Buhari: Ó dára kí Orílẹ̀èdè Naijiria wa ní ìṣọ̀kan jú kí a pínyà lọ

Naijiria

Oríṣun àwòrán, Twitter

Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti ni iṣọkan ati ibagbepọ gẹgẹ bi orilẹede kan lo dara fun orilẹede Naijiria, kii ṣe ituka.

Buhari sọ eyi lasiko ijiroro ọlọdọọdun ti wọn fi sọri ọjọ ibi asiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu, ti wọn ṣe lori ẹrọ ayelujara ati ni gbọngan ileeṣẹ ijọba ni ipinlẹ Kano.

Aarẹ Buhari to sọrọ lori ayelujara lati Aso Rock ni ilu Abuja ni, Tinubu jẹ ẹnikan pato to ja fun iṣọkan ati alaafia Naijiria lati wa ni orilẹede kan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

''Tinubu ko ipa ribiribi lati ri wi pe ayajọ Ọjọ June 12 duro lailai lorilẹede Naijiria lati ṣeranti MKO Abiola ati ipa to ko nipa iṣejọba alagbada ni Naijiria''

''Bakan naa ni Tinubu ṣe daradara lasiko to jẹ gomina ipinlẹ Eko ni ọdun 1999 si ọdun 2007.''

Oríṣun àwòrán, Twitter

O ni ijọba gbọdọ ri wi pe awọn ohun alumọni Naijiria kari awọn eniyan nile-loko, ki ọkan awọn ọmọ Naijiria balẹ ni gbogbo ibi ti wọn ba wa.

Bakan naa ni aarẹ fikun wi pe iṣẹ ti oun yan laayo ti fun oun ni ore ofẹ lati kaakiri gbọgbọ Naijiria, eleyii to fihan oun wi pe iṣọkan ati alaafia lo le mu orilẹede Naijiria goke agba.

''Ogun abẹle to waye ni ọdun 1967 si 1970 ti mo kopa ninu rẹ, ti ọpọlọpọ ologun ku to fi mọ awọn ọmọde, agbalagbala, ọkunrin, obinrin, nitori naa ogun kii ṣe ọna abayọ si iṣoro Niajiria."

Àkọlé fídíò,

Akomolede àti Asa: Ìyàtọ̀ tó wà láàrin ìlànà ìpolówó ọjà láyé àtijọ́ àti òde òní

Ninu ọrọ tirẹ, Tinubu rọ ijọba aarẹ Buhari lati pese iṣẹ fun awọn ọdọ ti wọn pọ bi yanrin ni Naijiria, to si jẹ wi pe ida mẹtalelọgbọn ninu wọn nikan lo ni iṣẹ lọwọ.

Kí ló dé tí ẹsẹ̀ Tinubu fi yọ̀, tó fẹ́ ṣubú ní Kaduna?

Oríṣun àwòrán, @TheBolaATinubu

Fidio kan to n ja rainrain lori ayelujara lo se afihan asaaju ẹgbẹ oselu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu to fẹ yọ subu.

Tinubu lo wa nilu Kaduna lọjọ Abamẹta nibi idanilẹkọ ọlọdọọdun ti wọn fi sọri Ọlọla Ahmadu Bello, ikọkanla iru rẹ, to waye ni Gbọngan Arewa.

Gẹgẹ bi fidio naa ti se afihan rẹ, Jagaban tilu Eko n wọnu ile bọ, o si wa laarin ọpọ eeyan lori pepele ti wọn se fun awọn ọlọla, lasiko ti isẹlẹ naa waye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Tinubu, ẹni to n ki awọn alejo to wa lori tabili ọlọla naa, ni ẹsẹ rẹ sadede yọ, to si fẹ subu.

Ọpẹlọpẹ awọn ẹsọ alaabo to rọgba yi ka, ti wọn si tete dii mu, ko ma baa subu sori ilẹ.

Àkọlé fídíò,

Covid-19: Wo ìròyìn òfegè mẹ́jọ táwọn adarí ẹ̀sìn ń sọ nípa àbẹ́rẹ́ àjẹsára Coronavirus

Amọ sa, ero awọn eeyan kan se ọtọọtọ lori isẹlẹ bi ẹsẹ Tinubu se yọ nibi idanilẹkọ ọlọdọọdun naa.

Bi awọn eeyan kan se ni isẹlẹ naa kii se tuntun, ko si ni ọwọ aye ninu rara nitori ko si ẹni ti ko le subu.

Amọ awọn eeyan miran lero tiwọn ni agba ti de si gomina ana nipinlẹ Eko naa, ti ilera ara rẹ si ti jẹ ti agba, idi si ree ti ẹsẹ rẹ fi yọ subu.

Ki ni ero Shehu Sani?

Ni ti agba oselu kan lẹkun ariwa Naijiria, Sẹnatọ Shehu Sani, lowe lowe ni ọrọ rẹ gẹgẹ bi imọran fun asiwaju Bola Tinubu loju opo Twitter rẹ.

Oríṣun àwòrán, @ShehuSani

Sani ni " Iwọ Jagaban, mọ iwọn ara rẹ, wọn yoo maa rẹrin si ọ tabi ba ọ sọrọ kẹlẹkẹlẹ lati gbe ọ lọ sori oke Sinai, amọ wọn yoo ju ọ silẹ, wọn yoo si mu ko ri sinu odo Euphrates."

Ọrọ ti Sani sọ yii si ni awọn eeyan to sọrọ le lori n gba bii ẹni gba igba ọti.

Wo kókó ọ̀rọ̀ mẹ́wàá tí Bola Tinubu sọ ní Kaduna

Oríṣun àwòrán, @TheBolaATinubu

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe asaaju ẹgbẹ oselu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti tako gomina ipinlẹ Plateau, Simon Lalong, pe ki ẹka isejọba mẹtẹẹta se adinku owona wọn ni kiamọsa.

Gẹgẹ bi Lalong ti wi nibi eto ti Tinubu bawọn peju si nilu Kaduna, bi adinku ba ba owona ijọba, owo yoo wa lati gbọ bukata lawọn ẹka eto idagbasoke to se koko, eyi to jẹ ipenija fun Naijiria.

Amọ nigba to n sọrọ lọjọ Abamẹta nibi idanilẹkọ ọlọdọọdunti wọn fi sọri Ahmadu Bello, ikọkanla iru rẹ, nibi ti gomina Plateau naa wa, Tinubu ni ọrọ ko ri bi Lalong se woye rẹ.

Àkọlé fídíò,

'Èmi àti ìyàwó mi ti ń gbé pọ̀ nínú ìgbéyàwó wa fún 60 years', ẹ wá kọ́ ẹ̀kọ́ lẹ́nu àgbà méjì

Asaju ẹgbẹ oselu APC naa ni o yẹ kawọn ọmọ Naijiria tako ero pe owona ijọba ko mu eso rere kankan jade, to si lewu fun ọrọ aje orilẹede yii.

Tinubu ni o seese lootọ ki ijọba maa na inakuna tabi ko lo owo naa feto idagbosoke to yẹ, bẹẹ si ni ẹka eto aladani to n sọ owo na, ko tumọ si pe o n kopa gidi si agbega ọrọ aje.

O wa salaye pe o yẹ ki ijọba maa pese owona to jọju fawọn isẹ akanse ti yoo pese isẹ ati idagbasoke fun ilẹ wa.

Àkọlé fídíò,

'Pẹ̀lú gbogbo ìrìnàjò Dubai mi, ẹ̀sẹ̀ gígún ní Nàìjíríà láti pàdé èèyàn ńlá ńlá tó lè ra àwòrán wa ṣe pàtàkì'

Yatọ si eyi, ọpọ ọrọ ni oloye Tinubu sọ nibi ipade naa, akekuru awọn ọrọ naa ree:

Koko ohun mẹsan mii ti Tinubu sọ ni Kaduna:

  • Tinubu se kare si Ahmadu Bello, Obafemi Awolowo ati Nnamdi Azikwe fun agbekalẹ orilẹede Naijiria to ni ominira, to si jẹ ọkansoso
  • O yẹ kawọn iran yii ati iran to n bọ ni Naijiria mọ le ipilẹ tawọn akọni ilẹ wa naa sefilọlẹ rẹ, ki ayanmọ orilẹede yii le wa si imusẹ
  • Ẹka aladani ni Naijiria ko lagbara bo se yẹ fun eto idagbasoke ta n poungbẹ rẹ, idi si ree to fi yẹ ki ijọba dide lati di alafo naa
  • Ijọba gbọdọ na owo sawọn akanse isẹ ti yoo mu ere ọrọ aje to ru gọgọ wa fun Naijiria
  • Igun kọọkan ni Ariwa tabi Guusu Naijiria gbọdọ maa sọrọ ni ohun kan lai jẹ pe ẹya kankan fa sẹyin nidi jijẹ anfaani ilsiwaju to n ba orilẹede yii
  • Eto ibomirin yoo seranwọ feto ọgbin, ta si ri ọna abayọ si ipenija asalẹ
  • Ẹkun ariwa Naijiria n moke ninu idokowo lẹka eto ọgbin eyi to jẹ ẹka idokowo kan gboogi fun idagbasoke Naijiria
  • Agbelarugẹ eto aabo wa yoo wa ojutu si aawọ awọn agbẹ ati darandaran amọ o ni eyi kii se ọna kan soso ta fi le wa ojutu si wahala naa
  • Ko yẹ ka maa lo iwa ipa lati tan isoro eto aabo to mẹhẹ ni Naijiria nitori ọrọ aje ti ko fararọ lo faa, ilana ọrọ aje naa si la fi wa ojutu si.