Muhammadu Buhari London travel: Ìdí tí àwọn ọmọ Naijiria ṣe fẹ̀hónúhàn lòdì sí ìrìnàjò Buhari sí London

Awọn to n gbadura fun Buhari

Oríṣun àwòrán, @Adamsyyoladauda

Awọn alatilẹyin aarẹ Buhari naa ti farahan lati jẹ karaye mọ pe aarẹ Buhari kii ṣe eeyan buruku.

Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Nàìjíríà kan ṣe ìfẹ̀hónúhàn níwájú Abuja House, ibi tí Ààrẹ Buhari dé sí ní ìlú London, tí wọ́n sì sọ pé kó padà sílé, ni àwọn ọmọ Nàìjíríà míì náà wá ṣe ìwọ́de pé àwọn wà lẹ́yìn Ààrẹ náà.

Aarẹ Buhari lo tẹkọ ofurufu leti lọjọ diẹ sẹyin lati lọ fun isinmi ti yoo fi tọju ara rẹ ni London.

Amọ eyi waye ni kete ti awọn dokita lorilẹede Naijiria gun le iyanṣẹlodi nitori aisa owo oṣu wọn deede.

Bi iṣẹlẹ meji yii ṣe ṣe kongẹ ara wọn lo mu awọn ọmọ Naijria faraya ti wọn si n ṣe iwọde tako irinajo aarẹ si ilu London.

Amọ, amugbalẹgbẹ Aarẹ tẹlẹri Goodluck Jonathan, iyẹn Reno Omokri n gbe ọ̀rọ̀ sita pe Ọmọwe Philip[Idaewo to dari iwọde adura fun aarẹ Buhari kii ṣe ajoji ati pe bi oluranlọwọ aarẹ Buhari ṣe juwe rẹ gẹgẹ bi olufọkansin ọmọ Naijiria ko tọ.

O fi si oju opo Twitter rẹ pe Philip Idaewor yii naa ni alaga ẹgbẹ oṣelu APC niluu London torinaa ẹyin aarẹ Buhari lo wa tẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, Reno Omokri

Wo ìdí táwọn ọmọ Naijiria ṣe takú síwájú ilé tí Ààrẹ Muhammadu Buhari dé sí ní London

Awọn ọmọ Naijiria kan to n fi ilu London ṣebugbe ti bẹrẹ ifẹhonuhan lodi si bi Aarẹ Muhamadu Buhari ṣe lọ si ilu naa fun ayẹwo.

Ifẹhonuhan ọhun ti wọn kọ lati dẹwọ rẹ ni wọn fi n fa Aarẹ Buhari leti pe ko pada si Naijiria to ba fẹ ṣe ayẹwo ara rẹ.

Ọjọru to kọja yii ni amugbalẹgbẹ Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Goodluck Jonathan, iyẹn Reno Omokri tẹkọ ofurufu leti lọ siluu London lati bẹrẹ ifẹhonuhan naa, eyii ti ko tii dẹwọ rẹ lati igba naa wa.

Ṣugbọn ki lo fa iwọde naa gan?

Iwọde ọ́hun bẹrẹ nitori iyanṣelodi awọn dokita ni Naijiria, eyii to bẹrẹ lọjọ kinni, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

Awọn dokita ni Naijiria daṣẹ silẹ lọna ati bere awọn ẹtọ kan lọwọ ijọba apapọ bii owo oṣu to jẹ wọn atawọn ajẹmọnu kan to yẹ ki wọn gba lasiko ajakalẹ arun Covid-19.

Oríṣun àwòrán, Reno Omokri

Lati le fi aidunu wọn han si Aarẹ lori bo ṣe lọ gba itọju ni London lasiko ti awọn dokita wa ni iyanṣelodi ni Naijiria, Omokri ko awọn eeyan kan sọdi lati ṣe iwọde niwaju ile ijọba Naijiria ti Aarẹ Buhari wa ni London.

Àkọlé fídíò,

Jimoh Ológì déé! Ọ̀mọ̀wé ní kílàsì fásitì, ológì nílé

Ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Twitter rẹ, Omokri ni "ti awọn dokita nilẹ Gẹẹṣi ba n gunle iyanṣelodi, sẹ Aarẹ Bahari yoo to ẹni to n lọ sibẹ fun ayẹwo?"

Oríṣun àwòrán, Twitter/ Reno Omokri

Nigba ti ikọ BBC ṣabẹwo sile ijọba Naijiria ni London, ọkan lara awọn olufẹhonuhan naa ni ko dun mọ oun ninu bi Aarẹ Buhari ati ẹbi rẹ kii ṣe gba itọju ni Naijiria.

O ni Buhari kọ lati kọ ile iwosan to yanranti si Naijiria lati igba to ti gori oye lọdun 2015, ṣugbọn o nifẹ si ati maa lọ gba itọju ni London, eyii ti ko yẹ ko ri bẹẹ.

Ẹlomiran ni iye owo ti Buhari yoo na fun itọju ara rẹ ni London to wa kii ṣe owo kekere, ati pe kii ṣe iru owo to yẹ ki ijọba Naijiria maa na lasiko yii niyẹn.

Iye igba ti Buhari ti lọ silẹ Gẹẹsi fun itọju

Buhari lọ siluu London laarin ọjọ kẹfa si ọjọ kọkandinlogun ọdun 2016 lati gba itọju.

O tun ṣayẹwo siluu London larin ọjọ keje si ọjọ kẹtala, oṣu Kẹjọ, ọdun 2017 fun ayẹwo, iyẹn lasiko ti wọn sọ pe eku gba ile ijọba apapọ, Aso Rock, to wa niluu Abuja.

Àkọlé fídíò,

Àṣírí ìdí tí ìjínigbé fi ń ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà ló tú nínú fídíò yìí

Lọdun 2018, Buhari lo ọjọ mẹwaa ni London laarin ọjọ kẹjọ si ọjọ kejidinlogun lati ri awọn dokita.

Lẹyin na lo tun bẹ ilẹ Gẹẹṣi wo larin ọjọ keji si ọjọ kẹtadinlogun, ọdun 2019, ṣugbọn a ko le sọ boya ayẹwo lo lọ fun lasiko naa.

Oríṣun àwòrán, Reno Omokri/Twitter

Ẹwẹ, ijọba Naijiria ko tii ṣo ohun kankan lori ifẹhonuhan naa lati igba to ti bẹrẹ.

Àkọlé fídíò,

Mobile Wash: iṣẹ́ fífọ́ mọ́tò tà ni mó yàn láààyò- Slay Mama