Traditional Rulers Attack: Ọba David Oyewumi ti gba òmìnira lọ́wọ́ àwọn ajínigbé ní Ekiti

David Oyewumi

Oríṣun àwòrán, @insightlinkstv

Idunu ṣubu lu ayọ nipinlẹ Ekiti lẹyin ti ọba Ilemeso-Ekiti, Ọba David Oyewumi gba ominira lọwọ awọn ajinigbe.

Ọsẹ to kọja ni awọn ajinigbe naa kan lu aafin rẹ ni nnkan bii aago mẹjọ abọ aṣalẹ, ti wọn si ji i gbe lọ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, sọ fun BBC Yoruba pe ori ade naa ti bọ lọwọ awọn ajinigbe ọhun, o si ti pada sile lọdọ awọn ẹbi rẹ.

Agbenusọ ọlọpaa naa ni: "Mo fẹ sọ fun un yin pe awọn ajinigbe naa ti tu Kabiesi silẹ, o si ti pada silẹ lọdọ awọn mọlẹbi rẹ."

"Wọn tu u silẹ lẹyin ti awọn akọṣẹmọṣẹ ọlọpaa kan lu inu igbo ti wọn gbe e lọ lati doola rẹ lọwọ awọn ajinigbe ọhun."

Ṣaaju ni iroyin kan ti kọkọ gbode pe awọn ajinigbe ọhun beere ogun miliọnu naira gẹgẹ bii owo itusilẹ lọwọ awọn ẹbi rẹ.

Àkọlé fídíò,

Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba: Ẹ̀yà Ara Ifọ̀ ní olùkọ́ Adedokun kọ́ wa

Ṣugbọn Abutu sọ fun BBC pe ko si ohun to jọ bẹẹ, ati pe ileeṣẹ ọlọpaa ko le fidi rẹ mulẹ boya awọn ẹbi ọba alaye naa san owo itusilẹ kankan.

Wọn ji ori ade naa gbe ninu aafin rẹ l'Ọjọbọ lẹyin ti awọn ajinigbe ọhun kọlu aafin rẹ, ti wọn si fo ogiri wọle.

Iṣẹlẹ naa waye ni nnkan bii ọsẹ kan si asiko ti ọba Elewu ti Ewu-Ekiti, Ọba Adetutu Ajayi, ti kọkọ jajabọ lọwọ awọn kan ti wọn gbiyanju lati ji oun naa gbe.

Ọpọ awọn ọmọ Yoruba kaakiri orilẹ-ede naijiria lo bu ẹnu ẹtẹ lu iṣẹlẹ naa pe o jẹ ohun itiju pe awọn ajinigbe gboju-gboya lati wọ inu aafin lọ lati ji odidi ọba gbe.

Àkọlé fídíò,

aaaaaaaaaaaaaaa

Èèmọ̀ wọ̀lú, Ajínigbé fo ògiri wọnú ààfin, wọ́n jí oríadé gbé l'Ekiti

Yoruba ni iku to n pa ojugba ẹni, owe lo n pa fun ni, bi atẹgun ba si ti n gbe kẹtẹpẹ ogi, ayafi ki onilafun ma se afira.

Ọba David Oyewumi, to jẹ Obadu ti Ilemeso-Ekiti, ni awọn ajijigbe ji gbe ninu aafin rẹ to wa ni ijọba ibilẹ Oye, nipinle Ekiti.

Oríṣun àwòrán, @DailyPostNGR

Awọn ajinigbe naa fo iganna wọ inu aafin kabiesi, wọn si bẹrẹ si n yinbọ soke ki wọn to ji gbe lọ.

Iṣẹlẹ yii lo n waye ni nnkan bii ọsẹ kan si asiko ti ọba Elewu ti Ewu-Ekiti, Ọba Adetutu Ajayi, bọ lọwọ awọn kan ti wọn gbiyanju lati ji oun naa gbe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oṣojumikoro kan sọ pe awọn ajinigbe naa lu ori ade ọhun atawọn ẹbi rẹ ninu aafin, ki wọn to gbe salọ.

O ni "inu aafin baba ni wọn ti gbe wọn lọ, awọn eeyan bii mẹrin fo ogiri wọle, ti wọn si n beere pe, baba da, baba da… eyi to n ṣafihan pe baba gan ni wọn wa wa.

Àkọlé fídíò,

Sunday Igboho: Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọ̀n bàbá wa

Ni kete ti wọn ri baba bayii ni wọn gbe wọn salọ."

Ọpọ awọn olugbe ilu naa to jẹ agbẹ, lo ti bẹrẹ si n sa kuro nibẹ nitori ibẹru awọn ajinigbe.

Eti mi ko gbọ ri pe awọn ajinigbe wọ inu aafin lati gbe ọba lọ - Alawe ti Ilawe Ekiti

Nigba to n fi idi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba, Alaga igbimọ lọbalọba nipinlẹ Ekiti, Ọba Adebanji Ajibade Alabi, tii ṣe Alawe ti ilu Ilawe-Ekiti ni iṣẹlẹ naa jẹ eyii to buru jai o si ba awọn lọkan jẹ gidi.

O ni "awa gẹgẹ bii ọba, ati gbe igbesẹ lori iṣẹlẹ naa, nitori ni kete ti a gbọ ni mo ke si ileeṣẹ ọlọpaa, awọn fijilante atawọn ikọ Amọtẹkun lati wọ inu igbo ti wọn gbe ọba naa lọ, lati wa a ri."

Ọba Ajibade Alabi sọ pe, o jẹ ohun ti eti ko gbọ ri ki awọn ajinigbe maa farapamọ sinu igbo ki wọn si gboju gboya lati wọ inu aafin lati ji odidi ori gbe.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, "awọn Amọtekun n gbiyanju nitori awọn lo maa n wọnu igbo lọ lati lọ ṣọfintoto awọn ajinigbe, nitori naa, o yẹ ki ijọba ti wọn lẹyin, ki ijọba si pese irinṣẹ igbalode fun wọn lati ṣiṣẹ wọn."

Àkọlé fídíò,

Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

O rọ ileeṣẹ ọlọpaa lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn ẹṣọ alabo miran bii ileeṣẹ ologun, awọn fijilante ati ọlọdẹ ilu lai yọ Amọtekun silẹ, lati wọ inu ogbo lọ lati le gbogbo awọn ajinigbeto wa nibẹ jade.

Ọba Alabi ni itiju nla ni fun ilu pe awọn ajinigbe wọ inu aafin, ti wọn si ji ọba wọn gbe lọ lai si idiwọ kankan.

Bo tilẹ jẹ pe o mẹnuba ikọlu ti awọn eeyan kan ṣe si ọba Ewu lọna ilu Ayetoro, alaga igbimọ awọn lọbalọba Ekiti naa ni iṣẹlẹ yii ni igba akọkọ ti wọn yoo ji ọba gbe ni ipinlẹ Ekiti.

Ni ti awọn igbesẹ ti awọn lọbalọba n gbe nipinlẹ Ekiti lati dabo bo ara wọn atawọn eeyan ilu, Ọba Ajibade Alabi ni ipade ti n lọ lọwọ laarin awọn lọbalọba naa, ti oun ko fẹ mẹnuba.

Àkọlé fídíò,

Female Car Painter: Èmi ní obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò máa ṣiṣẹ́ akunmọ́tò ní Ibadan

A ti ran awọn ọtẹlẹmuyẹ lati se awari Kabiyesi - Ileesẹ ọlọpaa

Nigba ti BBC Yoruba kan si alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, ASP Sunday Abutu, o ni lootọ ni iṣẹlẹ naa waye, awọn si ti ran awọn akọṣẹmọṣẹ ọtẹlẹmuyẹ sinu igbo naa lati ṣawari kabiesi ọhun.

Abutu ni iṣẹ ti n lọ lọwọ lati ṣawari oriade naa, awọn yoo si doola kabiesi ọhun laipẹ.

O pari ọrọ rẹ pe, titi di akoko ti oun fi n ba BBC sọrọ, awọn ajijigbe naa ko tii beere owo itusilẹ kankan lọwọ awọn mọlẹbi ori ade ti wọn ji gbe ọhun.

Oríadé míì nílẹ̀ Yorùbá tún kàgbákò ìkọlù agbébọn

Oríṣun àwòrán, NigerianArmyHQ

Awọn ikọlu to n waye nilẹ Naijiria lemọ lemọ yii ti di Egbirin ọtẹ, baa se npa ọkan ni omii n ru.

Idi ni pe oriade kan nipinlẹ Ekiti, ẹni tii se ọkan lara awọn oriade pataki nipinlẹ naa, to tun jẹ Elewu tilu Ewu Ekiti, Ọba Adetutu Ajayi ni awọn gende agbebọn kan tun ti kọlu.

Awọn gende agbebọn naa kọlu oriade yii lasiko to n ti ilu Ayetoro Ekiti to mule ti ilu rẹ bọ, se ni wọn si rọjo ọta ibọn si ara ọkọ ayọkẹlẹ rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọba naa, to fi ara gba ọgbẹ ọta ibọn lori ko yọ lọwọ iku ojiji, to si ti n gba itọju nile iwosan aladani kan nilu Ado Ekiti.

Àkọlé fídíò,

Torí àti ṣe Kòkò irin, bí mo ṣe máa ǹ fara yá iná nìyìí - Amokoko Saki

A gbọ pe ẹsẹ, ọwọ ati ikun ni oriade naa ti fara gba ọgbẹ ọta ibọn, to si wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun bayii.

Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu ti wa fidi isẹlẹ naa mulẹ, to si n fi ika hanu pe isẹlẹ naa waye lai naani pe awọn ọlọpaa n paraaro ipinlẹ naa lati de ikọlu awọn ọdaran.

Àwọn ajínigbé bèèrè fún óúnjẹ àti suya kí wọ́n tó tú ọkọ, ìyàwó àtàwọn ọmọ sílẹ̀ l'Ondo

Oríṣun àwòrán, @DailyPostNGR

Ara mee riri, mo rori ologbo latẹ. Awọn ẹbi Ọgbẹni Olisa Ibrahim iyawo atawọn ọmọ wọn mẹta ti sọ ohun ti oju wọn lakata awọn agbebọn to ji wọn gbe nipinlẹ Ondo.

Ẹbi naa ti wọn jigbe lopopona Ajowa si Ayere kabba ṣalaye pe lara awọn nnkan tawọn ajinigbe ọhun beere fun ni ounjẹ to dun, ọti waini ati ẹran suya yatọ si owo.

Ẹbi Ọgbẹni Ibrahim to n pada lọ si ibugbe wọn niluu Abuja lẹyin ọdun Ajinde lawọn ajinigbe ọhun kọkọ beere fun miliọnu mẹwaa owo itusilẹ lẹyin ti wọn gbe wọn lọ tan.

Gbogbo wọn lo pada si ilu Ajowa-Akoko lẹyin ti wọn gba ominira tan lọwọ awọn agbebọn ajinigbe.

Ohun ti a gbọ ni pe wọn san owo kan ki wọn to fi wọn silẹ, ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ko le fidi rẹ mulẹ.

Niṣe lawọn eeyan n tu yaya lọ si ile wọn nibi ti wọn ti n ki wọn ku oriire pe aja to rele ẹkun to bọ, ki ki i ku ewu.

Ipinlẹ Ondo yii naa wọn ti ji pasaitọ Fredrick Aramuwa gbe ti wọn si ṣekupa lẹyin ti a gbọ pe awọn ẹbi san owo gọbọi fawọn kọlọnbiti ẹda ọhun.

Ariwo sọọ! Àwọn agbébọn jí ọkọ, ìyàwó àtàwọn ọmọ wọn gbé l'Ondo

Awọn agbebọn kan ti ji idile ẹlẹni marun un gbe niluu Ajowa-Akoko, ni ijọba ibilẹ Ariwa-Iwọ-oorun Akoko ni ipinlẹ Ondo.

Iroyin ni awọn eeyan naa n rinrinajo lọ si Abuja lati Ajowa-Akoko, nibi ti wọn ti lọ ṣe ọdun Ajinde ki awọn ajinigbe ọhun to ka wọn mọ abala kan ti ko dara loju ọna naa.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, wọn ji olori ẹbi naa, Ibrahim Olusa plẹlu iyawo atawọn ọmọ rẹ gbe loju ibọn laarin Ajowa-Akoko si Ayere ni ipinlẹ Kogi, wọn si ko gbogbo wọn lọ sinu igbo kijikiji.

Wọn ni awọn ajinigbe naa ti kan si ẹbi awọn ti wọn ti je gbe lati bere miliọnu mẹwaa naira owo itusilẹ wọn.

Isẹlẹ naa si ti mu iporuru ba ọkan awọn eeyan ilu ọhun.

Àkọlé fídíò,

'Bí ojú ọ̀nà agbàrá òjò tí ijọba ṣe n'IIorin ṣe ń pa àwọn ọmọ iléèwé wa rèé! Ẹ sàánú wa'

Ọkan lara awọn adari ilu naa, to tun jẹ alaga igbijmọ adari Ajowa-Akoko ana, Ajayi bakare to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe ijinigbe ati idigunjale n peleke sii lagbegbe nitori ọna ti ko dara ni iha ipinle Kogi.

Bakare wa ke si ijọba lati tun ọna naa ṣe ni kiakia lati le ṣadinku iwa ọdaran lagbegbe ọhun.

Àkọlé fídíò,

Àwọn èdè abẹ́ ahọ́n tóo lè fi sọ̀rọ̀ rèé láì tú àṣírí ọ̀rọ̀ rẹ áyé