Bola Tinubu: Ọ̀pọ̀ ní ìpolongo ìbò 2023 ni Tinubu ń ṣe pẹ̀lú ₦50m tó fàwọn oníṣòwò Katsina

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Bola Tinubu

Oriṣiiriṣii ọna lawọn eeyan fi wo igbesẹ eekan ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu to gbe aadọta miliọnu naira fawọn oniṣowo ti ṣọọbu wọn jona ni ipinlẹ Katsina .

Eleyii jẹ owo iranwọ fawọn ontaja naa to ti padunu dukia iyebiye ninu ijamba ina to ṣẹlẹ.

Awọn kan sọ lori ayelujara pe aluwala ologbo, ọgbọn ati ko ẹran jẹ naa ni gbogbo rẹ.

Eleyii tumọ si pe owo ti Tinubu gbe kalẹ niṣe pẹlu ipolongo oṣelu ṣaaju ibo aarẹ ọdun 2023.

Omooba Adejuyigbe Isaiah TaiyeTaiwo lori ikanni BBC Yoruba ni Facebook pe ko si ibi ti Tinubu n lọ ninu ibo 2023 to ba tiẹ dije fun ipo aarẹ gan an.

O beere wi pe elo ni Tinubu kede gẹgẹ bi owo iranwọ fawọn to ku nibi iṣẹlẹ Lekki Tollgate lọdun 2020?

Ọgbẹni Taiwo tiẹ lọ si inu iwe mimọ lori ọrọ naa lẹyin to sọ pe ''gbogbo aisododo, ẹsẹ ni.''

Ọgbẹni Joseph Olatunji ati Folakemi Oyeyipo ni ti wọn sọ pe ohun to da Tinubu atawọn oniṣowo katsina pọ naa ni yoo tu wọn ka.

Awọn tiẹ n beere lọwọ Tinubu wi pe kilode ti ko ṣe iranwọ owo fawọn oniṣowo ọjọ Ṣasha niluu Ibadan ti awọn padanu ọja wọn lẹyin rogbodiyan to waye nibẹ.

Bosede Comfort Ilesanmi naa sọ pe kinni Tinubu ṣe fawọn eeyan Yewa ipinlẹ Ogun ti wọn lọ ṣatipo lorilẹede Benin Republic lẹyin ikọlu awọn Fulani.

Amọ, ero Kamal Kamaldeen tayọ ni tiẹ, oun gbagbọ pe Tinubu yoo jẹ aarẹ orilẹede Naijiria laṣẹ Edumare lọdun 2023.

Ẹwẹ, ṣaaju ni iroyin kan ti kọkọ sọ pe Tinubu ṣe abẹwo si ipinlẹ Katsina laarọ Ọjọru, nibi to ti parọwa si awọn oniṣowo naa lati maṣe ba ọkan jẹ lori iṣẹlẹ ọhun.

Ọpọ ọja lo jona ninu iṣẹlẹ naa, eyii to mu ki ijọba ipinlẹ ọhun gbe iwadii dide lati mọ ohun to ṣokunfa ina naa.