Sunday Igboho: Àwọn èèyàn kan ní mò ń fi ètò ìjìjàgbara kó owó jọ láti lu jìbìtì

Sunday Igboho atawọn ọmọlẹyin rẹ

Gbajugbaja ajijagbara fun ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeyemo Igboho ti faraya fun awọn eeyan to n pe ni onijibi ati gbajuẹ.

Igboho lasiko to n kopa lori eto kan ti agbẹnusọ rẹ, Olayomi Koiki se atọkun rẹ, nibi to ti n ba obinrin ilẹ okeere kan sọrọ, lo ti fara ya bẹẹ.

Ajijagbara ọmọ ilẹ Yoruba naa ni eti oun ti kun pupọ nipa awọn eeyan to n sọ oun ni suna buruku pe onijibiti ni oun.

O ni awọn eeyan naa ni wọn n fi ẹnu ibajẹ kun eto ijijagbara ti oun n se pe oun fi n ko owo jọ ni, eto to buru jai.

Igboho ni Ọlọrun gba adura oun daadaa, ti kii se kekere pẹlu.

Àkọlé fọ́nrán ohùn,

Igboho Ultimatum to Fulani: Ẹni bá mọ Sunday Igboho kó bá wa bẹ̀ẹ́ o,

"Eeyan nla ni mi ti Ọlọrun kẹ pupọ, ti ẹnikẹni ko si le jade wa pe mo lu oun ni jibiti owo lati de ipo nla ti mo wa loni.

A jade sita lati daabo bo awọn eeyan wa, ti awọn eeyan kan si ni nitori owo la fi n se e, ẹ jọọ, iru owo wo niyẹn.

Lọpọ igba ni mo maa n sọ pe ki ni ere mi ninu ijijagbara naa, titi debi pe awọn eeyan yoo maa naka aleebu si mi pe mo n lu awọn ni jibiti ni."

Igboho tun wa fọwọ sọya pe, gbajumọ onisowo ọlọjọ pipẹ ni oun, ti oun si ri taje se lai se kekere. Orukọ ileesẹ oun si ni Adeson International Concept Limited.

Àkọlé fídíò,

Ifọrọwerọ pẹlu Gani Adams lori ọrọ Sunday Igboho

O fikun pe oun ni oludari agba fun ileesẹ elepo rọbi ati afẹfẹ idana gaasi naa, kii si se akoko yii ni oun da ileesẹ naa silẹ, ọjọ ti pẹ.

Sunday Igboho tun mẹnuba pe ijọba apapọ gan sewadi oun nigba ti wọn ri owo tuulu to wa ninu apo asunwọn owo oun nile ifowopamọ, ti wsn si gbẹsẹ le.

Amọ o ni ofo ọjọ keji ọja naa ni iwadi wọn ọhun ja si, ti wọn si pada kan saara si oun nitori wọn ri daju pe onisowo to lami laaka ni oun, isalẹ owo toun ko si lẹgbin.

Àkọlé fídíò,

Kò sí ìgbà kankan tí Yorùbá jókòó pé ki Igboho lọ kéde ìyapa kúrò ní Nàíjíríà

"Awọn eeyan kan wa n pe emi ni onijibiti, wọn n sọ orisirisi ọrọ kobakungbe pe mo fẹ lu awọn eeyan ni jibiti ni."

Bakan naa ni Igboho lo akoko eto naa lati tọrọ aforijin lọwọ awọn oriade ti wọn sọ pe awọn n yaju si tabi tabuku wọn.

O ni ki gbogbo awọn ọba alaye ti wọn ba ti sọrọ abuku si mase binu nitori a le bu ọba lẹyin, amọ ta ba de iwaju rẹ, a sọ pe a ko sọ bẹẹ.

"A ko yaju si awọn oriade wa, a kan n ke si wọn lati dide se ojuse wọn, nitori ẹtọ wa ni lati pe wọn, ara lo si n ta wa nipa eto aabo to mẹhẹ naa.

Ko gba ẹnu ọmọ ko ni ki iya oun pa idi mọ, nitori naa, ki wọn darijin wa ta ba yaju si wọn."

Àkọlé fídíò,

Covid-19: Wo ìròyìn òfegè mẹ́jọ táwọn adarí ẹ̀sìn ń sọ nípa àbẹ́rẹ́ àjẹsára Coronavirus

Ajijagbara naa wa fidi rẹ mulẹ pe, asiko ijijagbara fun ilẹ Oodua ti to nitori to ba ya awọn ọmọ kekeke yoo died lati gbeja ara wọn.

O ni awọn ọmọde naa yoo ja fun ẹtọ wọn, ti Ọba Oke yoo si ran wọn lọwọ lati gbeja wọn, idi si niyi ta fi gbọdọ dide.

O wa dupẹ lọwọ awọn ọmọ Yoruba to wa loke okun fun atilẹyin wọn fun eto ijijagbara to n se, to si ni akoko ti to bayii lati tako iwa isekupani, ijinigbe ati ifipabanilopọ.

Sunday Igboho gbé ìjìjàgbara dé Osogbo, ó ṣàlàyé orísun agbára rẹ̀

Oríṣun àwòrán, koiki media

Eekan ọmọ Yoruba nni, Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho, ti ṣalaye pe oun ko mọ adura gba bẹẹni oun o fi ọjọkan ri dupẹ lọwọ Ọlọrun fun oore ana.

Amọṣa, o ni oun mọ daju pe adura ọpọ awọn eeyan Ọlọrun bi awọn Alfa n gba pupọ lori oun, ni oun fi n se aseyọri.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oloye Sunday Igboho ṣalaye ọrọ yii nigba to n sọrọ nibi eto Malud Nabiy kan to waye nilu Ido Ọṣun ni ipinlẹ Ọṣun.

Sunday Igboho ni ajogunba ni oogun abẹnugọngọ jẹ fun oun nitori ọwọ baba oun ni oun ti jogun rẹ ṣugbọn oun ko dara pọ mọ ẹgbẹ awo kankan.

Oríṣun àwòrán, koiki media

O fi kun un pe, lati kekere ni oun ti sunmọ awọn Alfaa, ti oun si mọ pe pupọ wọn lo ni ifẹ oun daradara, bẹẹ ni adura wọn ni gbogbo igba n gba lori oun.

Igboho ni "Aya mi tubọ di lati maa jijagbara tori adura awọn aafa n gba lori mi. Lati kekere ni mo ti sunmọ awọn Alfa bi n ko tilẹ mọ adura gba."

Sunday Igboho wa ranti isẹlẹ kan to waye lopopona Ibadan silu Eko, lasiko ti awọn osisẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS fẹ gbe ni tipatipa lasiko to n lọ silu Eko, amọ ti ori ko yọ.

Oríṣun àwòrán, Koiki Media

Asaaju ajijagbara naa mu wa siranti pe ọjọ Jimoh ni ọjọ ti isẹlẹ naa waye, adura ti awọn Alfa si gba fun oun lọjọ naa, lo ko oun yọ.

"Awọn osisẹ DSS to le ni ọgọta, ti gbogbo wọn gbe ibọn lọwọ, lo sẹburu mi lọjọ naa, ti wọn si ti wa baalu kekere ẹlikopita kalẹ, lati di mi ni apanyaka lọ silu Abuja.

Amọ mo kan pasẹ fun wọn pe ki wọn maa lọ, ni gbogbo wọn ba tuka, mo mọ pe adura tawọn Alfa gba fun mi lọjọ Jimoh naa lo gba lori mi."

Igboho ni "alaigbọn ẹda ni yoo sọ pe ko si Alfa lẹyin wa, inu awọn Alfa si n dun pe adura awọn n gba lori wa."

Àkọlé fídíò,

Covid-19: Wo ìròyìn òfegè mẹ́jọ táwọn adarí ẹ̀sìn ń sọ nípa àbẹ́rẹ́ àjẹsára Coronavirus

O wa fi ọwọ gbaya pe ni iwoyi ọdun ti n bọ, ilẹ Yoruba yoo ti wa ni ominira lasiko ọdun Nabiyy Maolud, tawọn ọba alaye yoo si pejọ lati se ayẹyẹ ominira ilẹ Yoruba lasiko naa.

Oloye Sunday Igboho tun jẹ ko di mimọ pe, ohun ti oun n ja fun, gẹgẹ bi idagbasoke, aabo ati alaafia ni ilẹ Yoruba n tẹsiwaju nitori atilẹyin awọn iranṣẹ Ọlọrun gbogbo ti wọn n fi adura ran oun lọwọ.

O ni ohun to n waye nilẹ Yoruba ko sẹlẹ ri, imọsi Ọlọrun ati tawọn Alfa, lo si jẹ ki oun maa se ohun ti mo n se.

Oríṣun àwòrán, Koiki Media

Awọn Alfa to wa nibi eto naa wa kan sara sii fun ọkan akin rẹ ati ifaraẹni jin fun idagbasoke ilẹ Yoruba paapaa julọ didide tako awọn ọdaran darandaran to n ji ọpọ gbe nilẹ Yoruba, ti wọn si tun ti sọ ọpọ di ero ọrun.