Bola Tinubu: Ojú ọjọ́ ti kò dára ṣèdíwọ́ fáwọn èèkànlú láti bá Asiwaju ṣe ọjọ́ ìbí ní Kano

Bola Tinubu ati Yemi Osinbajo

Oríṣun àwòrán, @akandeoj

Yoruba ni riro ni ti eniyan amọ sise ni ti Ọlọrun nitori ko si ẹda to mọ ọla.

Bẹẹ ni ọrọ ri nibi eto idanilẹkọ ọlọdọọdun, ikejila iru rẹ, ti wọn gbe kalẹ lati sami ọjọ ibi asaaju ẹgbẹ oselu APC, Asiwaju Bola Tinubu nilu Kano.

Idi ni pe ọpọ awọn eeyan jankan jankan to yẹ ko peju sibi ayẹyẹ naa ni ko le lọ nitori oju ọjọ ti ko dara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oju ọjọ to mẹhẹ naa lo se idiwọ fun baalu wọn lati fo lọ silu Kano nibi ti idanilẹkọ ọjọ ibi naa ti n waye.

Àkọlé fídíò,

Onpetu Ijeru: Akala ní torí Aláàfin kò ṣúgbàá òun fún sáà kejì, ló ṣe ní kí pín ipò alága

Lara awọn eekanlu ti oju ọjọ sediwọ fun lati peju sibi ayẹyẹ naa ni igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo, Minisita fọrọ abẹle, Rauf Aregbesola ati olori ile asojusofin nilẹ wa, Femi Gbajabiamila.

Awọn yoku ni akọwe fun ijọba apapọ Naijiria, Boss Mustapha, Minisita feto iroyin ati asa, Lai Muhammed atawsn eeyan jankan jankan miran.

Nigba to n fidi isẹlẹ yii mulẹ ni oju opo Twitter rẹ, agbẹnusọ fun igbakeji aarẹ, Laolu Akande kede pe ori ayelujara ni aarẹ ati igbakeji rẹ yoo ti wo eto naa.

Oríṣun àwòrán, @akandeoj

O ni aarọ yii lo yẹ ki Yemi Osinbajo tẹ baalu leti lọ silu Kano fun idanilẹkọ ti wọn fi sọri ọjọ ibi kọkandinlaadọrin Asiwaju Bola Tinubu.

Amọ Akande tẹsiwaju pe oju ọjọ ti ko dara lo se idiwọ fun igbakeji aarẹ lati peju sibi eto naa.

Buhari kò ṣèlérí pé Naira kan yóò bá Dọ́là kan dọ́gba - Iléeṣẹ́ ààrẹ

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Ileesẹ aarẹ Naijiria ti sọrọ lori ọrọ kan to gba igboro kan pe owo Naira ilẹ wa yoo ba owo Dọla kan dọgba ni kete ti Muhammmadu Buhari ba gba akoso.

Ọrọ yii ni awọn eeyan kan sọ pe Buhari fi se ileri lasiko ipolongo ibo rẹ lọdun 2015.

Amọ nigba to n fesi lori ọrọ ọhun, Oludamọran fun aarẹ Buhari feto iroyin, Femi Adesina salaye pe aarẹ ko figba kankan seleri bẹẹ fawọn ọmọ Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adesina, lasiko to n kopa lori eto ori tẹlifisan kan nilu Eko fikun pe ayederu ati iroyin eke ni ọrọ bẹẹ, ko waye ri .

"Iru ọrọ bayii ko waye ri. Ayederu iroyin ni, ti ko le see se."

Àkọlé fídíò,

Onpetu Ijeru: Akala ní torí Aláàfin kò ṣúgbàá òun fún sáà kejì, ló ṣe ní kí pín ipò alága

Bẹẹ ba gbagbe, o ti to ọjọ mẹta tawọn eeyan kan ti n ni aarẹ Buhari niran nipa awọn ileri to se lasiko eto ipolongo ibo rẹ lọdun 2015.

Ileri pe Buhari ni Naira kan yoo fi ẹgbẹ kẹgbẹ pẹlu Dọla kan lọdun 2015 si ni wọn n gba bii ẹni gba igba ọti lawọn oju opo ayelujara gbogbo.

Lọwọlọwọ bayii, lẹyin ti aarẹ Buhari ti lo ọdun mẹfa lori aleefa, ọrinlenirinwo naira ni wọn fi n se pasipaarọ fun dọla kan bayii.

Àkọlé fídíò,

'Òde ìnáwó làwọn èèyàn ma ń rò bí wọ́n bá rí Ankara, ìgbà tí wọ́n rí i lára àga tí mo ṣe, ẹnu wọn ò padé mọ́'

Idi si ree ti awọn ọmọ Naijiria fi n lọgun pe isẹlẹ naa tako ileri ti aarẹ Buhari se fun awọn lọdun 2015 to fẹ dije.

Iná ṣẹ́yọ lẹ́bàá mọ́ṣálááṣí Anabi ní Medina

Oríṣun àwòrán, Twitter/Haramain Sharifain

Ina ṣẹyọ lẹgbẹ mọṣalaaṣi Anabi Mohammad ni Medina ni orilẹede Saudi Arabia.

Oriṣiiriṣii fidio to lu ori opo Twitter pa ṣe afihan bi ina ọhun ṣe n jo ile kan, to wa lẹgbẹ mọṣalaaṣi Anabi ti eefi ṣi gbalẹ nibẹ.

Ko si ẹni to kọkọ mọ ohun to ṣe okunfa iṣẹlẹ ọhun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ, wọn ti pada pa ina ọhun to n jo bi ina sufuru tẹlẹ.

Haramain Sharifain to fi awọn fidio naa lede loju opo Twitter rẹ sọ pe, kete tawọn oṣiṣẹ alaabo Civil Defence de ibi iṣẹlẹ naa ni wọn pana ọhun.

Gbogbo bi iṣẹlẹ naa ti waye kawọn panapana to de lo wa ninu fidio ti Sharifain fi soju opo Twitter rẹ.