Ebenezer Obey and Simi: Commander ní akọrin tó ní tálẹ́ǹtì ni Simi, òun ní ìrírí tó dára pẹ̀lú rẹ̀

Simi ati Ebenezer Obey

Oríṣun àwòrán, Instagram/Simply Simi

Awọn Yoruba maa n sọ pe bi okete ba dagba tan, ọmu ọmọ rẹ lo maa n mu.

Bayii lọrọ ri pẹlu gbajugbaja olorin Juju, Oloye Ebenezer Obey Fabiyi ti ọpọ maa n pe ni Chief Commander pẹlu olorin takasufe, Simisola ti ọpọ mọ si Simi.

Simi ṣe ẹda ọkan lara orin ti Obey ti kọ, ti akọle rẹ n jẹ ''Aimasiko'', eyi ti awọn mejeeji di jọ kọ papọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba ti o ba awọn akọroyin sọrọ, Obey Commander ni iriri to dara ni kikọ orin awo ''Aimasiko'' papọ pẹlu Simi.

''Bi ọmọ ni Simi ati Adekunle Gold, ọkọ rẹ jẹ si mi.

Àkọlé fídíò,

'Èmi àti ìyàwó mi ti ń gbé pọ̀ nínú ìgbéyàwó wa fún 60 years', ẹ wá kọ́ ẹ̀kọ́ lẹ́nu àgbà méjì

Simi jẹ olorin to ni talẹnti gan an, o ṣe ẹda ọkan lara awọn awo orin, ''Aimasiko'' lẹyin to gba iyọnda lati ọdọ mi.

Lẹyin naa ni emi ati Simi jọ kọ orin naa papọ, eleyii to dun un gbọ leti.'' Ebenezer lo ṣalaye bẹẹ.

Agbaọjẹ olorin Juju naa ni onirẹlẹ ni Simi, atipe olorin ti ko ṣe fi ọwọ rọ sẹyin loun ati ọkọ rẹ, Adekunle Gold.

Ebenezer Obey ko ṣai sọrọ nipa Burna Boy ati Wizkid ti wọn gba ami ẹyẹ agbaye Grammy ninu orin kikọ.

Àkọlé fídíò,

Covid-19: Wo ìròyìn òfegè mẹ́jọ táwọn adarí ẹ̀sìn ń sọ nípa àbẹ́rẹ́ àjẹsára Coronavirus

''Idunnu lo jẹ fun mi pe Burna Boy ati Wizkid pada gba ami ẹyẹ Grammy, oriire nla ni,'' Obey lo sọ bẹẹ.

Chief Commander, ti yoo pe ẹni ọdun mọkandinlọgọrin lọjọ kẹta oṣu kẹrin sọ pe gbogbo iyoku aye oun, Ọlọrun oba loun yoo fi sin.

Obey ni igba mẹrin ọtọtọ lawọn eeyan kan ti tufọ oun lai tii ku, nitori naa, ''mo ni lati maa yin Ọba oke to da mi si.

Ati pe jijẹ olorin fun ọgọta ọdun to lati maa yin Eleduwa to fun mi ni ore ọfẹ,'' Chief Commander lo ṣalaye bẹẹ.