Sunday Igboho: YCE ní ọ̀pọ̀ ìgbà ní Miyetti Allah sọ̀rọ̀ àbùkù, tí kò sẹ́ni tó gbé wọn

Oga Agba ọlọpaa ati Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, TWITTER

Àkọlé àwòrán,

Sunday Igboho ke gbajare sita pe gende mẹẹdogun mu iwe wa sile oun pe Ọga ọlọpaa fẹ ri oun.

Ẹgbẹ agbaagba nilẹ Yoruba, YCE ti fi atilẹyin wọn han si bi ajijagbara ati ajafẹtọ ẹni nni, Sunday Igboho ṣe kọ lati tẹwọ gba iwe ipe ti ọga agba ọlọpaa fi n pe e wa si Abuja.

Akọwe agba fẹgbẹ YCE, Dokita Kunle Olajide lo fi atilẹyin rẹ han wipe, o dara bi Igboho ṣe kọ ipe naa, nitori ejo lọwọ ninu.

Olajide ni Igboho lasẹ lati mase tẹwọ gba iru lẹta bẹẹ lọwọ awọn ti ọga agba ọlọpaa fi ran nitori bi nkan ṣe ri lorilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

''O buru jai ki Ọga agba ọlọpaa fi iwe pe Igboho lati ilu Ibadan wa si ilu Abuja pẹlu bi oju ọna ṣe ri lorilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò,

Sunday Igboho latest: Sunday Igboho kò gba 'Award'ti a fún un ní Ogo Yorùbá nítorí inú rẹ̀

''Ti awọn ọlọpaa ba ni ibeere fun Igboho, awọn ọga ọlọpaa to wa ni ilu Ibadan le ṣoju Ọga ọlọpaa, lai si wi pe wọn rin irinajo lọ si ilu Abuja."

Akọwe ẹgbẹ awọn agbaagba ni ilẹ Yoruba naa ni ki ọga agba ọlọpaa tẹle ilana awọn ọlọpaa nitori o ni awọn kọmiṣọna ni abẹ rẹ, to le ṣiṣẹ fun un ni ilu Ibadan lai de Abuja.

''Nitori to ba jẹ emi naa, n ko ni gba lẹta ọhun, nitori a ti ri awọn to gba lẹta saaju ri, to jẹ ado oloro to bu gbamu lo wa ninu rẹ''

''O tilẹ lewu ki eniyan gbera lati ilu Ibadan lọ si ilu Abuja pẹlu bi awọn oju ọna ṣe lewu lati gba lasiko yii.''

Àkọlé fídíò,

Pure Water Lylon Art: Adejoke ní ohun èlò ta fi ọ̀rá ṣe ń ní àlòpẹ́, kìí tètè jẹ

Bakan naa lo kesi ẹka eto aabo lorilẹede Naijiria lati ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ, ki wọn ye e fari apa kan, da apa kan si ni idi iṣẹ wọn.

Kunle Olajide fikun wi pe, ọpọ igba ni ẹgbẹ awọn Fulani darandaran, Miyetti Alah ti n sọrọ kubakugbe lori afẹfẹ, ti ko si si ẹni to fi iwe pe wọn, ki wọn wa jẹjọ.

Àwọn èèkàn ọmọ Yorùbá tí ìràwọ̀ Sunday Igboho bo tiwọn mọ́lẹ̀, ló ń dọdẹ rẹ̀ - Fani-Kayode

Oríṣun àwòrán, femi fani Kayode

Awọn ọmọ Yoruba kan ti n fesi lori iwe ipe ti ọga agba ọlọpaa fi ransẹ si ile Oloye Sunday Igboho lọjọbọ.

Sunday Igboho lo pariwo sita pe awọn eeyan kan, ti wọn pe ara wọn ni ọlọpaa, mu iwe kan wa si ile oun.

O ni awọn gende mẹẹdogun to wa sile oun naa sọ pe ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria lo n pe oun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ nigba to n fesi lori isẹlẹ yii, Minisita feto irinna ofurufu tẹlẹ, Fẹmi Fani Kayode ke si ijọba apapọ pe ko ṣe pẹlẹ lori ọrọ Sunday Igboho.

Oríṣun àwòrán, femi fani-kayode

Fani-Kayode, ẹni to se ikilọ naa loju opo Twitter rẹ ni ko ni dara ki ijọba apapọ fi ọwọ ara rẹ da wahala ti ko ni lee pari silẹ.

Fani Kayọde ṣalaye pe, o daju pe awọn eekan ọmọ Yoruba kan to woye pe, okiki ati ọla ti Sunday Igboho n ni lojoojumọ, ti fẹ bori tiwọn, lo wa nidi ọrọ yii.

O ni awọn ọmọ Yoruba naa, ti wọn ri pe irawọ Igboho ti fẹ bo irawọ tiwọn mọle ni wọn n ko si ijọba aarẹ Buhari ninu pe ko fi panpẹ ofin gbe Sunday Igboho.

Oríṣun àwòrán, @realFFK

"...fifi papnpẹ ofin gbe Igboho ko lee ran awọn eeyan wọnyi lọwọ ninu ilepa oṣelu wọn. Yoo kan tun tubọ jẹ ko ṣoro fun wọn lati mu erongba oṣelu ti wọn ni ṣẹ ni."

O fi kun pe ni ilẹ to mọ loni yii, oun ko lero pe Sunday Igboho tii ṣe ohunkohun to tapa si ofin orilẹede Naijiria.

Ohun kan to ṣe naa ko ju wi pe o duro fun erongba ati ilepa awọn ọmọ Yoruba to le ni aadọrin miliọnu.

Oríṣun àwòrán, @realFFK

O ni Igboho ni ọpọ ọmọ Kaarọ oojire n wo gẹgẹ bii akinkanju ilẹ Yoruba, lẹyin Oduduwa to tẹ ilẹ naa gan do.

Oloye Fẹmi Fani Kayọde wa ke si ijọba aarẹ Buhari pe, dipo wiwa ọna ati mu Igboho tabi ṣeku paa, o yẹ ki wọn wa ọna ati joko baa jiroro lori ohun to n ja fun ni.

O ni erongba rẹ naa ko si sẹyin didẹkun gulegule awọn ọdaran darandaran Fulani to n da hilahilo silẹ lẹkun ilẹ Yoruba.

Oríṣun àwòrán, @realFFK

"Maa sọ ọ lẹẹkan yii pe, ohun kan to fẹ ti igi bọ oju alaafia ati iduro ṣinṣin orilẹede Naijiria loni yii ni bi awọn eeyan kan

Ni ijọba Buhari ṣe n gbero lati pa, tabi fi panpaẹ ofin mu ọrẹ mi ati eeyan mi, Oloye Sunday Adeyẹmo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho."