Military Plane Crash in Ngeria: Ìgbà mẹ́ta rèé tí ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú mú ẹ̀mi ológun 20 lọ ní Nàìjíríà

Aworan isinku ọmọ ogun Naijiria

Oríṣun àwòrán, NAF/FACEBOOK

Iṣẹlẹ ijamba ọkọ ofurufu a maa waye lati igba degba kaakiri agbaye.

Orisirisi nkan lo maa n sokunfa ijamba ofurufu yii, bi aṣiṣe lati ọdọ awọn ẹda ọmọniyan tabi ki omiran si jẹ amuwa lati ọdọ Ọlọrun.

Iru iṣẹlẹ bayi ko yọ Naijiria silẹ amọ lẹnu oṣu meloo sira wọn, ijamba ọkọ ofurufu to n waye ti n mu ki awọn eeyan maa beere pe ki gan lo n ṣẹlẹ?

Ijamba ọkọ ofurufu to waye lọjọ Ẹti, nibi ti ọga awọn ọmọ ogun Naijiria, Ọgagun Ibrahim Attahiru ti padanu ẹmi rẹ, lo tun mi ilu titi bayii.

Oun nikan kọ lo ba ijamba yii lọ, awọn ọmọ ogun mẹwaa mii to kọwọrin pẹlu rẹ, naa dagbere fun duniyan.

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ki a to maa dahun nkan to ṣokunfa awọn ijamba wọn naa, ẹ jẹ ki a ṣagbeyẹwo awọn igba mẹta ọtọọtọ ti ijamba ọkọ ofurufu ti mu ẹmi awọn ọmọ ogun Naijiria lọ.

Ọjọ Kọkanlelogun oṣu Keji ọdun 2021, ọmọ ogun ofurufu NAF 201 ko agbako

Minsita feto irina ofurufu, Hadi Sirika lo kede iṣẹlẹ yii fun awọn ọmọ Naijiria.

Awọn ọmọ ogun Naijiria meje lo wa ninu baalu King Air B350i (NAF 201) ti o jabọ ni papakọ ofurufu ilu Abuja.

A gbọ pe awọn ọmọ ogun ofurufu naa n lọ si ipinlẹ Niger ni, ki wọn to padanu ẹmi wọn.

Oríṣun àwòrán, NIGERIAN AIRFORCE

Ko pẹ si igba naa, ti ọga ileeṣe ọmọ ogun ofurufu kede pe ki wọn ṣe iwadii ohun to fa ijamba yii.

Titi di ba ṣe n ko iroyin yii jọ, a ko mọ nnkan pato to mu ki baalu naa ja.

Ọkọ ofurufu ologun ti o poora lẹba Maiduguri ni Borno

Lọjọ Kọkanlelọgbọn oṣu Kẹta ni a gbọ ikede pe baalu Alpha Jet to fẹ lọ ṣe iranwọ fawọn ọmọ ogun ni Borno poora.

Ko kọkọ si ẹni to le sọ nkan to ṣẹlẹ si baalu (NAF) Alpha Jet aircraft (NAF475) naa laarin wakati meloo ti iṣẹlẹ yi waye.

Oríṣun àwòrán, NAF/FACEBOOK

Amọ nigba ti yoo fi di ọjọ Keji, ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu kede pe awọn awakọ baalu meji Flight, Lieutenant John Abolarinwa ati Flight Lieutenant Ebiakpo Chapele, lo ba iṣẹlẹ yi lọ.

Ikọ Boko Haram sọ pe awọn lawọn wa nidi ijamba yii ṣugbọn ileeṣẹ ologun ni ọrọ ko ri bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, NAF/FACEBOOK

Ijamba ọkọ ofurufu Kaduna Ọjọ Kejilelogun oṣu Kaarun

Eleyi ni iṣẹlẹ ijamba ọkọ to ṣẹṣẹ waye, to si mu ki awọn eeyan maa ṣe eemọ ohun to n fa iṣẹlẹ yi leralera.

Ọgagun agba awọn ọmọ Ogun Naijiria, Ibrahim Attahiru to ba iṣẹlẹ yii lọ ṣẹṣẹ gba iṣẹ ko pẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oun ati awọn ọmọ ogun mẹwaa miran ni wọn kọwọrin ninu ọkọ ofurufu to jabọ ni Kaduna yii.

Ki eledua dẹlẹ fawọn to ti lọ.