Alaafin: Ọba Adeyemi kọ̀ ilé alárinrin méjì fún Ayaba Folashade ati Omowunmi

Oríṣun àwòrán, olori_omoh_one/Instagram
O ti foju han gbangba pe kii se olori kansoso ni Alaafin tilu Oyo, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta fun ni ẹbun ile alarinrin.
Ọjọ Aiku la mu iroyin wa fun yin pe Kabiyesi naa fun Olori Memunat Omowunmi ni ẹbun ile alarinrin kan nilu Ibadan.
Amọ olori keji, Aishat Folasade toun naa gba ẹbun ile alarinrin mii naa ti kede sita loju opo ibanidọrẹpọ rẹ pe oriire naa kan oun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ wo ìdí tí omije fi bọ́ lójú Pasuma níbi ìgbéyàwó ọmọ rẹ̀ obìnrin
- Ẹ̀tanú ní kó jẹ kí wọ́n gbé ipò ààrẹ fún MKO Abiola - Obasanjo
- Alaafin kọ́lé tuntun fún ọ̀kan lára Olorì rẹ̀ ní Ibadan, ariwo sọ
- Davido, Pasuma àti Yinka Ayefele dábírà lópin ọ̀sẹ̀, aráyé múgbe bọnu
- Yorùbá sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Arewa lórí bó ṣe fẹ́ àtúntò Nàíjíríà àmọ́ tó tako pínpín ipò ààrẹ
- Ìsìn àrà ọ̀tọ̀ wáyé níjọ Canterbury Cathedral láti yẹ́ Ọmọọba Phillip sí
- Jàndùkú pa ìyá ọlọ́mọ mẹ́ta l‘Eko bó ṣe kù díẹ̀ kóun àti ẹbí rẹ̀ lọ tẹ̀dó sí Canada
Nigba to n sọrọ loju opo Instagram rẹ, Olori Folasade n dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ẹbun naa, to si n ki ara rẹ ku oriire ati ibukun to ri gba.
Oríṣun àwòrán, ayaba_folashade
"Lotitọ, aafin suuru ni ile yii. Ọlọrun dara si mi, mo si n dupẹ lọwọ Kabiyesi pe o jẹ ọkọ daradara.
Mo ki ara mi ku oriire, mo si gba adura pe ki Ọlọrun tubọ maa bukun fun mi siwaju si.
Emi ni iya onile tuntun lọwọlọwọ laarin igboro."
Iroyin ohun to n lọ fi ye ni pe kori-kosun ni Olori Folashade ati Olori Omowunmi, ti ajọsepọ to dan mọran si wa ni aarin awọn mejeeji.
Ankoo asọ ni wọn maa n wọ lọ sode nigba gbogbo, ti wọn si maa n dijọ ya aworan papọ lori ayelujara lati fi han araye pe ọrẹ gidi ni awọn laafin Oyo.
Bakan naa ni Olori Omowunmi fidi rẹ mulẹ pe kii se oun nikan ni oun gba ẹbun ile alarinrin yii, nitori ọrọ to sẹsẹ kọ soju opo Instagram rẹ lo sisọ loju eyi.
Olori Omowunmi mi oun ati Olori Folashade ko sẹsẹ maa pe ara awọn ni oloriire julọ laarin awọn obinrin.
Female Car Painter: Èmi ní obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò máa ṣiṣẹ́ akunmọ́tò ní Ibadan
"A ko mọ pe yoo sẹ nibẹrẹ amọ agbara to wa ninu ahọn ta fi n sọrọ, ti jẹ ki ọrọ naa wa si imusẹ.
Emi ati olori oloriire keji, Ayaba Folashade wa n dupẹ pupọ lọwọ baba ati ọkọ wa, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta fun ẹbun naa.
Kii se pe ẹbun naa yẹ fun wa, a kan ri aanu gba ni. Ọkan imoore wa ko si to lai jẹ pe a dupẹ lọwọ awọn Ayaba yoku pe wọn ko ni ri ibanujẹ laye wọn."
Ile mejeeji ti Alaafin kọ yii fun awọn olori mejeeji lo wa ni ẹgbẹ ara wọn, to si jẹ aworan ati ọda kannaa.
Koda, ọjọ Satide ni wọn si ile mejeeji, tawsn Olori Omowunmi ati Ayaba Folasade si wọn asọ ankoo lati si ile wọn.
Alaafin kọ́lé tuntun fún ọ̀kan lára Olorì rẹ̀ ní Ibadan, ariwo sọ
Oríṣun àwòrán, olori_omoh_one/Instagram
Idunnu ti subu lu ayọ ni aafin Oyo bayii nitori bi Alaafin tilu Oyo, Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta se kọ ile fun ọkan lara awọn olori rẹ, Ayaba Memunat Omowunmi Adeyemi.
Ayẹyẹ isile naa si lo waye ni ọjọ Satide, ọjọ Kẹwa osu Kẹrin ọdun 2021.
Gẹgẹ bi ayaba oloriire naa ti kọ soju opo Instagram rẹ, o foju han pe ilu Ibadan ni ile alaja kan , to jẹ ọna meji naa wa.
Aworan ti Olori Omowunmi fi sita fihan pe ile alaja kan wa niwaju, omiran tun wa lẹyin, ti wọn si kọ wọn ni irufẹ aworan kan naa.
- Eyí ni àwọn arẹwà 'ẹ̀lẹ̀ Daddy', àfẹ́fẹ́ tí Aláàfin fi ń mí
- Wo àwọn olorì àgbà mẹ́rin tí Aláàfin ń wárí fún
- Àwọn olorì Aláàfin fi oríkì awúnilórí yẹ́ ọkọ wọn sí fún àádọ́ta ọdún tó gorí ìtẹ́
- N kò mọ bí wọ́n ṣe n bá obìnrin sọ̀rọ̀ ìfẹ́ - Aláàfin
- Wo ọ̀nà tí àwọn ‘ẹ̀lẹ̀ Daddy’ gbà dé ààfin Ọyọ
- Kí ló wà ní ìdí igbá tí àwọn olorì Aláàfin máa ń tí lóde Ọ̀yọ̀
- Alaafin bi ibeji l‘ẹẹmeji lọsẹ kansoso
- Kí ló ń ṣẹlẹ̀ láàfin Oyo táwọn èèyàn fi ń ki Alaafin ní mẹ́sàn án mẹ́wàá?
- Irú ẹ̀dá wo ni Lamidi Adeyemi? Aláàfin tó rí ìbẹ̀rẹ̀ àti opin sáà gómìnà mọ́kànlélógún l‘Oyo
Ile alarinrin naa lo pe ni 'Palace of Patience' eyi to tumọ si Aafin Suuru.
Koda, ọda kan naa ni wọn fi kun awọn ile naa, to si ni aburada fun aaye igbọkọsi lọna igbalode niwaju ile, bẹẹ ni wọn mọ ogiri yi ile ọhun ka.
Oríṣun àwòrán, olori_omoh_one/Instagram
Bakan naa ni aworan ile yii fihan pe adugbo to jẹ oju ni gbese nilu Ibadan ni ile naa wa, koda, o dabi ẹnipe adugbo Bodija nilu Ibadan ni.
Koda, Alaafin funra rẹ, ati awọn eeyan jankan jankan ti wọn fi iwe pe, lo wa si ile ọhun.
Yoruba ni Yinni Yinni, kẹni le se omii ni, eyi si lo mu ki Olori Omowunmi maa ki ọkọ rẹ, Alaafin ni mẹsan mẹsan mẹwa fun inawo rẹ lori ile naa.
Olori Memunat Omowunmi salaye loju opo Instagram naa, wa ki ara rẹ ku oriire fun ẹbun ile alarinrin ti ọkọ oun, fun oun bii ẹbun.
Oríṣun àwòrán, olori_omoh_one/Instagram
"Mo gba ẹbun ile lọwọ ọba, tii se ọkọ mi, oni yii, (ọjọ Satide) si ni ayẹyẹ isile naa. Mo dupẹ lọwọ gbogbo awọn to wa ba mi yọ.
Pẹlu ẹmi irẹlẹ ati ọwọ, ni mo fi n mọ riri ọkọ mi, baba awọn ọmọ mi fun ohun gbogbo to ti n se fun mi.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìjà parí! Ẹgbẹ́ dókítà dáwọ́ ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ mẹ́wàá dúró
- Duke ti Edinburgh ti dágbére fáyé lẹ́ni ọdún 99
- Ìlẹ̀kẹ̀ otútú ọgbọ̀n, Ìrọ́kẹ́, àwa ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ náà fẹ́ káwọn ọmọ wa máa wọ lọ sílé ìwé - Elebuibon
- Àrà kengé! Ṣọ́ọ̀ṣì Church of England fẹ́ dá ère idẹ Benin méjì padà sí Nàìjíríà
- Ẹ wo àwòrán bí wọ́n ṣe yìbọn sókè káàkiri Ilẹ̀ Gẹ́ẹ̀sì láti ṣẹ̀yẹ Duke ti Edinburgh
N ko le dupẹ lọwọ rẹ tan, nitori atilẹyin rẹ nigba gbogbo ko lonka, ,o si gbadura pe ki Ọlọrun fun wọn ni ilera pipe, ki wọn tun le se fun mi ju bẹẹ lọ."
Bakan naa ni Olori iya onile tuntun yii, tun mọ riri awọn eeyan to wa ba yọ ayọ ile tuntun naa.
Oríṣun àwòrán, olori_omoh_one/Instagram
Ohun rere ko ni wọn ninu ile gbogbo wa, mo si gba adura pe ayọ laa maa ba ara wa yọ."
Nibi ayẹyẹ awẹjẹwẹmu naa si ni ọpọ eeyan ti jẹ ajẹyo, ti wọn si tun fi ijo sara.
Gbogbo awọn ololufẹ Olori Memunat Omowunmi Adeyemi si lo ti wa n ki ku oriire ẹbun ile tuntun naa, ti wọn si n gbadura pe ẹmi rẹ yoo lo.