki wọn bi ọmọ ikoko pẹlu nkan kunrin tabi obinrin ti ko ṣara jọ daadaa.

Ninu iwe naa, arabinrin Shanna ṣagbeyẹwo bi wọn ṣe n fi ọwọ yẹpẹrẹ mu iye atọ ọmọkunrin to n jade eyi to maa ṣakoba fun idagbasoke ilana ibimọ ọkunrin ati obinrin to si n ko ọjọ iwaju sinu ewu.

Latari idọti ayika nkan ọmọkunrin tabi obinrin yii, awọn ọmọ ti wọn n bi ti nkan ọmọkunrin wọn kere ti n pọ sii.

Àkọlé fídíò,

'Èmi àti ìyàwó mi ti ń gbé pọ̀ nínú ìgbéyàwó wa fún 60 years', ẹ wá kọ́ ẹ̀kọ́ lẹ́nu àgbà méjì

Iwadi Dokita Swan fihan gẹgẹ bi wọn ṣe fi awọn ekute ṣe ayẹwo kẹmika phthalate ọhun ti wọn si rii pe nigba ti wọn fi ṣi ara ọmọ oyun inu wọn si kẹmika naa, o da bii pe wọn yoo bi awọn ọmọ naa pẹlu nkan ọmọ ọkunrin konkolo.

O wadii pe awọn ikoko ọkunrin ti ara wọn ba ni nkan ṣe pẹlu phthalates ninu oyun maa n ni awọn nkan to rọ mọ nkan ọmọkunrin kukuru.

Kẹmika naa ni iṣẹ to n ṣe ni awọn ileeṣẹ ti wọn fi n mu ki ike rọba fẹlẹ sii ṣugbọn Dokita Swan ni awọn kẹmika naa ti n wọ inu awọn nkan iṣere ati ounjẹ to si n ṣakoba fun idagbasoke eeyan.

Ki lo n jẹ ki nkan ọmọkunrin kere?

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ki ni itumọ kẹmika Phthalate to n mu nkan ọmọkunrin kere?

Phthalates jẹ akojọpọ awọn kẹmika ti wọn fi ṣe nkan elo pupọ bii iṣere ọmọde, nkan ti wọn n lẹ mọlẹ, lẹ m ogiri, ọṣẹ, ọili, nkan iko ounjẹ si, awn nkan ilera, apo ẹjẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Wọn maa n lo o ninu awọn oun elo aṣaraloge bii kẹmika ti wọn fi n nu eekana, iparun, ipa abiya lẹ́yìn fifa irun ibẹ, ọṣẹ iwẹ, ọṣẹ ifọrun, lọfinda ati bẹẹ lọ.

Wọn maa n lo o lati mu polyvinyl chloride, iyẹn ike rọba ti wọn si tun nlo bii amu nkan yọ ninu awọn ipara.

Ninu akọsilẹ iwe kan ti awọn onimọ Sayẹnsi tun fi si ori ayelujara Medical news website, wọn ṣalaye awọn idi mii to fi le mu nkan ọmọ ọkunrin kere sii.

Ki lo n jẹ ki nkan ọmọkunrin kere?

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ki lawọn nkan mii to le mu ki nkan ọmọkunrin kere sii?

Ki nkan ọmọkunrin maa kere wọpọ paapaa bi awọn ọkunrin ba ṣe n dagba si ṣugbọn awọn idi mii naa wa to le fi yoro.

Ọjọ ori

Bi ọkunrin ba ṣe n dagba sii, awọn nkan ọlọra to wa ninu ara wn a maa ṣa ara jọ ninu awọn nkan to maa n pin ẹjẹ kaakiri ara yoo si mu ki eyi dinku.

eleyi maa mu ki awọn sẹẹli iṣan ara to wa nibi ohun to n mu nkan ọmọ ọkunrin le bẹrẹ si ni ṣaarẹ. Awọn tuubu to n mu nkan ọmọkunrin le maa ṣiṣẹ karakara ti ẹjẹ ba n wọ ibẹ daadaa torinaa bi ẹjẹ naa ba ti dinku, o tumọ si pe nkan ọkunrin naa ko ni maa fibẹẹ le ni gbogbo igba.

Ki lo n jẹ ki nkan ọmọkunrin kere?

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Sisanra

Ipa ti sisanra n ko paapaa ni agbegbe ikùn jẹ pabanbari fun ọpọlọpọ awọn ọkunrin bi wọn ba ṣe n dagba.

Bo til jẹ pe nkan ọmọkunrin le fara han bii kekere nitori sisanra, amọ o le ma yoro. idi ti yoo fi jọ pe o kere ni pe ara ogiri ikun ni ibẹrẹ nkan ọmọkunrin wa bi ikun ba si ti n tobi sii, yoo fa nkan ọmọkunrin naa sinu. Bi eeyan ba wa jo lara, nkan ọmọkunrin rẹ yoo pada bọ sipo ati bo ṣe tobi si tẹlẹ.

Iṣẹ abẹ abẹ́ ọmọkunrin

Iwadii kan ninu Journal of Impotence Research fihan pe bi ọkunrin ba ni aisan jẹjẹrẹ abẹ, ti wọn si fẹ ṣe iṣẹ abẹ eyi ti wọn n pe ni radical prostatectomy, o lee ni iriri ki nkan ọmọkunrin rẹ kere

Oogun lilo

Awọn oogun kan wa to lee fa ki nkan ọmọkunrin kere. Awọn oogun bii Adderall ti wọn maa n lo fun ẹni ti iṣe féfé rẹ ba ti kọja ala, bakan naa awọn oogun to n wo iporuru ọkan san, oogun to n wo arun ọpọlọ san atawọn oogun mii ti dokita ba pe fun itọju abẹ wiwu.

Siga Mimu

Ni ọdun 1998, fasiti oniṣegun ti Boston ṣe ayẹwo nkan awọn ọkunrin igba to dide duro tandi. Abajade ayẹwo naa fihan pe, awọn to n mu siga, ti nkan ọmọkunrin wọn ba dide, o maa n kuru ju ti ẹni ti ko mu siga lọ.

Idi si ni pe kẹmika to n jade lasiko ti wọn ba n fa siga simu lee ṣe ọna ti ẹjọ n gba lọ inu nkan ọmọ ọkunrin leṣe. O si lee dena ki ẹjẹ kun inu nkan ọmọkunrin naa eyi ti yoo fi dide.

Lai wo ti miu ara ya ati ipa to n ko ninu ọpọlọ, bi ohun to n pin ẹjẹ kiri ba ti bajẹ, nkan ọmọkunrin ko le duro ko si ni le tandi.