Dangote, Adenuga àti Rabiu pọ̀ síi pẹ̀lú $5.7bn - Forbes

Aliko Dangote, Femi Otedola ati Mike Adenuga

Oríṣun àwòrán, Instagram/femiotedola

Ọrọ̀ awọn bilonia to jẹ ọmọ orilẹede Naijiria tun ti pọ sii pẹlu biliọnu mẹfa owo dọla din diẹ laarin ọdun kan sẹyin.

Iwe iroyin Forbes lo gbe iroyin naa jade pe ninu atẹjade awọn bilonia fun ọdun 2021.

Atẹjade ti Forbes gbe jade lọjọ Iṣẹgun fihan pe Aliko Dangote to jẹ oludari ati ọga agba ileeṣẹ Dangote naa si lo lowo julọ nilẹ Afirika.

Mẹrinla lara awọn bilonia agbaye ọhun lo wa lati ilẹ Afirika.

Ni bayii, dukia ati ọrọ Dangote ti di $11.5bn lati $8.3bn to wa lọdun 2020.

Dangote bilonia to wa ni ipo kọkanlelọgọsan lori tabili awọn eeyan to lọrọ julọ ni gbogbo agbaye.

Ọrọ ati dukia alaga ileeṣẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ Globacom ati ile epo rọbi Conoil Plc, Mike Adenuga naa le si lati $5.6bn lọdun 2020 si $6.1bn bayii.

Adenuga lẹni to lowo julọ ṣikeji lorilẹede Naijiria, amọ ipo karun un lo wa nilẹ Afirika nigba to wa ni ipo oji le ni irinwo 440 lagbaaye.

Oludasilẹ ileeṣẹ BUA Group, Abdulsamad Rabiu naa gberu sii pẹlu ọrọ rẹ.

Ohun ini rẹ ti di $4.9bn bayii lati $2.9bn to wa lọdun 2020.

Marun un ninu awọn bilonia lati ilẹ Afirika ti iwe iroyin Forbes gbe jade lo wa lati orilẹede South Africa.

Marun un miran wa lati orilẹede Egypt, nigba ti ẹyọkan jẹ ọmọ bibi orilẹede Algeria.

Ẹwẹ, oludasilẹ ileeṣẹ Amazon, Jeff Bezos si ni ẹni to lowo julọ lagbaaye pẹlu $177bn.

Ọgbẹni Bezos ti wa ni ipo kinni bayii fun ọdun mẹrin gbako.

Àkọlé fídíò,

'Bí ojú ọ̀nà agbàrá òjò tí ijọba ṣe n'IIorin ṣe ń pa àwọn ọmọ iléèwé wa rèé! Ẹ sàánú wa'