America's Newest Chess Master: Tanitoluwa rèé ògbóǹtarìgì ọmọdé aláyò eré Chess tó fi gbọ̀ọ̀rọ́ jẹkà

Aworan mọlẹbi Tanitoluwa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Jakejado agbaye lawọn ọmọ Naijiria tọmọde tagba ti n fi itan lelẹ nipa orisirisi igbiyanju wọn.

Ninu wọn la tun ti ri ọdọmdekunrin ọdun mẹwaa kan Tanitoluwa Adewumi to gbegba oroke lati di Chess Master tuntun ni ilu New York lorileede Amẹrika.

Pẹlu aṣeyọri yi, Tanitoluwa fi itan lelẹ gẹgẹ bi ogbontarigi elere ayo Chess ti ọjọ ori rẹ kere julọ ninu itan awọn elere Chess ni Amẹrika.

Nibi idije Fairfield County Chess Club Championship to waye ni ilu Connecticut lọjọ Kini oṣu karun un lo ti pegede.

Àkọlé fídíò,

Àìsàn jẹ́ kí àwọ̀ ara Amida dàbí ara ẹja

O ri ami ẹgbẹrun meji le ni okoolenigba ati meji gba eyi to mu U di ẹni kejidinlọgbọn ti ọjọ ori rẹ kere julọ lati gba ami yIi.

''Inu mi dun pupọ lati jawe olubori ati bi mo ti ṣe gba oye yii. Inu mi dun gaan pe ọwọ mi te oye ti mo n wa yii''.

Lẹyin ọdun mẹta gbako ni o ṣe aṣeyọri yi nitori nkan bi ọdun mẹta syin lo bẹrẹ si ni ta ere Chess.

Nigba ti yoo fi bẹrẹ, oun ati awọn mọlẹbi rẹ n sun ni ile awọn alainile l'Amẹrika ni.

Ohun to ṣokunfa eyi si ni pe wọn sa asala fẹmi wọn kuro ni Naijira nitori idojule ikọ Boko Haram ni Naijiria.

Ni bayi wakati mẹwa si mọkanla lojumọ ni Adewumi fi n ṣe igbaradi ti o si tun maa n raye lati sun fun igba diẹ,

O ti wa jere igbaradi rẹ bayi.

Afojusun Tani ni pe ko jẹ alayo Chess tọjọ ori r kere julọ ti yoo gboye Grandmaster lagbaye.

Ẹni to di ipo naa mu bayi lagbaye a maa jẹ Sergey Karjakin,to gba oye yi lẹni ọdun mejila ati oṣu mẹsan.

Ti Tanitoluwa ba gbaradi to si mura daada, o ṣeeṣe ki o gba oye yi.

Lọwọlọwọ bayi, ọmọ ọdun mẹwaa ati oṣu mẹjọ ni Tanioluwa n ṣe.

Lẹyin ti wọn ko kuro nibi aaye alaini ti wọn wa, o ti kọ iwe itan igbe aye rẹ to pe akọle rẹ ni ''My Name Is Tani . . . and I Believe in Miracles.''

Trevor Noah adẹrinposonu nii ni ireti wa pe yoo gbe ẹda itan naa jade nileeṣẹ sinima rẹ ti ilumọọka onkọtan ere itage to ba wọn lọwọ ninu fiimu The Pursuit of Happyness Steven Conrad naa yoo pawọpọ pẹlu wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images