Ibrahim Attahiru burial: Alààyè rèé nípa gbèsè tí Tinubusọ pé Nàìjíríà jẹ COAS tó kú nínú ìjàmbá okọ̀ òfurufú

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Agbaọjẹ oloṣelu ni Naijiria Bola Ahmed Tinubu ti pẹlu awọn ọmọ Naijiria to n daro ọga ọmọ ogun Naijiria to padanu ẹmi rẹ ninu ijamba ọkọ ofurufu ni Kaduna.

Tinubu to fi atẹjadẹ kan sita to pe akọle rẹ ni Asiwaju n ṣe idaro Attahiru.

Ninu rẹ o sọ pe ọna kan gboogi lati ranti Attahiru ati awọn mẹwaa to ku ninu ijamba ọkọ ni ki Naijiria bori igbesunmọmi ati awọn ipenija aabo mi.

Gomina nigba kan ri nipinlẹ Eko naa ṣalaye pe''Akikanju ọmọ ogun ni Attahiru ati awọn ti wọn padanu ẹmi wọn to si ṣe pe wọn gbajumọ iṣẹ wọn lati le fi mu afojusun Naijiria gẹgẹ bi orileede wa si imuṣẹ''

O ni iku wọn jẹ ohun to banilọkanjẹ ṣugbọn ''gbese ti a jẹ wọn ni pe ki a san bantẹ wa daada ki a si rii wipe a bori igbesunmọmi ati awọn iwa ipa mii to fẹ bẹgi dina ayanmọ rere ti Naijiria ni.''

Lọjọ Abamẹta ni wọn sinku Ọgagun Attahiru ati awọn mẹwaa mi ti wọn kọwọrin pẹlu rẹ ninu ijamba ọkọ ofurufu to waye ni Kaduna.

Kaakiri si ni ọrọ ikẹdun ti n jade ni iranti awọn akikanju to lọ yii.

Àkọlé fídíò,

Àìsàn jẹ́ kí àwọ̀ ara Amida dàbí ara ẹja