Buhari Medical Tourism: Kí lẹ̀ ń bú ààrẹ fún nígbà tọ́pọ́ òṣìṣẹ́ ìlera ń ṣe owó ìṣúná wọn báṣubàṣu

Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter

Agbẹjọro ati ajafẹtọ ọmọniyan, Kayode Ajulọ ti bu ẹnu atẹ lu awọn ti wọn n sọrọ odi si aarẹ Buhari nitori pe o lọ si ilu London lati lọ gba itọju.

Ajulọ ni aarẹ Buhari ni aṣẹ labẹ ofin ọdun 1999 ni Naijiria lati jade tabi wọle si orilẹede Naijiria, to fi mọ ilẹ okeere lati lọ gba itọju.

O fikun pe, aarẹ Buhari yoo ti ro o daadaa ki o to tẹsiwaju lati sọ fun awọn ọmọ Naijiria wi pe oun fẹ lọ isinmi ọṣẹ meji lati gba itọju fun ara rẹ lai pa irọ fun awọn ọmọ Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

''Ti aarẹ Buhari ba ni oun lọ fun ọlide, ta lo le e da duro tabi oun fẹ lọ ṣepade pẹlu eniyan kan ni Ilu Ọba?''

''Amọ o sọ otitọ fun awọn ọmọ Naijiria, nitori naa ko yẹ ki wọn bu ẹnu atẹ lu.''

Àkọlé fídíò,

Akomolede àti Asa: Ìyàtọ̀ tó wà láàrin ìlànà ìpolówó ọjà láyé àtijọ́ àti òde òní

Bakan naa lo ni ofin orilẹede Naijiria ko le e kan ni ipa fun ẹnikẹni lati duro si orilẹede rẹ lati gba iwosan ti o ba ni anfaani ati ọre ọfẹ lati lọ gba eto iwosan to peye.

Ajulọ fikun un pe eto ilera lorilẹede Naijiria ti dẹnukọlẹ to fi mọ eto ẹko ati eto irinna lorilẹede Naijiria.

''Amọ kii ṣe ijọba nikan lo jẹbi bi ohun gbogbo ṣe dẹnukọlẹ nitori lọpọ igba ni awọn adari eto ilera ko le e sọ pato bi wọn ṣe n ṣe owo ti ijọba n fun ẹka naa.

Àkọlé fídíò,

Onpetu Ijeru: Akala ní torí Aláàfin kò ṣúgbàá òun fún sáà kejì, ló ṣe ní kí pín ipò alága

Lori awọn dokita ti wọn fẹ gunle iyanṣelodi,atunṣe gbọdọ ba ẹka naa, ki awọn alaṣẹ si naani ẹmi awọn eniyan ati oṣiṣẹ wọn.

Aarẹ Buhari to lọ fun isinmi oloṣẹ meji naa ni yoo pada si Naijiria ni ọsẹ keji, Osu Kẹrin, ọdun 2021.

Wo ìgbà mẹ́fà tí Buhari rìnrin àjò lọ sókè òkun fún ìtọ́jú ara rẹ̀

Igba akọkọ kọ ni yii ti aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari yoo lọ si Ilẹ Gẹẹsi lati lọ gba eto ilera to peye.

Oríṣun àwòrán, Instagram/Bashir Ahmad

Eleyii ko ṣẹyin ikede ijọba apapọ pe Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari n lọ si ilu London lati lọ gba itọju fun isinmi ọlọsẹ-meji.

Ileeṣẹ ijọba ni Ọjọ Iṣẹgun, Ọgbọnjọ Oṣu Kẹta, ọdun 2021 ni aarẹ Buhari yoo ma a rin irinajo naa.

Wọn yii ni igba mẹ́fà ti Aarẹ Buhari lọ gba itọju nilẹ okeere

Ọjọ karun un oṣu keji, ọdun 2016

Ni bi oṣu mẹjọ to bẹrẹ ijọba gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Naijiria, Aarẹ Buhari rinrin ajo lọ si ilu London lọjọ karun un oṣu keji ọdun 2016.

Atẹjade lati ileeṣẹ ijọba ṣalaye pe ọrọ ara Buhari lo mu gunle irinajo naa.

O pada si Naijiria lati irinajo naa lọjọ kẹwaa oṣu keji ọdun 2016.

Ọjọ kọkandinlogun oṣu kinni, ọdun 2017

Aarẹ Buhari mori le ilẹ Gẹẹsi lọjọ kọkandinlogun oṣu kinni, ọdun 2017.

Ileeṣẹ aarẹ sọ pe itọju ara rẹ lo mu ki aarẹ Buhari gunle irinajo ọhun si ilu Oba.

Ọjọ kẹwaa oṣu kẹta ọdun 2017 ni Buhari pada si Naijiria lẹyin to lo ọjọ mọkanlelaadọta lorilẹede UK.

Ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹsan an, ọdun 2017

Ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹsan an ọdun 2017 ni Aarẹ Buhari gbera lati ilu London lọ si orilẹede Amẹrika.

Aarẹ rinrin ajo naa lati lọ gba itọju fun agọ ara rẹ.

Ọjọ mẹrin ni Buhari lo nilẹ Amẹrika ko to pada si ilu Abuja lọjọ kẹẹdọgbvọn oṣu kẹsan an ọdun 2017 .

Ọjọ kẹsan an oṣu kẹrin, ọdun 2018

Buhari fi orilẹede Naijiria silẹ lọ si ilẹ Gẹẹsi lọjọ kẹsan an oṣu kẹrin ọdun 2018.

Ọjọ mẹtala gbako ni Buhari nilẹ Uk ki o to pada wale lọjọ kọkanlelogun oṣu kẹsan an ọdun 2018.

Ijọba ni isinmi ọlọdọọdun ni Aarẹ Buhari lọ fun nilẹ Gẹẹsi.

Buhari kopa ninu ipade awọn orilẹede to gbominira lati ọdọ ilẹ Gẹẹsi, bakan naa lo ṣe ipade pẹlu Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi Theresa May nigba naa.

Ọjọ kẹjọ oṣu karun un ọdun 2018

Aarẹ Buhari tun gbera lọ si ilẹ Uk lọjọ kẹjọ oṣu karun un ọdun 2018.

Iroyin to jade lati ileeṣẹ ṣalaye pe itọju ara lo mu ki Buhari rinrin ajo lọ si ilẹ okeere.

Ọjọ kọkanla oṣu karun ọdun 2018 ni Buhari pada si Naijiria lẹyin to gba itọju tan niluu London.

Ọgbọnjọ, Osu Kẹrin, ọdun 2021

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari n lọ si ilu London lati lọ gba itọju fun isinmi ọlọsẹ-meji.

Ileeṣẹ ijọba fikun pe aarẹ yoo pada si orilẹede Naijiria ni Ọsẹ keji ni Oṣu Kẹrin, ọdun 2021.

Buhari ń lọ ṣàyẹ̀wò ara ní London lásìkò táwọn dókítà fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì

Oríṣun àwòrán, Twitter/Bashir Ahmad

Ijọba apapọ ti kede pe Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari n lọ si ilu London lati lọ gba itọju fun isinmi ọlọsẹ-meji.

Ileeṣẹ ijọba loju opo Twitter wọn ni Ọjọ Iṣẹgun, Ọgbọnjọ Oṣu Kẹta, ọdun 2021 ni aarẹ Buhari yoo ma a rin irinajo naa.

Amọ ki aarẹ Buhari to kuro ni ilu Abuja, yoo kọkọ ṣe ipade pẹlu awọn adari ikọ ọmọogun Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lẹyin naa ni aarẹ yoo tẹsiwaju irinajo rẹ si Ilẹ Gẹẹsi fun ọṣẹ meji.

Ileeṣẹ ijọba fikun pe aarẹ yoo pada si orilẹede Naijiria ni Ọsẹ keji ni Oṣu Kẹrin, ọdun 2021.

Amọ, ẹgbẹ awọn dokita lorilẹede Naijiria,NARD ti fariga wi pe awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi alaini gbedeke bẹrẹ lati Ọjọ Kini, Oṣu Kẹrin, ọdun 2021.

Lara ẹsun ti wọn fi kan ijọba ni wi pe wọn kọ lati mu ileri wọn ṣe lasiko ti wọn ba wọn ṣepade titi di asiko yii.

Bakan naa ni wọn fẹsun kan ijọba wi pe wọn kọ lati ṣetọju awọn ẹbi ati ara ti awọn dokita ti wọn ku tori arun Coronavirus.

Àkọlé fídíò,

Akomolede àti Asa: Ìyàtọ̀ tó wà láàrin ìlànà ìpolówó ọjà láyé àtijọ́ àti òde òní

Nibayii, ẹgbẹ awọn dokita lorilẹede Naijiria ti ni awọn ko ni yi ọkan wọn pada nitori ijọba kọ lati mu adehun wọn ṣẹ titi di asiko yii.

Amọ Minisita fun iṣẹ ati igbanisiṣẹ, Festus Keyamo ti rọ awọn dokita naa lati gbegile iyanṣẹlodi ọun nitori ijọba ti gbe igbese lati ṣe ipade pẹlu wọn.

Tí Naijiria bá pín, ó ṣe e ṣe kí ẹ má a gba físà kẹ́ ẹ tó wọ Kano - Osinbajo

Oríṣun àwòrán, @ProfOsinbajo

Igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo ti gba awọn to n polongo pe ki Naijiria tuka, lati tun ero ara wọn pa.

Iroyin sọ pe nibi eto idanilẹkọ to waye fun ọjọ ibi Bola Tinubu, ni Osinbajo ti sọ ọrọ naa.

Osinbajo sọ pe ti Naijiria ba tuka, o ṣe e ṣe ki awọn arinrinajo o nilo iwe irinna ki wọn o to le wọ awọn ilu bi Kano.

O fi ọrọ naa ṣakawe pe, ka ni Naijiria ti pin ni, gbogbo awọn to wa nibi idanilẹkọ naa ni i ba nilo fisa ki wọn o to o le wa.

Pínpín tàbí àtúntò Nàìjíríà kọ́ ló máa mú ìgbáyé-gbádùn wá fún wa lórílẹ́èdè yìí- Amaechi

Ninu iroyin mii, Minisita igbokegbodo ọkọ ni Naijiria, Rotimi Amaechi ti sọ pe pinpin tabi atunto Naijiria kọ ni yoo mu igbayegbadun wa fawọn ọmọ orilẹede yii.

Amaechi ni awọn to n kọminu lori ọjọ iwaju orilẹede Naijiria n ṣe bẹẹ nitori ifẹ ti wọn ni si orilẹede wọn.

Amọ, Amaechi sọ pe atunto tabi pinpin Naijiria kọ ni yoo jẹ ki nnkan ṣẹnu 're fawọn ọmọ orilẹede Naijiria.

Minisita igbokegbodo ọkọ sọ pe ko dara ki awọn eeyan maa sọ pe iṣẹ ati oṣi ti pọ sii lasiko ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ju ijọba Goodluck Jonathan to wa lori oye tẹlẹ lọ.

Amaechi ni kii ṣe asọdun pe lati ori awọn ijọba to ti ṣe ki Buhari to gori oye ni iṣẹ ati oṣi ti n gbilẹ bọ ki Buhari too de.

Minisita ni ati igba ti Naijiria ti pada si ijọba ologun ni iṣẹ ati oṣi ti bẹrẹ si ni ba ọpọ eeyan finra ni Naijiria.

''Gbogbo wa ni a nifẹ orilẹede wa Naijiria, ti a si n fẹ ki orilẹede naa dun un gbe fun gbogbo eeyan.

Àkọlé fídíò,

'Èmi àti ìyàwó mi ti ń gbé pọ̀ nínú ìgbéyàwó wa fún 60 years', ẹ wá kọ́ ẹ̀kọ́ lẹ́nu àgbà méjì

Amọ, erongba wa lati jẹ ki Naijiria dara ju ero awọn kan ti wọn fẹ ki orilẹede yii pin lọ.

Atunto tabi yiyapa Naijiria kọ lo maa mu inu awọn ọmọ orilẹede yii dun,'' Amaechi ṣalaye.

O ni wiwa ni iṣọkan lo le mu igbayegbadun wa fawọn ọmọ Naijiria.

Minisita igbokegbodo ọkọ ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe ko si igba tawọn eeyan ti ebi n pa ko ni doju Naijiria bolẹ ti iṣẹ ati oṣi ba si n pọ sii.