Hijab Crisis: Elebuibon ní àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ náà fẹ́ káwọn ọmọ wọn máa wọ ìlẹ̀kẹ̀ lọ sílé ìwé

Ifayemi Elebuibon

Oríṣun àwòrán, Instagram/Ifayemi Elebuibon

Araba ilu Osogbo, Oloye Yemi Elebuibon t i sọ pe awọn ẹlẹsin ibilẹ naa fẹ ki awọn ọmọ awọn naa maa wọ ilẹkẹ lọ si ile ẹkọ.

Laipẹ yii ni ija bẹ silẹ niluu Ilorin lori awọn akẹkọọ musulumi tawọn alaṣẹ ileewe girama kristẹni ko gba laaye lati maa wọ Hijaabu wa si ileewe.

Awọn alaṣẹ ileewe naa naa yari pe ilana ẹsin kristẹni lawọn fi da awọn ile ẹkọ ọhun silẹ.

Fun idi eyi, wọn gbagbọ pe ko yẹ ki awọn akẹkọọ musulumi maa wọ hijaabu wa si iru ile ẹkọ bẹẹ.

Amọ, awọn musulumi ni ijọba ipinlẹ Kwara ti gba awọn ile ẹkọ yii lọwọ awọn ijọ kristẹni to dawọn silẹ.

Nitori naa, awọn musulumi sọ pe o yẹ kawọn ọmọ awọn to jẹ akẹkọọ lawọn iru ileewe bẹẹ lanfaani lati maa wọ hijaabu.

Nigba ti o n ba BBC Yoruba sọrọ, Elebuibon ni awọn ẹlẹsin abalaye naa lẹtọ labẹ ofin gẹgẹ bi awọn ẹlẹsin musulumi ati kristẹni.

''Ko lẹtọ ko jẹ pe ki wọn maa sọ fawọn ọmọ oniṣẹṣe pe ki wọn maa bọ ilẹkẹ to wa lọwọ wọn.

Awa o ni kawọn ọmọ musulumi maa wọ hijaabu, a o ni kawọn ọmọ kristẹni maa mu ilẹkẹ ''Rosary'' ni, ṣugbọn ki wọn jẹ ki awa naa ṣe ti wa.

Ki wọn jẹ ki onifa bọ Ifa, ki ọlọṣun bọ Osun, ki olodu bọ Odu, ki aye ba le dara,''Elebuibon ṣalaye.

Agba babalawo naa fikun ọrọ rẹ gbogbo ẹsin mẹtẹẹta loyẹ ki ijọba fun laaye lati ṣe ẹsin wọn lai ṣegbe fẹni kan.

Elebuibon ni ''ooṣa lo ni gbogbo ilẹkẹ ti a ni nilẹ Yoruba.

Ilẹkẹ otutu ọpọn ni wọn maa n fi dawọn oniṣẹṣe mọ, awọn oni Sango le mu irọkẹ lọwọ.''

Elebuibon ni o jẹ iyalẹnu pe nnkan ti ara wa ni kii wu wa.

Araba ilu Osogbo sọ pe awọn musulumi atawọn kristẹni to bara wọn lori ọrọ wiwọ hijaabu, ai si ifẹ lo n fa iru iṣẹlẹ bẹẹ.

Elebuibon rọ awọn kristẹni ati musulumi papaa julọ niluu Ilorin pe ki wọn lọ wa imọ nipa ẹsin miiran nitori ko yẹ ki ẹsin fa ija rara.

Agba babalawo naa ṣalaye pe awọn oniṣẹṣe yoo gbe aba naa lọ si iwaju ijọba lati ṣe agbekalẹ ofin ti yoo fawọn oniṣẹṣe naa lanfaani lati maa ṣe ẹsin gẹgẹ bi wọn ṣe fẹ.