Olusegun Obasanjo: Àwọn òǹtàjà fi tijó-tìlú pàdé Baba Iyabo lọ́jà òròmọdìẹ

Oríṣun àwòrán, Kehinde Akinyemi
Aarẹ tẹlẹ ni Naijiria, Oloye Olusegun Obasanjo ti ṣeleri iranwọ ile itaja to dara, nigba to ṣe abẹwo sí ọja ti wọn fi orukọ rẹ sọ ni adugbo Oluyole Estate niluu Ibadan.
Obasanjo tun fi da awọn ọlọja loju pe oun yoo gbiyanju lati ri pe wọn rí atilẹyin ijọba gba ninu ọja ọhún.
Se lawọn ontaja tu yaya jade lọ pade baba Iyabo ni ọja ti wọn ti n ta òròmọdìẹ oojọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Tó bá dá Gani Adams lójú, kó dárúkọ àwọn ọ̀dàlẹ̀ inú Yoruba Nation - OPC New Era
- Obasanjo ṣàbẹ̀wò s'ọ́jà tí wọ́n fi sọrí rẹ̀ n'Ibadan, ó ṣèlérí ìrànwọ́ fáwọn ọlọ́jà
- Ààrẹ Buhari tí yan olórí ikọ̀ ọmọogun Naijiria tuntun
- Wo ohun màrùn-ún pàtàkì nípa ọ̀gá ológun tuntun
- Èpè elépè kò ní ràn ẹ́, aya Ajeyemi! Wo àwọn òṣèré tó ń fi àdúrà ré èpè ESABOD kúrò lóríi Toyin Abraham
- Ìgboro ayélujára ń gbóná lọ́wọ́lọ́wọ́ mọ́ Remi Tinubu lẹ́yìn tó pe obìnrin kan ní Tọ́ọ̀gì
Ọpọ awọn ọlọja naa lo fi ọja wọn silẹ lọ fi ijo ati ilu ki Obasanjo káàbọ̀.
Ninu atẹjade kan ti oluranlọwọ sí aarẹ ana lori ọrọ iroyin, Kehinde Akinyemi fi sita, o ṣalaye pe bíi ago mẹsan an kọja ogun iṣẹju ni Obasanjo balẹ bagẹ sí ọja naa.
Oríṣun àwòrán, Kehinde Akinyemi
O ni awọn oṣiṣẹ Obasanjo lo pe akiyesi rẹ si ọja naa pe, awọn ontaja n lo orukọ rẹ lati mu idagbasoke ba ọja ọhun lati ibẹrẹ pẹpẹ, to fi dé ibi tí o wa lonii.
Eleyii si ti jẹ ki ọja naa di gbajugbaja bayii, bo tilẹ jẹ pe ko si ipilẹ ti ọja naa le duro le lori.
"Ẹ gbe ọja yii silẹ nibi ti ẹ ti n ta, ti ẹ si n ra.
Ohun to kan fún wa lati ṣe bayii ni lati ni ìpìlẹ gidi ti a ko ba fẹ ki wọn le wa kuro nibi.
Ohun ti mo n sọ ni pe, máa ba gomina ipinlẹ Oyo sọrọ pe ki o fun wa nilẹ mii, ti ijọba ko ba le yọnda eyi ti a wa lori rẹ," Obasanjo lo sọ bẹẹ.
Oríṣun àwòrán, Kehinde Akinyemi
Ẹwẹ, olori ẹgbẹ awọn to ta oromọdiẹ oojọ ni Naijiria, Ọgbẹni Olaiya Ogunmoyewa ni abẹwo Obasanjo ti mu ibẹru kuro lọkan awọn ontaja lọja naa.
O ni ohun to ti n gbe awọn ontaja lọkan ni Obasanjo ti wa ojutu si.
Ẹbun fọto nla Obasanjo ni awọn ẹgbẹ ọlọja òròmọdìẹ naa fi mọ riri rẹ.
Ẹ le fi owó ra gbogbo ayé àmọ́ kò sí owó tó lè ra ẹ̀rí ọkàn mi - Obasanjo
Oríṣun àwòrán, Olusegun Obasanjo
Aarẹ tẹlẹ ni Naijiria, Oloye Olusegun Obasanjo ti koro oju si iwa kawọn eeyan maa gbe owo atawọn ọrọ aye miran bori iwa otitọ ati isẹ asekara.
Obasanjo ni eyi gan lo n se okunfa ọpọ isoro to n doju kọ orilẹede Naijiria lasiko yii.
Ilu Ibadan ni Obasanjo ti woye ọrọ yii nibi ifilọlẹ ileesẹ adani kan, pẹlu afikun pe a ko le fi iye ile, mọto tabi owo ti eeyan kan ni se odiwọn aseyọri rẹ.
- Bí Nàíjíríà bá fẹ́ kí ọdún 2021 dára, ohun tí yóò ṣe rèé - Obasanjo
- Bí mo ṣe ń tako Buhari bá ìjọba tiwantiwa mu - Ọbasanjọ
- Nàìjíríà yóò túbọ̀ máa wojú Obasanjo fún ẹkọ́, ọgbọ́n àti ìmọ̀ ni- Ààrẹ Buhari
- Bàbá ẹni ọgọ́ta ọdún dèrò ilé ẹjọ́ nítorí ó wọ inú oko Obasanjo láì gba àṣẹ
- Irọ́ ni o! Èmi kò forí ṣọta ìjàmbá ọkọ̀ òfúrufú kankan - Obasanjo
- Obasanjo, Gowon, Muhammed- wo àwọn olóri Nàìjíríà lọ́dọ̀ọ́
- Ẹpọ̀n àgbò kàn ń mì lásán ni lórí ètò ààbò Nàíjíríà tó mẹ́hẹ, kò ní já - Obasanjo
Amọ o ni ipa rere ti iru ẹni bẹẹ ba ko si idagbasoke awujọ to wa, ati iye eeyan to seranwọ lati mu idagbasoke ba igbe aye wọn lo yẹ ka wo.
Oloye Obasanjo wa fikun pe ko si owo kankan, bo ti wu ko pọ to, to le ra ẹri ọkan oun.
Aremu: Eré ìtàn nípa ìbí, àti jéèyàn pẹ̀lú ìpèníjà Olusegun Aremu Obasanjo
"Awọn nnkan ta n mọriri wọn lode oni jẹ ara isoro to n ba wa finra, to mu ki ifẹ owo leke tente.
Nilẹ Yoruba, ifẹ owo kii jẹ wa logun bikose iwa Ọmọluabi, otitọ inu, orukọ rere, ati isẹ asekara.
Amọ nibo ni gbogbo rẹ wa bayii? Se la rọ gbogbo wọn da si ẹgbẹ kan lati maa le owo kiri, nibo si ni iyi ati imọriri wa wa?"
O fikun pe laye ode oni, ẹnikẹni to ba lowo le ra ohunkohun amọ kii se oun nitori owo ti n ra ọpọ ẹri ọkan, to si n beere pe ki ni anfaani ẹni to ba ni gbogbo owo ile aye?
Obasanjo: Buhari ní àìlera lẹ́mìí, lára, àti lọ́kàn.
"Bawo lẹ se fẹ se odieọn aseyọri? Ohun ti aseyọri tumọ si fun emi ni pe ka mu ki ibi kan dara ju ba se baa lọ.
Eyi kii si se bi owo to ni ba se pọ to tabi iye ile to kọ ati ọkọ to ra, amọ o nii se pẹlu ipa to ko lati mu ki ibi kan dara ju bo se baa lọ."
Olusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun