Oduduwa Nation: Femi Falana ní ọ̀nà láti pọ́n aráàlú lójú ni ìpè fún ìyapa Nàíjíríà

Femi Falana ati ami idamọ Naijiria

Ogbontarigi agbejọro agba ni Naijiria, Femi Falana, ti sọ pe elero kukuru ni awọn to n polongo pe ki Naijiria o pín si ẹlẹyamẹya. Ninu ifọrọwanilẹnu kan to ṣe pẹlu ileesẹ iroyin abẹle kan, Root TV, ni Falana ti sọ pe orilẹ-ede Naijiria ni awọn aláwọ̀ dúdú pọ si julọ ni agbaye.

O fikun pe o yẹ́ ka se gbogbo ohun to ba yẹ́ lati ri daju pe orilẹ́ede Naijiria duro re ni, ọpọ to si n beere fun ipinya Naijiria nilana ẹlẹyamẹya ni ko ni oju inu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Agba amofin naa fikun pe ọna lati lo anfaani ifiyajẹni, lilọ ni lọwọ gba, to wa ninu isejọba Naijiria, fun ominira ara wọn ni wọn n wa. "Ko si ẹnikẹni ninu wọn to n gbero eto ẹ̀kọ́ to dara tabi ọrọ aje ti yoo pin ọrọ̀ kari, ni orilẹ-ede ti wọn fẹ ẹ da silẹ.

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho

Oun to jẹ wọn lógún ni lati ni ominira ti yoo fi aaye gba wọn láti tẹsiwaju ninu pipọn araalu lójú. Eyi ti ko le ṣe e ṣe." O beere pe njẹ awọn eeyan to n kede orilẹ-ede tuntun lori ayelujara ti gbọ́ èrò awọn araalu lati mọ boya wọn fẹ ya kuro ni ara Naijiria. " Ko si ẹnikẹni to beere. "

"O ni awọ̀n eeyan kan ji lọjọ kan ni wọn kede pe a n lọ kuro lara Naijiria, lọ sibo? O yẹ ka kọkọ wa ojutu si aini idagbasoke Naijiria na."

Àkọlé fídíò,

Kò sí ìgbà kankan tí Yorùbá jókòó pé ki Igboho lọ kéde ìyapa kúrò ní Nàíjíríà

Femi Falana wa woye pe ọ̀pọ̀ isoro tawọ̀n eeyan kan n lọ̀gun pe gẹgẹ bii awawi lati ya kuro lara Naijiria lo jẹ isẹ́ ọwọ awọn eeyan, afọwọfa ẹda ni.

O fikun pe ko ohun to le, ti ko ni dẹ, ka sa ni suuru nitori awọn isoro to ni ojutu ni awọ̀n eeyan kan mu lọwọ lati maa polongo iyapa Naijiria.O ṣalaye pe nkan to ṣe koko ni lati wa ọna abayọ si awọn ìṣòro ti orile-ede Naijiria ni.