Herdsmen Attack: Adebanjo ní àwọn ọ̀dọ́ ní ìjọba ń fìyà jẹ pẹ̀lú àìkáátò rẹ̀

Sunday Igboho ati Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, Twitter

Adari kan ninu ẹgbẹ ọmọ Yoruba Afenifere, Oloye Ayo Adebanjo ni ọpọlọpọ awọn ọdọ ajijagbara bii Sunday Igboho ati Nnamdi Kanu ni yoo dide ti ijọba apapọ ko ba ṣe oun to yẹ.

Baba Adebanjọ ni iṣekupani ojojumọ ti pọju lorilẹede Naijiria, ni awọn ọdọ ṣe n dide lati gba ara wọn la.

O ni awọn ọdọ ni ijọba n koju pẹlu aikaato eto akoso rẹ, nitori naa, wọn ko le e da wọn duro.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

''Ọjọ ti pẹ ta ti n pariwo ki ijọba ṣe atunto orilẹede Naijiria, amọ wọn kọ eti ikun si ọrọ wa.

O yẹ ko ye ijọba pe o n fi ina si ibinu awọn ọdọ ni Naijiria nitori pe o kọ lati ṣe atunto orilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò,

Kò sí ìgbà kankan tí Yorùbá jókòó pé ki Igboho lọ kéde ìyapa kúrò ní Nàíjíríà

Ijọba yẹ ko fun awọn ẹkun to wa ni Naijiria laaye lati ṣakoso ohun ini wọn funra wọn ni''

Ẹya Igbo naa figbe ta pe awọn ko fẹ jiya lọwọ ọdaran darandaran mọ

Bakan naa ni ẹgbẹ awọn ẹya igbo, Nigeria Patriotic Youth Against Corruption and transparency, ni awọn ko ni gba fun awọn Fulani darandaran lati wa si ilẹ awọn, ki wọn si ma a jẹ awọn eniyan wọn ni iya.

Adari ẹgbẹ naa, Oloye Emmanuel Iwuayanwu ni awọn adari ni ilẹ igbo yoo dide lati gbogun ti ipaniyan awọn ẹbi ati ara awọn ni ilẹ Igbo, paapaa ni ipinlẹ Ebonyi.

''Nkan buburu lo n ṣẹlẹ ni Naijiria, o buru jai ki awon Fulani darandaran ma a pa eniyan kaakiri lai si pe wọn ti ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ.''

Àkọlé fídíò,

Cattle Ranching: Ẹ wo Fulani darandaran to tako àṣà dída màálù kiri lójú pópó

''Nibayii awọn ọdọ lati ipinlẹ mẹtadinlogun lorilẹede Naijiria ti kesi awọn darandaran to n paniyan, ki wọn kuro ni agbegbe naa ni kiakia lai wọ ẹyin.''

Bakan naa ni wọn kilọ fun ijọba lati jawọ igbeṣẹ fifi panpẹ mu awọn ọdọ to n ja fun ẹya wọn bii Alhaji Asari Dokubo, Sunday Igboho ati Nnamdi Kanu.

Ọpọlọpọ awọn eniyan lo sọrọ tako iṣekupani to n waye ni Guusu orilẹede Naijiria lati ọwọ awọn afurasi Fulani darandaran.

Afúrasí darandaran tó pa ènìyàn 15, jó ọ̀pọ̀ dúkìá ni Ebonyi ti bọ́ sí àhámọ́ ọlọ́pàá

Gomina ipinlẹ Ebonyi, David Umahi ọwọ awọn ti tẹ awọn afurasi darandaran to ṣekọlu awọn ijọba ibilẹ bii mẹrin ni ipinlẹ naa.

Gomina Umahi lo sọ ọrọ yii lasiko to ṣe abẹwọ si ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ni ijọba ibilẹ Nkalaha, Obegu, Umuhuali ati Amaezu.

Umahi ni awọn marundinlogun lo ku ninu ikọlu naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

''A ti ri awọn to sekọlu si awọn eniyan ijọba ipinlẹ yii, ti a si ti ri awọn to ran wọn ni iṣẹ''

''Mo si ti bẹrẹ si ni ba awn eniyan sọrọ ti iṣẹlẹ naa ṣe ijamba fun, ati ki awọn eniyan ma gbe ija ara wọn ja.''

''Ibanujẹ ọkan lo jẹfun mi pẹlu iṣẹlẹ to waye ni Ebọnyi ati bi awọn darandaran to wa nmi agbegbe naa ṣe sa asala fun ẹmi wọn, ki awọn eniyan ma ba a pa wọn''.

Gomina ipinlẹ Ebonyi ni ti iṣẹlẹ ikọlu awọn Fulani darandaran yii ba tẹsiwaju kaakiri orilẹede Naijiria, o le da ogun abẹle.

Ẹni ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ni awọn agbegbọn naa kọlu pẹlu ikọ ati ada ti wọn si fi ọbẹ le awọn eniyan kuro nibẹ.

O tun fikun wi pe wọn pa alfa ijọ Methodist to wa nibẹ, ti wọn si ko ọpọlọpọ dukia awọn eniyan lọ nibẹ.

Amọ, ijọba bu ẹnu atẹ lu bi awọn eniyan ṣe fiyajẹ awọn afurasi ti wọn ri lagbagbe naa, jungle justice lai fi idi rẹ mulẹ pe awọn gan an lo ṣiṣẹ ibi ọhun.

Gomina ipinlẹ Ebonyi, David Umahi ni iwadii ṣin tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa.

Akwa Ibom state Attack: Àwọn agbébọn pa ọ̀pọ̀ ọlọ́pàá, ṣọ́jà, wọ́n tún jó ọ̀pọ̀ ọkọ̀ ní Akwa Ibom

Oríṣun àwòrán, DIANAIME UKO

Nnkan ko fi gbogbo ara rọgbọ ni ijọba ibilẹ Essien Udim ni ipinlẹ Akwa Ibom, lẹyin ti awọn agbebọn kan lọ kọlu awọn ọkọ ọlọpaa atawọn ologun to n mojuto eto abo nibẹ.

Awọn agbebọn naa ti wọn to aadọta ni iye ni wọn ni wọn n tako alaga ijọba ibilẹ naa, ti wọn si tipa bẹẹ kọlu awọn ọlọpaa ati ọmọ ogun ti wọn ko lọ si ibẹ lati pẹtu si awọ.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, ọga ọlọpaa kan ti orukọ rẹ n jẹ Benedict Okoh Ajide atawọn ọlọpaa miran ni awọn agbebọn naa pa ni owurọ ọjọ Iṣẹgun ọgbọn ọjọ oṣu kẹta ọdun 2021.

Oríṣun àwòrán, DIANAIME UKO

Ohun ti BBC News gbọ nibẹ ni pe, awọn agbebọn naa jo ile ọga ọlọpaa, CSP Ajide, koda ọta ibọn ba eeyan kan to n kọja ls ni tirẹ to si gba ibẹ ku.

Bakan naa ni wọn tun da ina sun awọn ọkọ Hilux kan, wọnṣe awọn ọlọpaa miran leṣe bi o tilẹ jẹ pe a ko lee sọ iye wọn.

Bawo lo ṣe ṣẹlẹ ati pe ki lo fa sababi?

Ni nnkan bii ọsẹ mẹrin sẹyin, awọn agbebọn kan kọlu agọ ọlọpaa kan ti wọn si da ina sun apakan agọ ọlọpaa naa titi kan awọn aloku ọkọ kan ti wọn wa kalẹ si ọgba agọ ọlọpaa naa.

Ikọlu yii lo mu ki ijọba ipinlẹ Akwa Ibom fofin de lilo alupupu ọkada tabi kẹkẹ marwa nibẹ lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹta ọdun 2021.

Ijọba ibilẹ Essien Udim atawọn ijọba ibilẹ meji miran ni aṣẹ naa kan, laarin agogo mẹfa irọlẹ si meje aarọ lati dẹkun iwa ọdaran nibẹ.

Ni bi a ṣe n sọrọ yii, ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Akwa Ibom ko tii sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ naa.