Oyo LG Polls: Ẹgbẹ́ òṣèlú 17 ń kópa nínú ìbò ìjọba ìbílẹ̀, APC takété

Others

Iroyin sọ wi pe awọn janduku ti da ibo ru ni ijọba ibilẹ Ila-oorun Ibarapa, Ibarapa East Local Government ti o jẹ ijọba ibilẹ adari ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ, Họnọrebu Adebo Ogundoyin.

Ohun ti o ṣokunfa iwa ipanle naa ni a ko tii fi idiẹ mulẹ ni asiko ti a ko iroyin yii jọ.

Bakan naa ni ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọyọ, OYSIEC ti da ọjọ mii fun eto idibo ijọba ibilẹ Ido.

Eyi waye lẹyin ti ajọ naa fagile idibo to waye nibẹ lọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2021, nitori bi ko ṣe si ami idanimọ ẹgbẹ osẹlu ZLP lori iwe idibo.

Àkọlé fídíò,

Àìsàn jẹ́ kí àwọ̀ ara Amida dàbí ara ẹja

Ijọba ibilẹ Ido nikan ni ẹgbẹ oṣelu naa ti ni oludije fun idibo ijọba ibilẹ to waye.

Ọjọ Aiku, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Karun-un ni idibo yoo waye ni ijọba ibilẹ naa.

Ṣaaju ni alaga ajọ OYSIEC, Aarẹ Isiaka Olagunju ti tọrọ aforiji pe aṣiṣe lati ọwọ ajọ naa lo fa ifasẹyin naa.

Gẹgẹ bi ohun ti alaga ajọ naa, Aarẹ Abiọla Ọlagunju sọ lori redio Fresh Fm 105.9 nilu Ibadan, o ni igbesẹ naa pọn dandan nitori aisi ami idanimọ ẹgbẹ oṣelu ZLP lori iwe idibo.

Oríṣun àwòrán, others

Ijọba ibilẹ Ido nikan sini ẹgbẹ oṣelu naa ti n dije ninu eto idibo to n lọ lọwọ.

Adari ajọ OYSIEC gba wi pe lootọ ni awọn ṣe aṣiṣẹ lori ọrọ naa pẹlu alaye wi pe oun ati wọn igbimọ to n ṣe akoso ajọ naa yoo gbe igbesẹ ti o tọ.

O ni aṣiṣẹ naa ki i ṣe ohun ti wọn mọọmọ ṣe nitori gbogbo eto ti wọn ṣe tẹlẹ ni lati riidaju wi pe eto idibo naa lọ lai ni aṣiṣe ninu.

Ẹwẹ, botilẹ jẹ wi pe ikede ti waye wi pe ajọ eleto idibo ti wọgile ibo ni ijọba ibilẹ naa, iroyin sọ wi pe ibo ṣi n tẹsiwaju ni ijọba ibilẹ naa titi di asiko yii.

Ijọba ibilẹ mẹtẹẹtalelọgbọn to wa nipinlẹ Oyo ti eto idibo naa ti n waye.

Gẹgẹ bi alaga fun ajọ eleto idibo nipinlẹ Oyo, OYSIEC, Amofin Isiaka Olagunju ti, ajọ naa ko ni segbe si ẹyin ẹgbẹ oselu kankan lasiko eto idibo naa.

Olagunju ni igbaradi to mọyan lori ti wa nilẹ lati ri daju pe eto idibo naa lọ ni alaafia laisi mọkaruru kankan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O salaye pe ẹgbẹ oselu mẹtadinlogun lo n kopa ninu eto idibo lati yan awọn alaga ati Kanselọ ti yoo maa dari awọn ijọba ipinlẹ to wa nipinlẹ Oyo.

Amọ saaju ni ẹgbẹ oselu APC ti kede pe, oun ko ni kopa ninu eto idibo naa nitori pe oun ko ni aaye lati gbaradi fun idibo ọhun lẹyin ti oun ti ileẹjọ to ga julọ ni Naijiria de lọsẹ kan sẹyin.

Àkọlé fídíò,

Oyo LG Polls: OYSIEC ní APC ló yẹ kò bẹ aráàlú lórí àṣìṣe rẹ̀ nípa ìbò ìjọba ìbílẹ̀

Bakan naa ni ẹgbẹ oselu APC dunkooko lati gbe alaga ajọ OYSIEC ati gomina Seyi Makinde lọ sile ẹjọ, to ba fi tẹsiwaju pẹlu eto idibo naa.

Sugbọn ajọ OYSIEC kede pe onyẹ kankan ko le yẹ eto idibo ọhun, ti oun si n tẹsiwaju nidi rẹ.

Saaju ni gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti kede pe ko ni si lilọ bibọ ọkọ ati ero lati aago mẹfa aarọ si mẹta ọsanni aarọ ọjọ Satide ti eto idibo naa n waye.

Bakan naa ni wọn kede ana ọjọ Ẹti gẹgẹ bi ọjọ isinmi lẹnu isẹ fun awọn olugbe ipinlẹ Oyo fun igbaradi eto idibo naa.

Àkọlé fídíò,

ALGON Oyo: Aleshinloye ní ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ làwọn ń tẹ̀lé, kò sì yẹ kó fa ìjà

Nigba ti BBC Yoruba tọpinpin bi eto idibo naa se n lọ si nilu Ibadan, a sawari rẹ pe wọn ti n pin awọn eroja idibo lati idaji ọjọ Satide.

Idibo bẹrẹ, awọn oludibo ko tii jade

Lati ibi eto idibo si awọn ijọba ibilẹ to n bẹ nipinlẹ Ọyọ. Idibo ti bẹrẹ ni nnkan bi aago mẹwa owurọ ni awon ibudo idibo kan.

Amọ awọn oludibo ko ti i jade ni awọn adugbo mii, bẹẹ si ni awọn kan n reti awọn ohun elo fun idibo ni awọn ikorita kan, ti akọroyin BBC Yoruba ṣe abẹwo si.

Awọn ẹgbẹ oṣelu mẹtadinlogun lo n dije ninu eto idibo naa jakejado awọn ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn to n bẹ nipinlẹ Ọyọ.