Adekunle Ajasin lecturer: Ó jọ bí ẹni pé ṣe ni alàgbà Olatunde Adegbuyi fọwọ́ rọrí kú - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ondo

Ọlatunde Adegbuyi

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori iku to pa olukọ fasiti Adekunle Ajasin tẹlẹ, Ọjọgbọn Olatunde Adegbuyi, ti wọn ba oku rẹ ninu ọkọ rẹ.

Alukoro ileeṣẹ naa nipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro lo fidi ọrọ naa mule fun BBC Yoruba.

Ikoro sọ pe lootọ ni awọn ọlọpaa le fidi rẹ mulẹ pe ọkunrin naa ku sinu ọkọ rẹ niluu Akungba-Akoko.

O ni "nigba ti awọn ọlọpaa de ibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, wọn rii pe o ti ku sinu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ."

"Lẹyin ti wọn rii ni wọn si gbe oku naa lọ sile iwosan, ko si ami kankan lara rẹ pe boya ṣe ni wọn pa oloogbe ọhun."

Gẹgẹ bi alukoro ileeṣẹ naa ṣe sọ, awọn ko tii le sọ ohun to ṣokunfa iku ọkunrin naa titi di igba ti awọn dokita yoo fi esi iwadii ti wọn n ṣe lede ṣugbọn o jọ bi ẹni pe ejo ko lọwọ ninu iku rẹ.

Ọpọ ẹbi, ọrẹ, atawọn akẹkọọ oloogbe naa nigba kan ri lo ti bẹrẹ si n kẹdun iku rẹ.

Lara awọn eeyan naa ni Alade Olugbenga to sọ pe oun maa n gbadun kilaasi oloogbe naa ni ẹka imọ Geology lasiko ti oun jẹ akẹkọọ labẹ rẹ.

O ni ko si igba ti oun kii gbadun kilaasi rẹ lati igba ti oun ti wa ni ipele kinni titi de ipele kẹrin ni fasiti ọhun.

Kí ló lè ṣekúpa olùkọ́ fásitì Adekunle Ajasin tẹ́lẹ̀ tó dákẹ́ sínú mọ́tò rẹ̀ yìí?

Oríṣun àwòrán, @globalextra

Wọn ti ri oku olukọ fasiti Adekunle Ajasin, AAUA, tẹlẹri kan, Olatunde Adegbuyi ninu ọkọ rẹ niluu Akungba-Akoko.

Awọn to ri oloogbe naa, to ti fi igba kan jẹ olukọ ni ẹka imọ Earth Science ko to di oloogbe sọ pe alaafia lo wa ki iṣẹlẹ na to waye.

Iroyin ni wọn ri oku oloogbe ọhun ninu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ lagbegbe Permanent Site niluu Akungba.

Ẹnikan ti ọrọ naa ṣoju rẹ sọ fun awọn akọroyin pe "eeyan kan to n kọja lọ lo ri okunrin naa ninu ọkọ rẹ to dori kodo lai mi ara."

"Ẹni naa lo ke gbajare si awọn eeyan adugbo ki wọn ti ri pe o ti dakẹ."

Àkọlé fídíò,

'Òde ìnáwó làwọn èèyàn ma ń rò bí wọ́n bá rí Ankara, ìgbà tí wọ́n rí i lára àga tí mo ṣe, ẹnu wọn ò padé mọ́'

Ko ṣeni to tii le sọ ohun to ṣokunfa iku oloogbe naa titi di akoko ti a fi n ko iryin yii jọ.

Alukoro fasiti Adekunle Ajasin, Victor Askinpelumi lo fidi iroyin naa mulẹ fun BBC Yoruba.

Ọpọ awọn ololufẹ oloogbe ọhun atawọn to ti fi igba kan jẹ akẹkọọ rẹ lo ti bẹrẹ si n ṣedaro rẹ lori ayelujara.

Àkọlé fídíò,

'Bí ojú ọ̀nà agbàrá òjò tí ijọba ṣe n'IIorin ṣe ń pa àwọn ọmọ iléèwé wa rèé! Ẹ sàánú wa'