Bola Tinubu: Èèkàn Afenifere àtàwọn ọba l'Ondo kéde àtìlẹ́yìn wọn fún Tinubu fún ìbò ààrẹ 2023

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Twitter/Babajide Sanwo-Olu

Olori ẹgbẹ ọmọ Yoruba, Afenifere tẹlẹ, Pa Reuben Fasoranti ti kede atilẹyin rẹ fun Aṣiwaju Bola Tinubu lati di aarẹ orilẹede Naijiria lọdun 2023.

Pa Fasoranti sọrọ yii nigba tawọn ẹgbẹ to n ṣe ipolongo fun Tinubu lapa iwọ oorun gusu ni Naijiria, South West Agenda for Asiwaju Bola Ahmed Tinubu (SWAGA 23) ṣe abẹwo si i nile rẹ niluu Akure.

Baba Fasoranti ni ''Tinubu koju osunwọn lati tukọ orilẹede Naijiria pẹlu oriṣiiriṣii nkan to ti gbe ṣe lati ẹyin wa.''

''Tinubu to gbangbaa sun lọyẹ lati jẹ aarẹ Naijiria lọdun 2023.

Mo fọwọ sii, mo si gbadura pe ki Eleduwa gbọ adura rẹ nitori to ba de ipo naa tan, gbogbo ohun ti a n fẹ ni yoo ṣe,'' Pa Fasoranti lo ṣalaye bẹẹ.

Baba Fasoranti sọ pe ti Tinubu ba fi le di aarẹ Naijiria, gbogbo erongba ẹgbẹ Afenifere lori ọrọ atunto Naijiria ni yoo di mimuṣẹ.

''Lai si ani-ani kankan nibẹ, Tinubu lo le ṣee lọdun 2023, mo mọ Tinubu daadaa.

Tinubu ko ni ja awọn ọmọ Naijiria kulẹ ti o ba de ipo aarẹ lọdun 2023, Fasoranti ṣalaye.

Alakoṣo ẹgbẹ SWAGA 23, Dayo Adeyeye kepe awọn ọmọ ilẹ Yoruba lati fohun ṣọkan, ki wọn si gbaruku ti Tinubu fun ibo aarẹ lọdun 2023.

O ni ọna kan gboogi ti ọmọ Yoruba le fi jẹ aarẹ Naijiria lọdun 2023 ni pe ki onikalulu lapa iwọ oorun gusu Naijiria gbaruku ti Tinubu.

Ẹwẹ, Osemawe Ondo, Oba Victor Kiladejo ati Abodi Ikale, Oba George Faduyile naa ni Tinubu lo le ṣee ti yoo fi yanju lọdun 2023.

Wọn ni ilẹ Yoruba le gbaruku ti lati dupo aarẹ ninu eto idibo gbogbogbo ọdun 2023.