Leah Sharibu bímọ kò bímọ, òhun tí ìwádìí fihàn rèé nipa akẹ́kọ̀ọ́ Dapchi táwọn agbébọn jígbé

Leah Sharibu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Leah Sharibu ti bimọ mii lahamọ to wa?

O da wa loju pe ibeere yi lo wa lọkan yi nipa akẹkọọ ileewe Dapchi tawọn Boko Haram ji gbe lati oṣu Keji ọdun 2018.

Lori iroyin to gbode yi, BBC kan si baba to bi ọmọbinrin akẹkọọ yi, Nathan Sharibu to si sọ nipa ohun to mọ boya lootọ ni Leah ti bimọ keji ni ahamọ Boko Haram.

Ka ti bi pẹlẹbẹ mu ọọlẹ jẹ.

Lọjọ Iṣẹgun, ajọ ajafẹtọmọniyan kan to wa ni orileede Amẹrika n kẹdun bi wọn ti ṣe pa Leah Sharibu ti si ahamọ awọn Boko Haram latijọyi.

O ni akikanju ọmọbinrin ẹlẹsin Kristẹni yi ni iroyin tẹ awọn lọwọ pe o ti bimọ ẹlẹkeeji si ahamọ.

Àkọlé fídíò,

Ojojumọ n'inu awọn ẹbi n bajẹ lori ikọlu Dapchi

BBC ko ribi fidi ọrọ yi mulẹ boya lootọ lo ṣẹlẹ bẹẹ amọ a kan si baba to bi Leah Sharibu, Nathan Sharibu.

Pẹlu ibanujẹ ọkan o sọ fun wa nirọlẹ Ọjọru pe ''Ahesọ ni ọrọ naa''.

O sọ pe oun ko ti gbọ nkankan nip ape ọmọ rẹ bi ọmọ lahamọ awọn agbesunmọmi yi.

O ni lati igba ti wọn ti ji Leah gbe, oun ko gbọ nkankan lati ọdọ rẹ ati awọn to jiigbe.

Oríṣun àwòrán, Twitter

Arakunrin Nathan tẹsiwaju pe lọpọ igba lawọn ijọba apapọ ti ṣeleri fun oun pe awọn yoo doola ọmọ rẹ kuro lahamọ to wa.

''Mo ti parọwa si wọn lọpọ igba ṣugbọn titi di asiko yi pabo lo ja si. Mio ti ẹ wa mọ nkan ti mole sọ fun wọn mọ.''

Orisirisi iroyin lo gbode nipa Leah Sharibu lati igba ti wọn ti ji i gbe ni ọdun 2018.

Ni oṣu kini awọn ileeṣẹ iwe iroyin Naijiria kan sọ pe Leah loyun fun ọgagun Boko Harm kan ti eyiun si ti ti gbe ekuro ni Naijiria.

Lọjọ Kọkandilogun oṣu Keji 2018 ni awọn Boko Harm ji Leah ati awọn akẹgbẹ rẹ obinrin mi gbe nileẹkọ Dapchi towa ni Yobe.

Lẹyin igba naa ni ijọba apapọ ri bi doola awọn ọmọbinrin yi ṣugbọn wọn kọ lati fi Leah silẹ nitori pe o ni oun ko ni yi ẹsin oun pada di musulumi.

Loṣu Kẹjọ ọdun 2019, ijọba Naijiria sọ pe Leah ṣi wa laaye. Nigba taa n wi yi, agbẹnusọ aarẹ Buhari, Garba Shehu ni ọjọ ko ni simi ayafi ti wọn ba ri Leah da pada wa sile.