Owerri jailbreak: Àwọn agbébọn tún kọlu Àgọ́ Ọlọ́pàá míì

Ọgba ẹwọn Owerri

Agọ Ọlọpaa Mbieri to wa ni agbegbe ijọba ibilẹ Mbaitoli tun ni tuntun ti a gbọ tẹlẹ pe wọn ṣe ikọlu si.

Eyi ni yoo jẹ agọ ọlọpaa ikeje ti awọn janduku kọlu ni ipinlẹ Imo laarin oṣu kini ọdun yii si oṣu kẹrin, lara rẹ si ni ikọlu si olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni ipinlẹ Imo lọjọ Aje.

Gẹgẹ bi awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ṣe sọ ọ, awọn agbebọn ba agọ ọlọpaa naa jẹ ti wọn si tu awọn afurasi ọdaran to wa nibẹ silẹ.

Iroyin sọ pe alẹ Ọjọru ni wọn tun yabo ibẹ pẹlu awọn ohun ija nla nla lai tii to wakati mẹrinlelogun ti awọn kan ṣẹṣẹ kọlu agọ ọlọpaa ti Ehime Mbano ti wọn si jo o ni ina.

Bii ọlọpaa meji ni a gbọ pe wn ṣe leṣe ti iroyin si ni wọn ti ji eeyan kan gbe lọ.

Ọlọpaa ipinlẹ Imo lo fidi ọr naa mulẹ pe lootọ ni wọn tun kọlu agọ mii.

Ẹwẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Imo ni awọn ribi kapaa awọn to ṣe ikọlu naa o si ni awọn afurasi kan ti wa ni ahamọ ọlọpaa.

Àwọn agbébọn tún dáná sun àgọ́ ọlọ́pàá ní Imo, wọ́n tú àwọn tó wà ní àhámọ́ sílẹ̀

Awọn agbebọn kan ti dana sun olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni ijọba ibilẹ Ehime Mbano, nipinlẹ Imo.

Ikọlu yii waye lẹyin ọjọ kan ti awọn agbebọn kan kọlu ọgba ẹwọn to wa ni ilu Owerri, ati olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni ipinlẹ Imo.

Lasiko ikọlu naa ni wọn tu ẹlẹwọn 1,884 silẹ, ti wọn si tun dana sun ọkọ to le ni aadọta ni olu ileeṣẹ ọlọpaa.

Ikọlu ti ọjọ Iṣẹgun waye lẹyin wakati diẹ ti Igbakeji Aarẹ Naijiria, Yẹmi Ọṣinbajo, Ọga Agba fun ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn ṣẹṣẹ yọ nipo, Mohammed Adama, ati awọn olori ijọba mii ṣe abẹwo si ilu Owerri nitori ikọlu to waye lọjọ Aje.

Iroyin sọ pe gbogbo awọn afurasi ọdaran to wa ni ahamọ ni agọ ọlọpaa naa ni awọn agbebọn ọhun tu silẹ, ko to o di pe wọn dana sun un.

Ọkan lara awọn to n gbe ni agbegbe naa sọ fun BBC Pidgin pe titi di aago meje abọ alẹ ni iro ibọn n dun.

Ẹlẹ́wọ̀n 1,881 ló wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Owerri kìí ṣe 2,156 bí Amnesty Int'l ṣe sọ - iléeṣẹ́ ọgbá ẹ̀wọ̀n

Ileeṣẹ ọgba ẹwọn ni Naijiria ti sọ pe awọn ẹlẹwọn to wa ni ọgba ẹwọn niluu Owerri ko to ẹgbẹrun meji bi ajọ Amnesty International ṣe sọ.

Ajọ Amnesty International ti sọ tẹlẹ pe ọgba ẹwọn tawọn agbebọn kọlu ni ilu Owerri eyi to mu kawọn ẹlẹwọn salọ ko yẹ ko gba ju ẹlẹwọn 548 lọ.

Ajọ naa sọ pe ẹlẹwọn 2,156 lo wa ninu ọgba ẹwọn naa nigba tawọn agbebọn kọlu ọgba ẹwọn ọhun.

Nigba ti o n ba BBC Yoruba sọrọ, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọgba ẹwọn ni Naijiria, Francis Osagiede Enobore ṣalaye pe kii ṣe ẹlẹwọn 2,156 lo wa ninu ọgba ẹwọn naa nigba ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.

Ọgbẹni Enobore ni ẹlẹwọn 1,881 lo wa lọgba ẹwọn ki iṣẹlẹ naa to waye.

''Bo tilẹ jẹ pe awọn ẹlẹwọn to wa lọgba ẹwọn ilu Owerri ju iye awọn to yẹ ko wa nibẹ lọ, amọ ọrọ ko ri bi ajọ Amnesty Insternational ṣe sọ,'' Ọgbẹni Enobore lo sọ bẹẹ.

Ọgbẹni Enobore sọ pe ọpọ eeyan to wa lẹwọn lo yẹ ki wọn ti gba idajọ kuro lẹwọn ṣugbọn ọpọ ninu wọn ni ko lowo lati gba agbẹjọro ti yoo ṣoju wọn.

O fikun ọrọ rẹ pe kii ṣe ọgba ẹwọn ilu Owerri nikan lawọn ẹlẹwọn ti pọju lọgba ẹwọn, o ni kaakiri ilu nla nla ni Naijiria ni.

Enobore kepe awọn agbẹjọro ẹlẹyinju aanu lati ṣoju awọn ẹlẹwọn ti ko rọwọ họri lati ṣoju wọn nile ẹjọ ki awọn to wa lẹwọn le dinku.

Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe iṣẹ n lọ lọwọ lori kikọ ọgba ẹwọn to tobi ti yoo gba awọn ẹlẹwọn to pọ kaakiri Naijiria.

Àkọlé fídíò,

Àwọn èdè abẹ́ ahọ́n tóo lè fi sọ̀rọ̀ rèé láì tú àṣírí ọ̀rọ̀ rẹ áyé