Yinka Odumakin: Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa agbẹnusọ Afenifere tó dolóògbé

Yinka Odumakin

Oríṣun àwòrán, dapo Abiodun

Aarọ ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin, ọdun 2021 ni iroyin gbode pe ọkan ninu awọn asaaju ẹgbẹ ọmọ bibi ilẹ Yoruba, Oloye Yinka Odumakin ti dagbere faye.

Odumakin, nigba aye rẹ ni agbẹnusọ fun ẹgbẹ Afenifere, to n sọrọ lorukọ ẹya Yoruba lori awọn isẹlẹ to n waye nilẹ wa.

Lati igba ti iroyin naa ti jade ni ọpọ awọn eekan ilu atawọn oloṣelu ti bẹrẹ si n fi ọrọ ẹdun lede lori iku akọni ọhun.

Awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa Yinka Odumakin ree.

  • Ọjọ kẹwaa, ninu oṣu kejila ni wọn bi Yinka Odumakin
  • O kawe gboye ni fasiti Obafemi Awolowo, niluu Ile Ife lọdun 1989
  • Lasiko to jẹ akẹkọọ ni fasiti, oun ni agbẹnusọ fun ẹgbẹ awọn akẹkọọ, iyẹn SUG
  • O bẹrẹ iṣẹ akọroyin nileeṣẹ iwe iroyin Punch to wa niluu Eko, lẹyin naa lo darapọ mọ iwe iroyin Guardian
  • Akọni ọhun wa lara awọn to gbogun ti ijọba ologun labẹ iṣakoso ọgagun Sani Abacha lẹyin to da ibo Aarẹ nu lọjọ kejila, oṣu Kẹfa, ọdun 1993 ti gbogbo eeyan gbagbọ pe o gbe oloogbe MKO Abiola wọle sipo Aarẹ
  • Odumakin kopa ninu ipade apapọ orilẹ-ede Naijiria, National Confab, to waye niluu Abuja lọdun 2014
  • Aarẹ Muhammadu Buhari yan Odumakin gẹgẹ bii agbẹnusọ ikọ ipolongo rẹ nigba to n mura idibo Aarẹ lọdun 2011
  • Odamakin gbe ajafẹtọ bii tirẹ ni iyawo, iyẹn Joe Okei-Odumakin, wọn si jọ wa titi di akoko ti ọlọjọ de
  • Ko tan sibẹ, Odumakin tun ṣiṣẹ gẹgẹ bii akọwe ẹgbẹ ajafẹtọ Save Nigerian Group ti Pasitọ Tunde Bakare ṣagbatẹru rẹ lọdun 2010
  • Titi di igba ti ọlọjọ de, Odumakin ni agbẹnusọ fun ẹgbẹ ọmọ Yoruba, Afenifere, o si wa lara awọn to n bu ẹnu ẹtẹ lu bii awọn ọdaran darandaran ṣe n pa eeyan kaakiri ilẹ Yoruba

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Ọ̀pọ̀ ọmọ Yorùbá ń ṣèdárò Yinka Odumakin tó di olóògbé

Oríṣun àwòrán, Joe Odumakin

Yoruba ni bi ọdẹ ba ku, ọdẹ ni yoo se oro lẹyin ọdẹ, ba si ku la dere, eeyan ko sunwọn laaye.

Ọpọ ọmọ ilẹ kaarọ oojire lo ti n sedaro iku agba ọmọ Yoruba to jade laye, Oloye Yinka Odumakin.

Ile iwosan ẹkọsẹ isegun fasiti ipinlẹ Eko, LASUTH ni Odumakin dakẹ si lasiko aisan ranpẹ to se e.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ ba se gbọ, ẹka ile iwosan naa, ti wọn ti n tọju awọn eeyan to ni arun Coronavirus ni Odumakin mi kanlẹ si ni idaji ọjọ Abamẹta.

Oríṣun àwòrán, Joe Odumakin

Nigba to n fi idi iku ọrọ rẹ mulẹ fawọn akọroyin, aya oloogbe naa, Ọmọwe Joe Odumakin ni manigbagbe ni iku oloogbe naa jẹ fun oun.

"Ọkan lara ẹya ara mi lo lọ yii."

YCE ni iku doro

Nigba tawọn naa n se idaro ẹni rere to lọ, Ọjọgbọn Banji Akitoye sọ fun BBC Yoruba pe akikanju ọmọ Yoruba lo papoda yii, igi nla lo da nigbo.

Lero ti akọwe fun ẹgbẹ agbaagba ilẹ Yoruba, YCE, Dokita Kunle Olajide ni "Iku doro, erin wo, igi da, Ajanaku sun bi oke, ẹni re lọ."

Dokita Olajide ni alafo nla ni iku Odumakin yoo fi silẹ ninu iran Yoruba nitori ipa akikanju to ko fun ilọsiwaju iran rẹ lasiko to wa loke eepẹ.

Akọwe ẹgbẹ agbaagba fun ilẹ Yoruba naa wa gbadura pe ki ọba oke tẹ Odumakin si afẹfẹ rere.

Àkọlé fídíò,

Pure Water Lylon Art: Adejoke ní ohun èlò ta fi ọ̀rá ṣe ń ní àlòpẹ́, kìí tètè jẹ

Afenifere sọ̀ pe adanu nla ni iku Odumakin

Bakan naa niakọwe ẹgbẹ Afenifere, Basorun Sehinde Arogbofa se apejuwe iku Odumakin bii adanu nla fun ẹgbẹ naa ati orilẹede Naijiria lapapọ.

Arogbọfa ni iku Odumakin ba oun lojiji, to si jẹ ẹsẹ nla to ba oun lairotẹlẹ nitori ẹni to sun mọ oun bii isan ọrun ni.

"Yinka ko ba ma lọ lasiko yii nitori ọlọpọlọ pipe ẹda ni, to si maa n mu awọn aba to kun fun ọgbọn wa, isẹlẹ yii ba mi ninu jẹ pupọ.

Arogbofa wa gbadura pe ki Ọlọrun tẹ oloogbe Yinka Odumakin si afẹfẹ rere.

Ìròyìn Yàjóyàjó - Yinka Odumakin, agbẹnusọ fẹ́gbẹ́ Afenifere, jáde láyé

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo ti ni ọkan ninu awọn asaaju ẹgbẹ ọmọ bibi ilẹ Yoruba, Oloye Yinka Odumakin ti dagbere faye.

Odumakin, nigba aye rẹ ni agbẹnusọ fun ẹgbẹ Afenifere, to n sọrọ lorukọ ẹya Yoruba lori awọn isẹlẹ to n waye nilẹ wa.

Nigba to n fi idi iku oloogbe naa mulẹ fun BBc Yoruba, Ọjọgbọn Banji Akintoye, tii se ọkan lara agbaagba ilẹ Yoruba sọ pe igi nla lo da nigbo Naijiria.

Yinka Odumakin si ni ọkọ gbajumọ ajafẹtọ ẹni lobinrin, Comrade Joe Odumakin.Iku doro, iku sika, iku ti mu ẹni re lọ.

A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin nipa itan igbe aye ati iku oloogbe Yinka Odumakin wa fun yin laipẹ.