Toyin Abraham: Ìyálàyá gbogbo yin, mo mọ àwọn olólùfẹ́ mi tí wọn ń gba tèmi

Toyin Abraham ninu asọ adura

Oríṣun àwòrán, toyin_abraham/Instagram

Yoruba ni arẹmaja kan ko si, ajamarẹ ni ko sunwọn nitori ahọn ati ẹnu maa n ja.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu gbajumọ osere tiata lobinrin kan, Toyin Abraham ati ololufẹ rẹ kan, ti wọn n tahun si ara wọn.

Bakan naa ni awọn mejeeji n sọ oko ọrọ sira wọn eyi to n ya ọpọ eeyan lẹnu pe ki lo le to eyi.

Ki ni ololufẹ Toyin Abraham sọ to fa ija?

Fiimu kan ti Niyi Akinmolayan gbe jade, ninu eyi ti Toyin Abraham kopa ninu rẹ lo fa ibẹrẹ aawọ naa.

Bẹẹ ba gbagbe, o ti ti ọjọ mẹta kan, ti Toyin ti n pariwo sinima naa lori ayelujara pe yoo jade, eyi to pe akori rẹ ni 'Prophetess'.

Ni kete ti sinima naa jade, lawọn eeyan ti n tu jade lọ sile sinima lati lọ wo fiimu naa, eyi to n mu ki awọn olootu sinima naa ri taje se, to fi mọ Toyin funra rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ ni kete ti sinima naa jade, ni ọkunrin kan ti wọn n pe ni Cinema Pointer,ẹni to gbajumọ nidi ka gbọn sinima wo yẹbẹyẹbẹ, ka si se agbeyẹwo bo se dara si, sọ ero rẹ nipa fiimu ọhun.

Lero ti Cinema Pointer, o ni agbeẹwo fiimu Prophetess ti oun se fihan pe "Kii se fiimu ti oun le ni ki awọn eeyan lọ wo rara.

Sinima naa ri rudurudu, to si kun fun ariwo lasan. Sinima Prophetess yii lo jẹ sinima oni wakati kan ati isẹju mẹrinlelogun to jẹ radarada."

Oríṣun àwòrán, toyin_abraham/Instagram

'Iyalaya gbogbo yin' ni esi ti Toyin fọ, to fa awuyewuye?

Ni kete ti Toyin Abraham ka agbeyẹwo ati ariwisi Cinema Pointer ni ibinu gba oju rẹ, to si fesi pada fun onitọhun pẹlu ara gbigbona.

"Mo le fọwọ gbaya pe eeyan kan to n sisẹ lagbo tiata ni ọ, ẹni to korira mi nitori ọwọ mi n lọ soke, ti o ko si lagbara lati da mi duro.

Gbogbo sinima ti mo ba ti kopa tabi gbe jade lo maa n bu ẹnu atẹ lu. Boya o ro pe emi lo gbe sinima Prophetess jade, amọ emi kọ lo ni, mo kan kopa ninu rẹ ni."

Toyin tẹsiwaju pe oun ni awọn ololufẹ toun ati agbo awọn to n ra ọja oun, oun si maa n fun wọn ni ohun ti wọn n fẹ.

"Se o mọ pe kii se wasa pe ki eeyan pa owo to to miliọnu lọna aadoje naira lasiko iwọde ENDSars ati igbele Coronavirus, ki n si tun ẹni osere tiata akọkọ fun aimọye ọsẹ loju mohunmaworan Neflix?"

Oríṣun àwòrán, cinemapointer/Instagram

Toyin wa la Cinima Pointer loye pe ọrọ to da lori ohun to n sẹlẹ lorilẹede Naijiria ni sinima Prophetess da le lori, to si wa fawọn ọmọ Naijiria, eyi ti ọmọ Naijiria se jade, ti inu rẹ ko si dun si.

"Cinema Pointer abi ẹnikẹni to wu ko jẹ tabi iru ẹni yoowu to ran ọ, mo fi ẹ silẹ ki ẹri ọkan rẹ maa jẹ ọ. N ko si ni fun s ni riba, gẹgẹ bi awọn eeyan yoku se n fun ọ, nitori naa, maa sọ isọkusọ to ba wu ọ sita, ki Ọlọrun se idajọ rẹ.

To ba wa jẹ pe lootọ lo fẹ ki n gba ariwisi rẹ gbọ, fi oju rẹ sita, jẹ ki n mọ ọ, ka jọ roju ara wa."

Ọrọ naa ko tii balẹ ti Cinema Pointer naa fi fesi pada fun Toyin pe ko mase se giragira nitori pe o pa aadoje miliọny naira lasiko igbele Coronavirus.

Oríṣun àwòrán, cinemapointer/Instagram

O ni sebi eeyan ni akẹẹgbẹ rẹ, Funke Akindele to pa ọtalelẹgbẹta (650m) lasiko naa, ti ko si pariwo, eelo wa ni aadoje miliọnu naira ti Toyin n sakọ si.

Ọpọ eeyan lo ti n fesi lori aawọ to n waye laarin awọn mejeeji naa, ti wọn si ni o yẹ ki Toyin le ni ara lati gba ariwisi si lati ọdọ awọn ololufẹ rẹ, nigba ti awọn miran sọ pe agbeyẹwo Cinema Pointer lori sinima Prophetess fi si apakan, ti ko si jẹ ojulowo.

Amọ nigba ti Toyin Abraham yoo fesi pada fun wọ, iyalaya gbogbo yin lo fi fesi pada.