Bí àwọn gbájúẹ̀ ṣe lu ìyá ẹni ọdún 90 ní jìbìtì $32 mílíọ́nù dọ́là rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn gbajuẹ kan ti wọn dibọn gẹgẹ bi alaṣẹ lati orilẹ-ede China ti lu iya arugbo ẹni aadọrun ọdun kan ni jibiti owo to to miliọnu mejilelọgbọn dọla owo ilẹ Amẹrika
Awọn ọlọpaa ni Hongkong ṣalaye pe awọn ọdaran naa yoo maa mura bi awọn oṣiṣẹ alaabo ilu to n ṣe iwadi awọn iwa ọdaran kan ni China lati ṣiṣẹ ibi wọn.
Awọn gbajuẹ naa sọ fun mama arugbo ọhun pe eeyan kan ti ji orukọ rẹ to si n lo o ni China.
Wọn ni ko san owo sinu aṣuwọn banki ni igba mọkanla laarin oṣu kẹjọ si oṣu kini ọdun yii fun wọn lati lee fi dọdẹ ẹni to n ji orukọ rẹ lo naa.
Ni bayii, ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ ọdọkunrin ọmọ ọdun mọkandinlogun kan ti wọn gba beeli rẹ.
Budo Ikoko water problem: Ìyàwó wa ti sá lọ kúrò ní Asa nítorí àìsí omi- Alhaji Sunmonu
Awọn ileeṣẹ iroyin ni HongKong gbe e sita pe oṣu kẹjọ, ọdun to kọja ni wọn kọkọ kan si obinrin naa.
Wọn dibọn bii pe oṣiṣẹ lati orilẹ-ede China ni awọn ki wọn to wa lọ fun iya naa ni foonu ibanisọrọ kan pe oun ni ko maa fi pe awọn nigbakugba to ba fẹ pe wọn.
hhhhhh
Ara awọn ọmọ ọdọ iya arugbo naa lo pariwo sita fun awọn ọmọ rẹ nipa awọn iwa kotọ tawọn eeyan, ti wọn ro pe oṣiṣẹ alaabo latọdọ ijọba, naa n hu.
Iya agba naa ko gbe pẹlu awọn mọlẹbi rẹ ṣugbọn o ni ọpọlọpọ awọn oṣiṣẹ bi ọmọọdọ to n baa ṣiṣẹ ni ile rẹ to wa ni ọkan lara awọn ibugbe awọn to rijajẹ lawujọ ni Hong Kong.
- Àwọn ọlọ́pàá ti dóòlà ọmọbìnrin tí àwọn òbí rẹ̀ so mọ́lẹ̀ fún ọdún 10
- Ọwọ́ NDLEA tẹ akẹ́kọ̀ọ́ fásitì tó n ta 'cookies' tí wọ́n fi oògùn olóro ṣe fún àwọn ọmọ́de
- Ilé ẹjọ́ dá ẹjọ́ ìdálẹ́bi fún Derek Chauvin lórí ẹ̀sùn gbogbo lórí ikú Floyd
- Tani Mahamat Kaka Idriss Deby tó di aàrẹ̀ tuntun ilẹ̀ Chad lẹ́yìn ìṣekúpani bàbá rẹ̀?
- Wo àwọn nkan tó yẹ́ kí o mọ̀ nípa Olufon, Ọba Adekunle Magbagbeola tó wàjà
- Ó dá wa lójú pé Eyitayo Jegede á borí nílé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn- Ondo PDP
Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba: Ẹ̀yà Ara Ifọ̀ ní olùkọ́ Adedokun kọ́ wa