CCT Tribunal: Alága CCT fèsì lórí fídíò kan tó ṣàfihàn bó ṣe ń fìyà jẹ ẹsọ kan

Aworan ifiyajẹni

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Alaga igbimọ onidajọ to n gbọ ẹsun asemase nidi ihuwasi osisẹ ọba atawọn to dipo oselu mu, Code of Conduct Tribunal, Adajọ Danladi Umar ti fesi lori fidio kan to gbode eyi to se afihan rẹ.

Fidio naa, to ti gba ori ayelujara kan, lo safihan Umar to fa ibinu yọ nile itaja igbalode kan ti wọn n pe ni Banex to wa ladugbo Wuse keji nilu Abuja nibi to ti n lu ẹsọ alaabo ile itaja naa.

Umar lo lu ipa si ẹsọ alaabo ọhun, ko to di pe wọn gba ọkunrin naa mu, tawọn ọlọpaa si gbe ju sinu ọkọ wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ nigba to n fesi lori fidio ifiyajẹni naa, Umar ni ẹsọ ibudo itaja naa lo yaju si oun, to si n halẹ mọ oun.

Oríṣun àwòrán, NTA

Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun igbimọ olugbẹjọ CCT, Ibraheem Al-Hazzan fisita lori isẹlẹ naa lo sisọ loju ọrọ Umar yii.

Ohun to jẹ yọ ni pe Umar ati ẹsọ alaabo naa ni wsn dijọ n tahun sira wọn ni ibudo igbọkọsi to wa nile itaja naa lọjọ Aje, eyi to papa di ija.

Umar la gbọ pe o lọ sile itaja igbalode Banex lọjọ Aje lati lọ tun ẹrọ ibaraẹnisọrọ rẹ to bajẹ se nibẹ.

Ni kete to si de ibudo itaja naa, ni awakọ rẹ gbe ọkọ si aaye kan to sofo nibudo igbọkọsi ile itaja ọhun.

Amọ ẹsọ to wa lọọkan nibudo naa tete pariwo pe ki wọn mase gbe ọkọ wọn gunlẹ si aaye to sofo naa.

Sugbọn se ni alaga igbimọ olugbẹjọ CCT naa yari pe awakọ oun ko gbọdọ gbe ọkọ naa kuro ni aaye to wa naa.

Nigba to n salaye bi isẹlẹ naa se waye, Al-Hassan ni aawọ naa bẹrẹ nigba ti ẹsọ ile itaja naa ko le se alaye to yẹ lori idi ti Alaga CCT ko fi gbọdọ gbe ọkọ rẹ duro ni aaye to sofo naa.

"Bi o tilẹ jẹ pe alaga CCT naa ko sọ iru eeyan to jẹ fun, amọ ẹsọ naa yaju si pupọ, to si ni oun yoo se alaga awọn bii ọsẹ tii se oju, ti ko ba gbe ọkọ rẹ kuro nibẹ.

"To ba jẹ pe ọga wa lọ sile itaja naa ni lati fa wahala tabi dunkoko mọ ẹnikẹni gẹgẹ bi awọn eeyan kan se n sọ, yoo lọ sibẹ bii ọlọla ni pẹlu awọn ẹsọ alaabo rẹ.

Àkọlé fídíò,

Blighted Ovum: Obìnrin kan sọ ohun tójú rẹ̀ rí nígbà tí oyún bàjẹ́ lára rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹta

Amọ Umar nikan lo lọ pẹlu aburo rẹ ọkunrin, ọlọpa to si han ninu fidio naa, kii se ikọ ọlọpa fun alaga igbimọ CCT."

O ni ọlọpaa naa lo n sisẹ ni agbegbe ti ibudo itaja naa wa, ẹni to kọkọ da si aawọ naa, ko to di pe awọn ikọ ọlọpaa lati agọ ọlọpaa Maitama de sibẹ.

"Se ni awọn ikọ janduku kan to wa ninu ile itaja naa bẹrk si ju ada ati ohun ija oloro mọ ọkọ ọga Umar, eyi to mu ọgbẹ ba ni ọmọ ika ọwọ rẹ kan.

Koda, mọto rẹ bajẹ, ti wọn si fọ digi iwaju ọkọ naa."