10 Streets In Ilorin: Oke Kura, Ita Ogunbọ, Ita Kudimoh jẹ́ ara orúkọ àdúgbò tó níí ṣe pẹ̀lú ìjà Oyo àti Ilorin

Aworan ọkunrin to gun ẹsin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ilu Ilorin wa lara awọn ilu ilẹ Yoruba to lamilaaka, ti itan idasilẹ rẹ si nii se pẹlu ilẹ Kaarọ ojire.

Ilorin jẹ ilu kan to kun fun itan ati iriri bi awọn Yoruba ati awọn ẹya miran bii Fulani, Bariba, Tapa atawọn ẹya miran lapa Oke Ọya, se ni ajọsepọ, eyi to bi irẹpọ oniruuru aṣa ti ko si iru afiwe rẹ nilẹ Yoruba kankan.

Itan ilu Ilorin pọ debi pe ti a ba ni ka maa sọ labẹ apilẹkọ yii, a ko ni le e pari rẹ, amọ a le se agbeyẹwo awọn orukọ adugbo to jẹ manigbagbe nilu Ilorin to n safihan ibasepọ Oyo ati Ilorin laye atijọ.

Awọn adugbo naa ree:

Oke Kura

Nigba ti Alaafin Oluewu ti ilu Oyo kogun ja Ilorin ni ọdun 1835, ọkan lara awọn jagunjagun to dara pọ mọ awọn ọmọ ogun Oyo ni Woru Kura.

Kura ni orukọ inagijẹ rẹ, ti eleyi si tumọ si Ìkookò (Hyena) lede Hausa.

Jagunjagun yii jẹ ẹya Baruba ti a si mọ si Sona Kpera.

Wọn fi adugbo Oke Kura sọri rẹ nitori pe ibẹ ni ọwọ awọn ọmọ ogun Ilorin ti tẹ.

Oke Kura gba orukọ rẹ lẹyin iṣẹlẹ yii ati pe, ni Oke Kura ni wọn ti ṣekupa Sona Kpera.

Bi awọn eeyan ko ba fẹ pe orukọ adugbo yii ni Oke Kura, wọn a tun maa pe ni Ode Olohunmamuwa nitori ọgba ẹwọn to wa nibẹ.

Àkọlé fídíò,

'Fulani Ilorin l'ọkọ mi'

Ita Ogunbo/Ita Kudimoh

Orukọ awọn adugbo mejeeji yii naa ni ohun ṣe pẹlu ogun ti Oyo ko ja Ilorin lọsun 1835, eyi ta mẹnu ba saaju.

Itumọ orukọ adugbo Ita Ogunbọ, ninu alaye tawọn onimọ nipa itan Ilorin ṣe fun wa, pin si ọna meji.

Akọkọ ibẹ ni pe lasiko ogun yii, adugbo ibi ti oogun tawọn ọmọ ogun wọn ti jabọ, ni wọn fi sọri adugbo yii.

O tumọ si pe ''Ita ti oogun ti bọ'' ni kukuru, Ita Ogunbọ.

Alaye ẹlẹẹkeji ni pe adugbo yii ni ibi ti wọn ti n bọ ''Ogun'' ṣugbọn itan eleyi ko gbalẹ to alakọkọ.

Àkọlé fídíò,

Ìjọba AbdulRazaq ti wólé aláànúú wa ní Ilorin

Ita Kudimoh

Adugbo Ita Kudimoh, gẹgẹ bi itan ti a ri ka ninu iwe alagba LAK Jimoh, naa ni ohun ṣe pẹlu ogun ti a n ba ọrọ rẹ bọ.

Ita Kudimoh ko jina si Ita Ogunbo, nibi ni iku di awọn ọmọ ogun Oyo to wa kogun ja Ilorin mọ.

"Ita ti iku di wọn mọ". Ita Ẹgba

Adugbo yii ni ibi ti awọn eeyan Ẹgba to n gbe nilu Ilorin tẹdo si.

Titi di oni, agboole kan wa ti wọn n pe ni Ile Ẹgba, ti eleyi si fi han pe orisirisi ẹya Yoruba lo wa nilu Ilorin.

Yatọ si orukọ agboole Ile Ẹgba yii, awọn agboole mii naa bi Agboole Ologbomoṣọ, Agboole Baba Offa ati awọn agboole mii, ti orisun wọn jẹ ti ilẹ Yoruba wa ni Ilorin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Geri Alimi/Garin Alimi

Yoo ṣoro ki eeyan maa bọ lati Eko tabi Ibadan wa si Ilorin, ko ma kọja niwaju opopona tabi adugbo taa n pe ni Geri Alimi.

Geri Alimi jẹ adugbo ikini kaabọ si ilu Ilorin ni kete ti eeyan ba ti n wọ inu ilu bọ.

Ṣugbọn orukọ Geri Alimi ti wọn fi sọ adugbọ yii jẹ ilumọọka ni Ilorin, paapa bi a ba wo itan bi awọn Fulani ti ṣe tẹdo ni ilu naa.

Adugbo yii si ni Alimi tẹdo si, ẹni tii se Fulani to gba Ilorin lọwọ Aarẹ Ọna Kakanfo, Afonja.

Oríṣun àwòrán, Xultan Visuals

Geri Alimi tumọ si ilu Alimi tabi ilu onimọ.

Adugbo yii si ni awọn Fulani musulumi labẹ idari Sheikh Salih Janta, tawọn onitan a maa pe ni Alimi tẹdo si, lati maa ṣiṣẹ Daawah tabi iwaasu wọn.

Loni bi a ba pe Geri Alimi, ile iwosan to wa nibẹ ti wọn n pe orukọ rẹ naa ni Geri Alimi Hospital, lọpọ a maa ranti.

Post Office

Nibi yii ni ijọba ṣe flyover ẹyọ kan ṣoṣo to wa nilu Ilorin si.

Ile ifiweranṣẹ Post Office to wa niwaju ibẹ ni wọn fi sọ orukọ adugbo yii.

Lara nkan tawọn eeyan si mọ Post Office si ni pe, awọn to n ta ọja lẹgbẹ oju irin reluwe ko jina sibẹ, ati pe o jẹ gẹgẹ bi ọna tawọn elero ọkọ to n gbe ilu bi Offa ati Oshogbo ti maa n gbe ero.

Bi awọn eeyan ba si n ṣe iwọde, Post Offfice wa lara ibi ti wọn maa n pejọ si nitori pe awọn eeyan a maa pade nibi lọpọ igba.

Oríṣun àwòrán, Gobir Foundation

Okesuna

Adugbo yii ni gbajugbaja onimọ ẹsin Islam Solagberu ati awọn eeyan rẹ tẹdo si nigba ti wọn fi wa si Ilorin.

Yatọ si pe Solagberu jẹ alufaa, o tun jẹ onisowo.

Saaju ki Alfa Alimi to de silu Ilorin, wọn ka Okesuna gẹgẹ bi agbegbe to wa lẹyin ilu ti wọn n pe ni Ilorin gan.

Loni awọn to n ta ọja ati awọn Hausa lo wa ni adugbo naa loni.

Ileewe alakọbẹrẹ akọkọ ni Kwara ta mọ si Okesuna Primary School wa ni adugbo yii.

Ọdun 1915 ni wọn da ileewe naa silẹ ni wọọdu Zango to wa labẹ ijọba ibilẹ iwọọrun Ilorin.

Ninu awọn eekan ilu Ilorin to kẹkọ jade ni ileewe naa ni Mallam Muhammadu Ajeigbe Gobir(1900-1960), Waziri ilu Ilorin akọkọ.

Pakata

Aarin gbungbun Ilorin nibi ti awọn eeyan mọ si Oke Male ni adugbo taa n pe ni Pakata wa.

Opopona rẹ, Pakata Road si bẹrẹ lati Oja Oba titi to fi de ''Roundabout'' Pakata.

Adugbo Pakata lamilaaka laarin awọn eeyan Ilorin nitori awọn eeyan jankan jankan ọmọ bibi ilu Ilorin to wa lati ibẹ.

Adugbo Pakata ni wọn ti bi oṣere tiata ilumọọka nii, Adebayo Salami, tawọn eeyan mọ si ọga Bello.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lagbo oṣelu, awọn ilumọọka bi S.B Pakata ati awọn alfa onimọ bi Sheikh Ghali Alaaya wa lati adugbo Pakata.

Adugbo Pakata naa ni wọn da Ileewe alakọbẹrẹ keji ni Kwara si lẹyin ti Okesuna, iyẹn Pakata Elementary School.

Bi eeyan ba fẹ lọ si adugbo bi Alore, Adeta, Ita Nmo ati Oloje to fi mọ Ogidi ati Oko Olowo, o le gba Pakata de ibẹ.

Taiwo Road

Opopona Taiwo nilu Ilorin kan, Ilorin kan ni.

Bi eeyan ba si ti wọ inu ilu naa, ni yoo ti ri pe ọna yii yatọ nipa titi rẹ ati awọn ile itaja to wa lapa ọtun ati osi rẹ.

Wọn fi orukọ opopona Taiwo road sọri ọgagun Ibrahim Taiwo, to jẹ alakoso ipinlẹ naa lasiko ijọba ologun ọdun 1975-1976.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi a ko ba gbagbe, lasiko ifitẹgbajọba ni wọn pa Ibrahim Taiwo ati ọgagun Murtala Mohammed to jẹ olori ologun Naijiria nigba naa.

Ni iranti rẹ ni wọn fi sọ opopona yii ni Taiwo Road.

Ṣaaju igba naa "Oyo Bye-Pass" ni a ri akọsilẹ pe wọn n pe adugbo yii.

Unity Road

Orukọ meji ni adugbo Unity Road n jẹ.

Lọkan awọn araalu, Unity Road ni wọn mọ opopona ọhun si ṣugbọn lakọsilẹ lọdọ ijọba, Wahab Folawiyo lorukọ rẹ n jẹ.

Eyikeyi ti ẹ ba darukọ fawọn awakọ, ko si eyi ti wọn ko mọ.

Oríṣun àwòrán, Ilorin Info

Opopona Unity bẹrẹ lati iyana tawọn adari ọkọ Traffic Warden wa ni Taiwo ki a to maa lọ si Taiwo Isale.

Loju ọna yii laa ti ri ileeṣẹ awọn panapana ati ile inaju taa mọ si Amusement Park.

Lopopona Unity bakan naa, awọn ile ijọsin bi ECWA naa wa, ti awọn ile itaja naa si wa nibẹ.