Yoruba film celebrities: Ìdí tí mo fi ṣe ìgbéyàwó ìdákọ́nkọ́ - Sotayo Gaga

Sotayo Gaga

Oríṣun àwòrán, Sotayo Gaga

Gbajugbaja oṣere tiata Tayo Sobola ti fi idi rẹ mulẹ erongba rẹ to fi ṣe iyawo idakọnkọ.

Ni nkan bi oṣu melo kan sẹyin ni gbogbo awọn ololufẹ oṣere naa n kọ haa lẹyin ti wọn ri foto oṣere yii lori ayelujara instagram rẹ. Nigba ti awọn kan n ki ku orire ni awọn miiran n sọ pe awo sinima to fẹ gbe jade ni.

Oríṣun àwòrán, Sotayo Gaga

Sugbọn ninu ifọrọwerọ pẹlu iwe iroyin kan ni Sotayo ti fi idi ọrọ naa mulẹ pe lootọ ni oun ṣe igbeyawo ati pe o ti to ọdun meje sẹyin ni oun ti mọ ọ.

O ní, "mo ti ṣe igbeyawo, ọkọ mi kii si ṣe oni tiata. O ti ṣe diẹ ti mo ti ṣe iyawo. Mo ti mọ ọkọ mi fun ọdun meje ki a to ṣe igbeyawo. Ti ẹ ba mọ mi, ẹ mọ pe mi kii gbe ọrọ ara mi sita.

Mo ti wa pẹlu ọkọ mi lati ọdun meje sẹyin. Irubọ ni ọrọ igbeyawo.

"Mo n ka nkan miiran lori awọn iwe iroyin ayelujara mo si rẹrin: gbogbo ibi ti wọn ba fẹ ni wọn le tan an ka de, mi o nifẹ lati maa gbe nkan to ba kan mi si aaye ara mi, nitori rẹ ni mo se fi igbeyawo mi ṣe idakọnkọ.

Kii ṣe ọdun yii ni mo ṣe igbeyawo, mo kan ṣẹṣẹ fi fọto igbeyawo mi sita ni oṣu diẹ sẹyin ni."

Oríṣun àwòrán, Sotayo Gaga

Àwọn òbìnrin tó ń ya fọ́tò ìhòhò ara wọn níwájú ilé kó sí gbaga ọlọ́pàá!Gbajugbaja oṣere naa, to tun jẹ oniṣowo aṣọ fidirẹ mulẹ pe lootọ ni oun ko kopa ninu awọn Sinima pupọ lati bi ọjọ mẹta sẹyin nitori pe oun n di asiko yii moju to ọrọ aṣọ ti mo n ta ni, eyi ti mo ṣẹṣẹ ṣi ẹka kan si Abuja.

O ni "asiko wa dun gbogbo nkan, mo si ni igbagbọ pe gbogbo nkan ri eniyan ba fẹ ṣe eniyan gbọdọ wa asiko fun.

Fun emi, ọpọ lo n fi atẹjiṣẹ ranṣẹ pe awọn o ri mi ninu sinima mọ, nigba miiran eeyan a ma fi iṣẹ silẹ lati wa owo. Igba miiran wa ti mo ma n fẹ lati ṣe sinima, gbigbo ẹni to ba si pe mi fun ere lasiko naa, mo n da wọn lohun, mo si le ṣe sinima meji si mẹta.

"Igba miran si wa ti mi o le ṣe sinima, ki n sọ ootọ iṣẹ aṣọ ti mo n ṣe o maa n gba asiko gidi afi ti ko ba si adojusun. Mo ṣi sọọbu tuntun kan ni Abuja, ibẹ naa si ni ile mi wa nitori ibẹ ni awọn alabara mi pọ si. Ni bayii iṣẹ aṣọ ni mo gbajumọ bi mo ṣe n ta ni mo n ra "Mo ti ni oju ti awọn eniyan n fẹ ninu sinima, ti mo ba di silẹ diẹ lati lọ ṣowo, igbkuugba ti mo ba pada de ko ai eni ti yoo mọ pe mo fi igba kan kuro.

Ti mo ba ri ọwọ nilẹ ni mo n ṣe sinima bayii.