Makinde convoy in Ogbomosho: Alao Akala, APC ṣàlàyé bí ọmọ ṣe kú lásìkò ipolongo ìbo l‘ogbomoso

Seyi Makinde ati Alao Akala

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Alao Akala Facebook

Ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Oyo ti fi ẹdun ọkan rẹ han lori isẹlẹ ibanujẹ to waye nigba ti ọkọ kan tẹ ọmọdebinrin kan pa nilu Ogbomoso lọjọbọ.

Isẹlẹ naa ni wọn di ẹbi rẹ ru ọkan lara awọn ọkọ to kọwọrin pẹlu gomina Seyi Makinde lọ seto ipolongo ibo ijọba ibilẹ nilu Ogbomoso amọ ti gomina ti sẹ pe ko ri bẹẹ.

Nigba to n wa safihan bi isẹlẹ naa se ka lara to, ẹgbẹ oselu APC ni o se oun laanu pe gomina Makinde ko tiẹ gbinyanju lati se awari ẹni to se iku pa ọmọdebinrin naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atẹjade kan ti ẹgbẹ APC fisita lori isẹlẹ naa lọjọ Ẹti, eyi ti akọwe ipolongo rẹ, Ọmọọba Ayọbami Adejumọ fisita ni iwa aimọ ojuse ẹni to tii buru julọ ni Makinde hu.

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde Facebook

APC ni ko dara bi gomina Makinde se kọ jalẹ pe kii se ikọ to kọwọrin tẹle oun lẹyin, lọ se ipolongo ibo lo pa ọmọ naa, nigba ti iwadi ti fihan pe, ọkan lara awakọ awọn alatilẹyin gomina to tẹle lọ silu naa, lo huwa ibi yii.

"Ọkan lara awọn to tẹle Seyi Makinde lẹyin, to n wa mọto laibikita lati da ibẹru sọkan aya ara ilu, lo fi ọkọ pa smọdebinrin naa.

Atẹjade naa ni ẹni ti aje iwa ibajẹ yii si mọ lori jẹ ọkan lara ọmọ ẹgbẹ alakoso gareji ọkọ nipinlẹ Oyo, to si tun jẹ ọmọ ẹgbẹ oselu PDP."

Ẹgbẹ oselu APC wa n rọ awọn agbofinro lati se iwadi wọn bo se yẹ lori isẹlẹ naa, ki wọn si ri pe ẹni to pa ọmọ naa gba idajọ to yẹ labẹ ofin.

Àkọlé fídíò,

Epe Fish Market: Wá wo oríṣi ẹja tí o rírí lọ́jà ẹja tó tóbi jùlọ ní Nàíjíríà

Seyi Makinde, fi oju ẹni to pa ọmọde ni Ogbomoso han fun araye - Alao Akala

Wayi o, Gomina tẹlẹ nipinlẹ Oyo, Oloye Adebayo Alao-Akala ti ke pe gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde pe ko wa ẹni to fi ọkọ pa ọmọde kan niluu Ogbomoso.

Alao-Akala sọ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Ẹti wí pe, ẹnikan lara awọn to kọwọ rin pẹlu Makinde wa si Ogbomoso l'Ọjọbọ lo ṣeku pa ọmọ naa.

Alao-Akala ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi ohun to ba ni lọkan jẹ, papaa julọ bi baba ọmọdekunrin naa ṣe gbe oku rẹ dani pẹlu ibanujẹ ọkan ati omije loju.

Gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ ni ẹni to pa ọmọdebinrin yii ti ko jẹ ko dagba, gbọdọ foju wina ofin, iru eeyan to wu ti ko ba a jẹ.

Àkọlé fídíò,

Down Syndrome Skill centre: Wo bí ọmọ tí ọpọlọ wọn kù díẹ̀ ṣe ń kọ́ iṣẹ́ agẹrun

"Makinde gbọdọ ri pe idajọ ododo waye lori iṣẹlẹ yii lati le jẹ arikọgbọn fawọn awakọ oniwa kuwa," Alao-Akala ṣalaye.

Gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ ni oun mọ irora ti baba ọmọ naa n la kọja bayii lẹyin iṣẹlẹ naa.

Alao-Akala ni gomina ipinlẹ Oyo gbọdọ jẹ ki gbogbo araalu mọ abajade iwadii ti ijọba ba ṣe lori iṣẹlẹ naa.

Ṣé lóòtọ́ ni mọ́tò tó kọ́wọ̀rín pẹ̀lú Seyi Makinde pa ọmọdébìnrin kan l'Ogbomoso?

Oríṣun àwòrán, Twitter/seyi Makinde/other

Ni Ọjọbọ ni iroyin kan jade pe ọkọ kan pa ọmọdebinrin jojolo kan nitosi ibi ti ẹgbẹ oṣelu PDP ti n ṣe ipolongo itagbangba wọn lagbegbe Ọja Igbo nilu Ogbomọṣọ.

Wọn ni ọkan lara awọn ọkọ to kọwọrin pẹlu gomina Seyi Makinde lo seku pa ọmọ ọmọ naa.

Iṣẹlẹ yii fa ọpọ ariwo nibi ipolongo naa eleyii ti gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde pẹlu peju si.

Iroyin sọ pe awọn mọlẹbi ọmọ naa gbe oku rẹ wa sibi ipolongo itagbangba naa lati beere fun idajọ ododo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oniruuru iroyin lo jade nipa bi iṣẹlẹ iku ọmọ naa ṣe waye, bi awọn kan ṣe n sọ pe ọkan lara awọn ọkọ to ba gomina kọwọrin lo ṣeku pa ọmọdebinrin naa.

Àkọlé fídíò,

Oyo LG Polls: OYSIEC ní APC ló yẹ kò bẹ aráàlú lórí àṣìṣe rẹ̀ nípa ìbò ìjọba ìbílẹ̀

Ni awọn eeyan miran n sọ pe o ku diẹ ki ikọ gomina Makinde de ibi ipolongo naa ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, gomina Seyi Makinde ṣalaye loju opo ayelujara Facebook rẹ pe, ọkọ to pa ọmọdebinrin jojolo naa ko si lara ọkọ to ba oun kọwọrin.

O wa ba awọn ẹbi ọmọde naa kẹdun nipa isẹlẹ laabi yii.

"Mo gbọ iroyin kan pe awọn ọkọ to ba mi kọwọrin pa ọmọdebinrin kan lasiko ti a n lọ si ilu Ogbomọṣọ, loni.

Iwadi wa fihan pe ọkọ eeyan kan ti ẹya rẹ jẹ Toyota Matrix, lo gba ọmọdebinrin yii. Kii ṣe ara ọkọ to ba mi kọwọrin rara."

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Tawo Adisa fi sita tun ṣalaye pe "Ikọ to ba gomina kọwọrin ti de adugbo Ọja Igbo nibi ti ipolongo itagbangba naa ti waye.

Koda, wọn ti wọn si ti joko sibi eto naa, igba ti eto ipolongo idibo naa n lọ lọwọ, lawọn eeyan kan ya wọ ibudo ipolongo ibo naa pẹlu oku ọmọde naa."

Nigba to ṣalaye pe awọn agbofinro ṣi n wa awakọ Toyota Matrix naa, Gomina ipinlẹ Ọyọ rọ awọn eeyan ilu Ogbomọṣọ lati fiyedenu pẹlu idaniloju pe, ijọba yoo tu iṣu de isalẹ ikoko ọrọ naa.