Buhari: PDP àtàwọn àjọ míì figbe ta lórí èsì ìwádìí Amẹ́ríkà nípa ìjọba Buhari

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Other

Orilẹ-ede Amẹrika ti fẹsun kan ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari pe iwa ajẹbanu ti pọju labẹ ijọba rẹ.

Bakanna ni Amerika sọ pe ijọba Buhari ko faye gba ẹtọ ọmọniyan lati sọrọ lawujọ papaa julọ lọdun 2020.

Ilẹ Amerika sọrọ yii ninu esi iwadii rẹ lori ẹtọ ọmọniyan lorilẹede Naijiria lọdun 2020.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Orilẹ-ede Amẹrika sọ ninu atẹjade ọhun pe iwa ibajẹ pọ kaakiri labẹ ijọba Buhari to fi mọ ẹka eto idajọ ati eto abo.

Ninu eleyi to tako igbesẹ ijọba to wa lode lati gbogun ti iwa ajẹbanu, ẹka ijọba ilẹ Amerika to n ri si ọrọ ilẹ okeere sọ pe ẹsun iwa ibajẹ ni ijọba lọdun 2020 pọju.

Àkọlé fídíò,

'Èmi àti ìyàwó mi ti ń gbé pọ̀ nínú ìgbéyàwó wa fún 60 years', ẹ wá kọ́ ẹ̀kọ́ lẹ́nu àgbà méjì

Orilẹ-ede Amẹrika fi iwadii ati bi wọn ti fi ọwọ ofin mu alaga ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ibajẹ, Ibrahim Magu lori ẹsun iwa ajẹbanu ṣe àpẹẹrẹ.

Amerika tun sọ ninu atẹjade naa pe ọpọ ẹjọ iwa ibajẹ ni ko tii niyanju ni Naijiria nitori bi wọn ṣe n fi falẹ.

Bakanna ni orilẹ-ede Amẹrika fẹsun kan ijọba Buhari pe o n dunkoko mawọn akọroyin lẹnu iṣẹ wọn.

Atẹjade naa ṣalaye pe awọn oloṣelu n lo awọn ẹṣọ eleto abo lati huwa ipa s'awọn akọroyin to n ṣiṣẹ lori titẹ ẹtọ.

Àkọlé fídíò,

Bí Oduduwa Republic bá bẹ̀rẹ̀, a ò ní ṣe aburú fún àwọn tó takò wá, ìlànà ààtẹ̀lé rèé - Banji Akintoye

Koda, atẹjade ọhun sọ pe awọn akọroyin kan ṣagbako iku ojiji lẹnu iṣẹ wọn ni Naijiria lọdun 2020.

Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu alatako PDP ati aarẹ ajọ to n ri si ẹrọ ọmọniyan tẹlẹ rí, Malachy Ugwumadu ti dẹnu bo ijọba Buhari lori atẹjade naa.

Akọwe iroyin fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Kola Ologbondiyan ni otitọ ni orile-ede Amerika sọ ninu atẹjade to fi sita lori ijọba Aarẹ Buhari.

"Gbogbo eeyan lo mọ pe ijọba Buhari lo tẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ julọ.

Àkọlé fídíò,

Omi iké kan, l'èèyàn kan lè mu f'ọ́jọ́ mẹ́ta láì ro ti ekòló inú rẹ̀ - Ìlú Elega, Kwara

Koda, titẹ ẹtọ ọmọniyan mọlẹ labẹ ijọba Buhari buru ju ti ijọba ologun Sani Abacha," Ologbondiyan lo sọ bẹẹ.

Oludasilẹ ajọ to n ri si ọrọ ijọba awaarawa, Ariyo-Dare Atoye ni atẹjade orilẹ ede Amẹrika ṣapejuwe bi iwa ibajẹ ṣe gbilẹ to ni ijọba Buhari.

Wo àbọ̀ ìwádìí Amẹ́ríkà lórí ìkọlù ológun tó wáyé ní Lekki

Oríṣun àwòrán, EPA

Orilẹede Amẹrika ti kede pe ọpọ awọn iroyin tawọn ileesẹ iroyin labẹle ati lagbaye kọ nipa pe ibọn yinyin sawọn oluwọde waye lẹnu ibode Lekki, ni oun ko le fi idi rẹ mulẹ.

Bẹẹ ba gbagbe, ogunjọ osu Kẹwa ọdun 2020 ni iroyin gbode pe awọn ọmọ ologun kan lọ yinbọn mọ awọn ọdọ to n se iwọde ENDSars lẹnu iloro Lekki, ti ọpọ si gbẹmi mi.

Ilẹ Amẹrika fi ero rẹ yii han ninu ikede abọ iwadi rẹ lori awọn ẹsun ti ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan fi kan ijọba Naijiria ati ileesẹ ologun ilẹ wa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atẹjade ọhun, ti wọn fisita lọjọ Isẹgun lo tẹnumọ pe awọn iroyin to jade nipa oku to sun lẹnu iloro Lekki lasiko ENDSars ko de ọdọ oun titi ti ọdun 2020 fi pari.

Oríṣun àwòrán, EPA

"Ajọ Ajafẹtọ ẹni Amnesty kede pe eeyan mẹwa lo jalaisi lasiko ikọlu naa amọ ijọba Naijiria tako iroyin ọhun, bẹẹ si ni ko si ẹgbẹ miran to fidi ootọ ọrọ mulẹ nipa rẹ.

Eeyan meji pere ni ijọba lo jade laye nipa isẹlẹ ọhun, oku kan ti wọn ri lẹnu iloro Lekki naa lo safihan pe o la wahala kọja, nigba ti oku keji ti wọn ri ni agbegbe kan nigboro Eko, ni ọgbẹ ọta ibọn lara.

Àkọlé fídíò,

Blighted Ovum: Obìnrin kan sọ ohun tójú rẹ̀ rí nígbà tí oyún bàjẹ́ lára rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹta

Nigba ti ọdun fi pari, igbimọ olugbẹjọ ẹsun ifiyajẹni ti wọn fi kan awọn ọlọpaa to n joko nilu Eko si n gbọ ẹsun latẹnu awọn ti ọrọ naa kan, ti iwadi lori ipaniyan Lekki si n tẹsiwaju."