National Sports Festival: Ìjọba àpapọ̀ ní kò sí ohun tó jọ pé ìdíje náà yóò párí l'Ọ́jọ́bọ̀

Awọn akẹṣẹ

Oríṣun àwòrán, Twitter/National Sports Festival

Ijọba apapọ ti sọ pe idije oriṣiiriṣii ere idaraya, National Sports Festival to n lọ lọwọ nipinlẹ Edo ko ni wa sopin lojiji lonii Ọjọbọ mọ.

Ọrọ yii jade lẹyin ti igbimọ abẹnu lori idije naa, LOC ti kọkọ kede pe idije naa yoo pari lọsan Ọjọbọ nitori aisowo.

Ṣugbọn igbakeji oludari ọrọ iroyin ni ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ere idaraya ati idagbasoke awọn ọdọ, Ramon Balogun lo fidi ọrọ naa mulẹ ninu atẹjade to fi sita l'Ọjọbọ.

O ṣalaye ninu atẹjade ọhun pe ẹka ijọba to n ṣakoso ere idaraya ati ajọ MOC to n ṣiṣẹ lori agbekalẹ idije naa ko gbọ ohun kan nipa ọrọ ti igbimọ LOC ipinlẹ Edo sọ pe idije naa ko ni le tẹsiwaju mọ.

Atẹjade naa ṣalaye pe ko si ipade kankan tabi apero kan lori ati da idije naa duro.

Ọgbẹni Balogun sọ pe Minisita ere idaraya, Sunday Dare, akọwe agba ileeṣẹ to n ri si ọrọ ere idaraya atawọn lọgalọga lo wa ni Benin fun idije National Sports Festival.

O ṣalaye pe ojuṣe ipinlẹ Edo tabi igbimọ LOC ni lati fi to wọn leti ti ipenija kan tabi omiran ba wa lori idije to n lọ lọwọ.

Igbakeji oludari ọrọ iroyin ni ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ere idaraya ati idagbasoke awọn ọdọ tun sọ pe ipinlẹ Edo tiẹ beere iranwọ owo lori ati gbalejo idije ọhun lẹyin ti ijọba sun un siwaju nitori ajakalẹ arun covid-19.

Ọgbẹni Balogun ni ileeṣẹ ijọba to n ri si ere idaraya ti gbe ọrọ naa de iwaju ijọba apapọ, o si yẹ ki owo iranwọ naa jade laipẹ.

Ẹwẹ, alakoso ọrọ iroyin lori idije National Sports Festival to n lọ lọwọ nipinlẹ Edo, Ebomhiana Musa lo sọ lalẹ Ọjọru pe igbesẹ lati da idije naa duro waye nibi ipade ti igbimọ LOC ṣe eleyii ti igbakeji gomina ipinlẹ Edo, Philip Shaibu wa nibẹ.

O sọ pe igbimọ LOC gbe igbesẹ yii nitori ijọba apapọ ko tii mu ileri iranwọ owo to ṣe fun ipinlẹ Edo ṣẹ lẹyin ti wọn ti kọkọ sun idije naa siwaju tẹlẹ.

O kere tan ẹgbẹrun mẹjọ awọn elere idaraya lo n kopa ninu idije National Sports Festival to n lọ lọwọ nipinlẹ Edo.