Miss Pepeiye: Òṣèré tíátà Yorùbá ṣe ìyàwó pẹ̀lú agbábọ́ọ̀lù Super Eagles Peter Olayinka

Peter Olayinka ati Yetunde Barnabas

Oríṣun àwòrán, Instagram/yetundebarnabas

Ojo ifẹ ti rọ nile agbabọọlu Super Eagles, Peter Olayinka ati oṣere tiata Yoruba kan, Yetunde Barnabas ti ọpọ mọ si Miss Pepeiye, nitori ipa to ko ninu ere Papa Ajasco.

Ọjọ Abamẹta ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹta ọdun 2021 yii ni Olayinka gbe Yetunde ni iyawo.

Iroyin ti a gbọ ni pe, Olayinka pade Yetunde lọdun 2019 ni ọdun kan naa ti o ṣoju ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles Naijiria fun igba akọkọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lati igba naa si ni wọn ti bẹrẹ irinajo ifẹ wọn, ki wọn to di lọkọ laya lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹta.

Lẹyin oṣu mẹta ti Peter dẹnu ifẹ kọ Yetunde ni wọn gbe igbesẹ akọkọ, nipa ṣiṣe mọ mi n mọ ọ pẹlu awọn ẹbi wọn.

Lẹyin naa ni wọn ṣe igbeyawo, ti awọn mejeeji si di lọkọ laya.

Olayinka ati Yetunde ni wọn sọ oriṣiiriṣii ọrọ ifẹ loju opo Instagram wọn, lẹyin ti wọn so wọn pọ tan.

Yetunde sọ loju opo Instagram rẹ pe ''o ṣe ti o fihan mi pe ifẹ otitọ ṣi wa.

Eyi gan an lo jẹ ki n gbe igbesẹ lati jẹ tirẹ titi aye mi.''

Olayinka ni tiẹ sọ lori Instagram pe ''mo le maa mọ ọrọ to yẹ ki n lo lati fi idunnu mi han ati iru ibukun to rọgba yi mi ka lẹyin ti o wọn inu aye mi.

Ṣugbọn mo ṣa fẹ ki o mọ pe mo nifẹ rẹ pẹlu gbogbo ohun to wa ninu mi, ati pe irinajo ti a bẹrẹ yii, titi laelae ni.''

Lẹyin ti wọn so awọn mejeeji pọ tan ni tọkọ taya fi ijo bẹẹ ti wọn si jọ sọdi rukẹ.