Davido: Ó fún Yinka Ayefele ní ₦1m, tó sì tún fẹ́ ran ẹ́ni tó fẹ́ pa ara rẹ̀ lọ́wọ́

Davido gbe miliọnu kan naira to fẹ fun Yinka Ayefele lọwọ

Oríṣun àwòrán, davido/Instagram

Se ni ori ayelujara n gbona lopin ọsẹ nitori awọn isẹ aanu kan ti ilumọọka akọrin taka n sufe nni, David Adeleke, ti ọpọ eeyan mọ si Davido se.

Se ni ojo owo yanturu rọ fun gbajumọ olorin Tungba, Yinka Ayefele lagbo ode ere kan ti Davido yọju si, to si na miliọnu kan naira fun bii owo imọri.

Ayẹyẹ inawo kan to waye nilu Abẹokuta nibi ti Yinka Ayefele ti sere loju agbo, ni Davido yọju si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to gbe fidio naa soju opo Instagram rẹ, Ayefele mọ riri ẹbun owo ti Davido fun naa, to si ni oun dupẹ fun iyi ati ẹyẹ to se fun oun.

Lasiko ti Davido de iwaju Ayefele, ni Akọrin Tungba naa mu orin bọnu, eyi to jẹ ọkan lara orin Davido to gbajumọ.

Oríṣun àwòrán, yinkaayefele/Instagram

Bi Ayefele si se n pariwo 'Ẹ ma da mi duro, emi lọmọ baba olowo...' ni Davido na owo naa si, to si tun bẹrẹ si ni fi ẹsẹ rajo.

Amọ nigba to ya, ni Davido gan gba ẹrọ amohunbugbẹnu, eyiun Maikirofoonu lọwọ Ayefele, to si n kọrin sẹlẹru agbo, agbara agbo, ni Ọsun fi n wẹ ọmọ rẹ, ki dokita to de.

Orin bii orisi mẹta ni Davido kọ loju agbo naa, to fi mọ alowo ma jaye, ẹyin lẹ mọ, tawọn eeyan oju agbo si n fi ẹsẹ rajo.

Amọ se ni Ayefele naa n na owo pada fun Davido, tọrọ naa si dabi olowo pade olowo.

Ninu fidio naa si lo ti fi oju han pe gbajumọ akọrin Fuji naa, Pasuma wa loju agbo yii, toun naa si n kọrin ki Davido ni mẹsan mẹwa.

Oríṣun àwòrán, yinkaayefele/Instagram

Davido, ti ko lo ju isẹju marun lọ loju agbo naa, wa di mọ Ayefele, to si di mọ ọ, ko to kuro loju agbo naa.

Davido rawọ ẹbẹ si ẹni to fẹ gbẹmi ara rẹ lati yi ero rẹ pada:

Bakan naa lopin ọsẹ yii, lara isẹ aanu mii ti Davido tun se ni bo se ke si awọn eeyan lati ba oun wa ọkunrin kan to fẹ gbẹmi ara rẹ.

Ọkunrin naa, to gbe oogun asekupani to fẹ lo soju opo Instagram rẹ, lo wa kọ ọrọ sabẹ aworan oogun naa pe ko si ẹnikẹni to bikita nipa oun.

Ni kete ti Davido si foju gan ni ọrọ naa ati bi ọkunrin yii, ti oju opo ibanidọrẹ rẹ ni Instagram jẹ @rjlawal se setan lati gbẹmi ara rk, lo ba fesi pada fun.

Oríṣun àwòrán, rjlawal/Instagram

Davido ni "Arakunrin mi, Ọlọrun bikita fun ọ..., n ko mọ ọ ni ojukoroju amọ mo setan lati ran ọ lọwọ... Ẹ jọwọ, ẹ ba mi kan si ọkunrin naa, pe mo n wa lati seranwọ fun."

Igbesẹ Davido yii si lo mu ki ọpọ eeyan maa kọrin rere kii, ti wsn si n gbe osuba randẹ fun pe eeyan rere ni, oloju aanu si ni pẹlu.

Ọpọ eeyan lo wa ki Davido lẹyin, ti wsn si n rawọ ẹbẹ si Lawal pe ko mase gbiyanju lati da ẹmi ara rẹ legbodo.

Amọ titi di akoko yii, ọkunrin naa ko tii yọju sita lati wa beere iranwọ ti Davido seleri lati se fun.