Kaduna killings: Àwọn jàndùkú pa èèyàn mẹ́jọ, wọ́n tún jí ọ̀pọ̀ gbé lọ ní Kaduna

Nasir El Rufai

Oríṣun àwòrán, Twitter/Kaduna Government

O kere tan, eeyan mẹjọ lawọn agbebọn ṣekupa lọjọ Iṣẹgun nigba tawọn eeyan mii si farapa yanyana ninu ikọlu tuntun to waye nipinlẹ Kaduna.

Kọmiṣọnna fun ọrọ abo abẹle nipinlẹ Kaduna, Samuel Aruwan ṣalaye pe awọn agbebọn ọhun di oju ọna lẹba abule Kadanye lagbegbe Kajuru.

Ọgbẹni Aruwan sọ pe nibẹ ni wọn ti dabọn bo ọkọ bọọsi akero kan ati ọkọ akẹru to ko igi idanam wọn si yinbọn pa eeyan marun un lẹsẹ kẹsẹ.

Awọn kan tiẹ sọ pe wọn tun ji ọpọ eeyan gbe ninu iṣẹlẹ naa.

Bakan naa ni

Kọmiṣọnna fun ọrọ abo abẹle nipinlẹ Kaduna ṣalaye pe ni abule Akilbu ati Inlowo lagbegbe Kachia lawọn agbebọn ti yinbọn pa awọn eeyan mii.

Bakan naa lo sọ pe ọgọsan maalu ni wọn tun jigbe lọ ni gaa awọn darandaran to wa lagbegbe naa.

Ọgbẹni Aruwan tun fidi rẹ mulẹ pe awọn ọlọpaa dena ikọlu mii ti ko ba tun waye loju ọna Kaduna si Birni Gwari lagbegbe Buruku.

Awọn ọlọpaa yabo ibi tawọn agbebọn ọhun ti fẹ ṣọṣẹ nibi ti wọn ti doju ija kọ ara wọn ti awọn janduku naa si fẹsẹ fẹ.

Eeyan meji, Fahad Lawal ati Usman Shehu ni wọn doola nibẹ, awọn mejeeji si n gba itọju nile iwosan bayii.

Àkọlé fídíò,

'Bí ojú ọ̀nà agbàrá òjò tí ijọba ṣe n'IIorin ṣe ń pa àwọn ọmọ iléèwé wa rèé! Ẹ sàánú wa'