Pure Water Lylon Art: Adejoke ní ohun èlò ta fi ọ̀rá ṣe ń ní àlòpẹ́, kìí tètè jẹ

Pure Water Lylon Art: Adejoke ní ohun èlò ta fi ọ̀rá ṣe ń ní àlòpẹ́, kìí tètè jẹ

Ori lo mọ isẹ asela, bẹẹ si ni atẹlẹwọ ẹni kii tan ni jẹ.

Adejoke Lasisi ree, ẹni ti isẹ ọọfisi wu lati se amọ to pada n fi isẹ ọwọ bu okele sẹnu lai wa isẹ sarafinni kiri mọ.

Adejoke, ẹni to n fi aloku ọra Pure Water atawọn aloku asọ se asọ oke eyi to n lo lati se baagi, bata, ẹni atẹẹka ati bẹẹ bẹẹ lọ, ba BBC Yoruba sọrọ nipa ohun to gbe de idi isẹ yii.

Inu isẹ asọ oke tita ni wọn bi Adejoke si amọ o ni oun korira idọti ni oun se ronu nnkan ta le fi aloku ọra ati asọ se.

Bakan naa lo ni ọpọ anfaani lo wa ninu awọn eroja ti oun n se jade nitori o maa n ni alopẹ, ti kii si tete bajẹ nitori eroja ọra funra rẹ kii jẹ mọlẹ.

Adejoke fikun pe, amulo aloku ọra yii lati fi se ohunmere-mere n pese isẹ oojọ, yoo si tun n mu ki ọrọ aje Naijiria ru gọgọ si tawọn eeyan ba le tẹwọgba.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O tẹsiwaju pe ti aaye ba si silẹ lati maa ko eroja ti wọn fi aloku ọra se lọ soke okun fun tita, pasipaarọ owo Naira wa si owo ilẹ okeere yoo tun lowura si.