Buhari driver: Kò sẹ́ni tó lè ní kí Buhari má gba ìtọ́jú nílẹ̀ òkèèrè - Amúgbálẹ́egbẹ́ Ààrẹ

Buhari

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina

Amugbalẹgbẹ Aarẹ Muhammadu Buhari lori oju opo ikansiraẹni lori ayelujara, Lauretta Onochie ti sọ pe Aarẹ lẹtọọ lati maa lọ gba itọju loke okun.

Onochie lo sọrọ naa ninu atẹjade kan loju opo Twitter rẹ lasiko to n fesi si bi awọn ọmọ Naijiria kan ṣe n bu ẹnu ẹtẹ lu Aare Buahri pe o lọ gba itọju loke okun lasiko ti awọn dokita daṣẹsilẹ ni Naijiria.

Ṣaaju ni ọpọ ọmọ Naijiria ti kọkọ bu ẹnu atẹ lu Buhari pe idi ti ko ṣe le gba itọju ni Naijiria ni pe o kọ lati tun ẹka eto ilera ṣe, koda awọn kan ṣe ifẹhonuhan niluu London pẹlu.

Lẹyin to de sile ijọba niluu London lawọn eeyan kan ti bẹrẹ ifẹhonuhan, ti wọn si n sọ pe ko pada si Naijiria lati tunṣẹ.

Nigba to n da si ọrọ naa, Onochie sọ pe ko sẹni to le ni ki Buhari ma kan si awọn dokita to n ti n ṣetọju rẹ lati nnkan bii ogoji ọdun sẹyin.

O ni "Aarẹ Buhari yoo tun lọ ṣe ayẹwo miran loke okun to ba di ọdun to n bọ, awọn eeyan yoo si tun pariwo ẹnu lasan naa ni."

Àkọlé fídíò,

'Bí ojú ọ̀nà agbàrá òjò tí ijọba ṣe n'IIorin ṣe ń pa àwọn ọmọ iléèwé wa rèé! Ẹ sàánú wa'

"O lọ fun ayẹwo lọdun 2017, 2018, 2019 ati 2020 ki Corona to de, ariwo ẹnu yii kan naa lawọn pa nigba naa."

Oríṣun àwòrán, Lauretta Onochie

Amugbalẹgbẹ Aarẹ naa fi kun pe ko si ọkunri ti yoo gba ki gẹrigẹ miran gẹ irun fun oun nitori gẹrigẹri rẹ ko si ni tosi.

Lauretta fi kun pe "to ba wu Aarẹ lati lọ fun ayẹwo miran lọdun 2022 ati 2023, yoo lọ nitori ọwọ rẹ lo wa."

Onochie pari ọrọ rẹ pe kaakiri agbaye lawọn eeyan ti maa n tẹkọ leti lati lọ ṣayẹwo lọdọ awọn dokita wọn, nitori naa, ariwo lasan lawọn eeyan n pa, ati pe ariwo naa ko le di Aarẹ lọwọ lati ri olutọju rẹ.

Àkọlé fídíò,

Àwọn èdè abẹ́ ahọ́n tóo lè fi sọ̀rọ̀ rèé láì tú àṣírí ọ̀rọ̀ rẹ áyé