Jaiye Kuti: Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mò n fi ẹ̀rín bo omijé mọ́lẹ̀ láti bo àṣírí ara mi

Jaiye Kuti

Oríṣun àwòrán, jayeola_monje/ Instagram

Yoruba ni onikaluku abi tiẹ lara, gbogbo asọ si kọ laa sa ninu oorun nitori asọ lo bo asiri isoro ẹda.

Bẹẹ lọrọ ri fun gbajugbaja oṣerebinrin kan ninu tiata Yoruba, Jaiye Kuti, ẹni to sọ pe ọpọlọpọ igba ni oun n fi ẹ̀rín bo omijé oju oun mọ́lẹ̀.

Ninu ọrọ kan to kọ sori ayelujara Instagram rẹ, arẹwà oṣerebinrin naa sọ pe lootọ ni oun ma n rẹrin ni gbogbo igba, àmọ́ ko tumọ si pe inu òun maa n dùn ni igba gbogbo.

"Mo ma n wa ninu awọn ipò to ma n mu mi sunkun lọpọ igba nitori mo n la awọn iriri kan kọja to maa n jẹ ki omije da silẹ loju mi."

Oríṣun àwòrán, jayeola_monje/ Instagram

" Ẹni to jade wa lati inu iriri to ṣòro lati gbagbọ ni mi, sugbọn imoore nikan lo gbe mi ro nitori ẹni to ba ni ọkan ọpẹ nikan lo ni ọrọ̀."

Gbajugbaja oṣere naa ṣalaye pe, ọpọlọpọ igba ni oun ti kuna, to si ma n jẹ ìnira fun oun lati dìde pada.

O ni nkan ẹyọ kan ṣoṣo ti oun ma n se lasiko naa ni ki oun sọ omijé di oúnjẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni bo tilẹ jẹ pe oun n sisẹ takuntakun lati tọju ẹbí oun, ati lati ṣe iranlọwọ fun awọn eeyan niwọnba ti agbara oun ká, sibẹsibẹ, òun n sunkun.

Àkọlé fídíò,

Blighted Ovum: Obìnrin kan sọ ohun tójú rẹ̀ rí nígbà tí oyún bàjẹ́ lára rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹta

O gba awọn ololufẹ rẹ ni imọran láti mọ riri, ki wọn si gbádùn gbogbo anfaani ti wọn ba ri gba, nitori pe to ba di ọjọ iwaju, wọn o ri pe nkan nla ni, to si se babara pupọ.

O ni oun dupẹ lọwọ gbogbo àwọn to ti ni ipa lori ayé òun, fun ifẹ ati atilẹyin wọn lọna kan abi omiran.