Prince Philip, Duke of Edinburgh ti dágbére fáyé lẹ́ni ọdún 99

Arẹmọ Phillip

Arẹmọ Phillip to jẹ ọkọ Ọbabinrin Elizabeth to ti wa lori aisan ti dagbere faye lẹni ọdun mọkandilọgọrun, gẹgẹ bi aafin Buckingham ṣe kede.

Aafin Buckingham sọ pe: "Pẹlu ọkan ibanujẹ ni Ọbabinrin fi kede iku ọkọ rẹ, Ọlọlajulọ Phillip to jẹ Duke ti Edinburgh.

"Ọlọlajulọ dagbere faye ni wọọrọwọ ni Windsor Castle."

Duke ti Edinburgh, to jẹ ọkọ Ọbabinrin to pẹ laye julọ ninu itan ilẹ Gẹẹsi pada si Windsor lọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹta lati ile iwosan to ti n gba itọju.

Nigba to n sọrọ ni ibugbe rẹ ni Downing Street, olootu ijọba Boris Johnson sọ pe Duke ''jẹ iwuri ninu igbesi aye ọpọ awọn ọdọ''.

"O gbiyanju lati ṣatọna idile ọlọla ilẹ Gẹẹsi lati le ri wi pe ọ jẹ ogunagbongbo to mu igbeaye alaafia ba awọn eeyan ilẹ naa''

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Wọn gbe aworan ikede iku Duke siwaju Buckingham Palace

Ẹwẹ, Justin Welby, to jẹ the Archbishop ilu Canterbury, sọ pe Duke "ko yẹ , bẹẹ ni ko gbo lati gbe bukata awọn ẹlomiran ni pataki dipo tiẹ to si mu ki eyi jẹ awokọṣe igbe aye Kristẹni nipa isin ara ilu''

Wọn fa aṣia iwaju Buckingham Palace wa si aarin ti wọn si gbe aamin ikede siwaju ẹnu ọna aafin naa lẹyin ikede iku Arẹmọ.

Niṣe lawọn eeyan gbe ododo orisirisi wa siwaju aafin ni idaro iku rẹ ti ọgọrọ eeyan naa si kan si aafin Windsor lati ṣe ikẹdun ẹni to lọ.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Awọn eeyan gbe ododo ikẹdun siwaju Buckingham Palace

Akọroyin BBC, Nicholas Witchel sọ pe o jẹ ''asiko ibanujẹ ọkan forileeede naa'' paapa julọ fun Ọmọbabinrin to padanu ọkọ rẹ ti wọn jijọ ti wa papọ lati nkan bi mẹtalelaadọrin-pupọ wa ni ko tilẹ wa laye pẹ to asiko yi''

O ni Arẹmọ Philip ti "ko ipa ribiribi ninu aṣeyọri ọmọbabinrin lori itẹ'' to si ṣe apejuwe Arẹmọ gẹgẹ bi ''ẹni ti ko mikan ninu igbagbọ pataki iṣẹ ti ọmọbabinrin n ṣe to si gbaruku ti digbi''

O fi kun pe "Pataki idurosinsin ibaṣepọ awọn mejeeji ati igbeyawo wọn lo jẹ ki ọmọbabinrin ṣe aṣeyọri to ṣe lori oye''

Oríṣun àwòrán, Tim Graham/PA

Àkọlé àwòrán,

O le ni ọgọta ọdun ti Duke fi wa lẹgbẹ ọmọbabinrin gẹgẹ bi ọkọ rẹ eyi to mu jẹ ọkọ ọmọbabinrin to pẹ laye julọ lọdun 2009

Arẹmọ fẹ Ọmọba Elizabeth lọdun 1947, ọdun marun ko to di Ọba oun si ni ọba to pẹ ju ninu itan ilẹ Britain.

Ninu oṣu kẹta, Duke ti Edinburgh kuro ni ileewosan lẹyin odidi oṣu kan fun iwosan.

O n gba itọju latari idamu ọkan to ti n ba finra tẹ́lẹ̀ nileewosan mii ni Londo - St Bartholomew's.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Wọn fa aṣia iwaju Buckingham Palace wa si aarin

Aremo Phillip ati Ọbabinrin ni ọmọ mẹrin, ọmọ-mọ mẹjọ ati ọmọ-ọmọ-ọmọ mẹwa.

Akọbi ọmọkunrin wọn, Arẹmọ Whales, Prince Charles ni wọn bi lọdun 1948, lẹyin naa ni wọn bi aburo rẹ obinrin, Ọmọbabinrin Anne, lọdun 1950, Duke ti York, Ọmọba Andrew lọdun 1960 ati Earl ti Wessex, Arẹmọ Edward lọdun 1964.

Wọn bí Arẹmọ Phillip ni Greek island ti Corfu ni ọjọ kẹwa oṣu kẹfa ọdun 1921.

Baba rẹ Arẹmọ Andrew ti Breece ati Denmark jẹ ọmọ ọba kekere ti Ọba George I ti Hellenes.