Miscarriage paid leave: Owó àti ìsinmi tí ìjọba yóò fún ọ rèé, tí oyún bá bàjẹ́ tàbí bímọ kú

Obinrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ko si ani-ani pe obinrin ti oyun ba bajẹ lara rẹ tabi ti o ba bimọ ku nilo itọju ati imulọkanle.

Eyi lo mi ki ile aṣofin orilẹede New Zealand buwọlu agbekalẹ ofin kan fawọn obinrin ti wọn ba bimọ ku tabi tabi ti oyun bajẹ lara wọn.

Labẹ ofin yii, awọn oṣiṣẹ ti iru nnkan yii ba ṣẹlẹ si yoo lanfaani lati gba isinmi ọjọ mẹta lẹnu iṣẹ, ti ijọba tabi awọn to gbawọn ṣiṣẹ si tun gbọdọ fun wọn lowo pẹlu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Aṣofin ẹgbẹ oṣelu Labour, Ginny Andersen to da aba ofin ọhun ṣalaye pe, ofin naa jẹ ẹtọ awọn ọmọbibi orilẹede New Zealand.

Aṣofin Andersen ni eyi yoo fun awọn ti oyun bajẹ lara wọn ni asiko lati tọju ara wọn, ki wọn to pada sẹnu iṣẹ.

O fikun ọrọ rẹ pe, New Zeland ni orilẹede keji lagbaaye lẹyin India, ti yoo gbe iru ofin yii kalẹ fawọn araalu.

Andersen ni ofin yii yoo fawọn obinrin ni igboya lati gba aaye fun isinmi lẹnu iṣẹ ti oyun ba bajẹ lara wọn tabi ti wọn ba bimọ ku.

Aṣofin naa ni awọn agbaniṣiṣẹ kan maa n fawọn obinrin to ba ni iru iriri bayii ni isinmi lẹnu iṣẹ, ṣugbọn awọn kan kii ṣe bẹẹ eleyii ti ko tọna.

Àkọlé fídíò,

Covid-19: Wo ìròyìn òfegè mẹ́jọ táwọn adarí ẹ̀sìn ń sọ nípa àbẹ́rẹ́ àjẹsára Coronavirus

O ṣalaye pe ofin tuntun yii yoo mu ẹgan tabi oju abuku tawọn kan maa n fi wo awọn ti oyun ba bajẹ lara wọn kuro.

Bakan naa lo sọ pe ofin ọhun yoo tun fawọn obinrin ni igboya lati le maa sọ nipa bibi ọmọ ku tabi oyun bibajẹ lara obinrin.

O ni ofin naa yoo tun fawọn obinrin lanfaani lati beere fun iranwọ nigba ti oyun ba bajẹ lara wọn.

Igbimọ alaṣẹ ijọba New Zealand ni lati buwọlu ofin yii ki o to di amulo nilẹ naa.