Viral Audio on Begging: Àwọn alágbe ń fapá jánú pé aráàlú kórira àwọn torí àhesọ ọ̀rọ̀

Awọn onibaara

Oríṣun àwòrán, Abdullahi Tafa

Yoruba ni tẹni ba dakẹ, ti ara rẹ maa n ba dakẹ ni nitori ẹnu ẹni la fi n kọ mejẹ.

Eyi lo mu ki awọn onibaara to wa ni agbegbe Ọja Ọba nilu Ibadan se figbe bọnu pe okuta ti ba ọja awọn eyi tii se agbe sise.

Ọpọ awọn eeyan apa oke ọya lo kun ilu Ibadan, tii se olu ilu ipinlẹ Oyo dẹnu lati wa se agbe, ti wsn si wọpọ lawọn agbegbe bii Sabo, Ọjọọ, Ọja Ọba, Mọkọla, Sasa ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bi iwe iroyin Vanguard ti wi, Ọjọbọ lawọn alagbe yii, ti wọn fẹẹ to ọọdunrun niye, bẹrẹ si ni fi ẹhonu han pe awọn eeyan ko fi bẹẹ se aanu fun awọn mọ.

Wọn ni agbara kaka ni awọn fi n mu ọwọ lọ sẹnu lasiko yii nitori fọnran kan to gbode pe awọn alagbe maa n ta owo baara fawọn to n fi se etutu ọla.

Oríṣun àwòrán, Abdullahi Tafa

Bẹẹ ba gbagbe, laipẹ yii la mu iroyin to wa nisalẹ yii wa fun yin nipa bawọn gbajumọ kan ni awujọ se pinnu pe awọn ko ni fun awọn onibara lowo mọ.

Idi ni bi fọnran ohun obinrin alagbe kan se gba ori ayelujara laipẹ yii, nibi to ti n tu asiri bi wọn se n parọ se agbe, ti wọn yoo si tun ta owo ti wọn ba ri kojọ fawọn eeyan kan.

Obinrin naa ni owo ọhun ni awọn eeyan to ba ra a lọwọ awọn maa fi n se etutu ọla, aṣiki ẹnikẹni to ba si fun awọn ni owo agbe naa yoo maa lọ silẹ ni.

Oríṣun àwòrán, Abdullahi Tafa

Nigba to sọrọ lorukọ awọn alagbe naa, Abubakar Abdullahi, tii se Seriki Hausawa lagbegbe Ọja Aba ni awọn eeyan ti bẹrẹ si ni ikorira nla sawọn alagbe bayii.

"Iroyin to gbode kan pe awọn alagbe maa n ta owo baara ti wọn ba ri gba lati ọdọ awọn alaanu fun awọn eeyan ti yoo fi owo naa se etutu ọla, kii se otitọ rara.

Ahesọ ọrọ yii si lo ti mu okuta ba agbe sise nitori ọpọ eeyan awujọ ni ko fẹ ri awọn alagbe soju mọ lasiko yi.

Àkọlé fídíò,

Blighted Ovum: Obìnrin kan sọ ohun tójú rẹ̀ rí nígbà tí oyún bàjẹ́ lára rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹta

Ohun ta mọ ni pe awọn ontaja, onikiri ọja atawọn awakọ ero maa n wa sẹ owo beba odidi si wẹwẹ lọdọ awọn alagbe yii, paapaa lọdọ awọn arọ, ati afọju.

Abdullahi wa kede pe o se pataki ki awọn wẹ orukọ awọn alagbe mọ ninu ẹsaun yii, tori awọn ko mọwọ, mẹsẹ ninu rẹ.

Àwọn gbajúmọ̀ faraya lórí alágbe tó kọ́ ilé mẹ̀rin, ra mọ́tò mẹ́ta

Oríṣun àwòrán, Access24

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe fọnran ohun arabinrin alagbe kan to fi iṣẹ bara ọdun mẹwaa kọ ile mẹrin, ra ọkọ mẹta, ti n lọ kaakiri lori ayelujara, to si gbalẹ kan.

Arabinrin naa to pe orukọ ara rẹ ni Simbiatu Mopelola ṣalaye ninu ifọrọwerọ akasilẹ naa pe, ẹni ọdun mọkanlelaadọta ni oun ati pe ọmọ oun meji lo wa loke okun, ti oun si ni awọn eeyan mejila to n ba oun ṣiṣẹ.

Arabinrin naa, ti iroyin sọ pe o ti wa ni ahamọ awọn ọlọpaa fi kun un pe, gbogbo owo ti awọn eeyan ba fun awọn gẹgẹ bii baara, ni awọn tun maa n tun ta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni awọn Alfa, Woli atawọn gbajumọ kan to fẹ ja ewe sobi etutu ọla wọn lo maa n ra awọn owo baara ti awọn ba pa naa, eleyi to ni o n fa sababi ifasẹyin fun ọpọ awọn ẹlẹyinju aanu to ba wa ninu awọn to fun onibaara lowo naa.

Nibayii, awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti n sọ si ọrọ naa, koda awọn eekan ilu pẹlu ko gbẹyin.

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Paul Play Dairo, ọmọ agba oṣere juju ni, IK Dairo lo kọkọ gbe ọrọ sita lori rẹ nigba to fi ọrọ naa soju opo ikansiraẹni Facebook rẹ.

Dairo ni pe " obinrin ẹni ọdun mọkanlelaadọta kọ ile mẹrin, ra mọto mẹta, o ran ọmọ nilẹ okeere ninu owo iṣẹ bara ọdun mẹwaa to ṣe."

Ọpọ awọn to da si ọrọ naa loju opo facebook Paul Play Dairo ni wọn ke ibosi ara adugbo, ti wọn si ni pe awọn ti pinnu lati dẹkun ṣiṣe aanu fun awọn onibara mọ.

Oríṣun àwòrán, facebook/paul dairo/daddy freeze

Nibayii naa, gbajugbaja agbohunsafẹfẹ nni, Daddy freeze ni tirẹ ni nṣe ni ara oun n gbọn lati igba ti oun ti gbọ fọnran ohun akasilẹ naa, nitori o mu ẹru oore ṣiṣe fun onibara ba oun.

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Haaa ni iṣẹlẹ naa n ṣe ọpọlọpọ loju opo ayelujara awọn mejeeji yii bayii, to si seese ki isẹlẹ naa da omi tutu sookan aya awọn araalu lati maa se oore fun onibaara.