Yoruba Nation: Banji Akitoye ní àbámọ̀ ni yóò kẹ́yìn ọ̀rọ̀ fáwọn aṣaájú APC nílẹ̀ Oodua

Alagba Banji Akitoye ati ami idamọ ẹgbẹ APC

Aarẹ ẹgbẹ Ilana Omo Yoruba, Ọjọgbọn Banji Akitoye ti fewe ọmọ mọ awọn asaaju ẹgbẹ oselu APC leti pe wọn yoo kabamọ bi wọn se takete si idasilẹ orilẹede Yoruba.rilẹ́

Ọjọ Aje ni Akitoye sekilọ yii fawọn asaaju ẹgbẹ oselu APC nilẹ Kaarọ Oojire, ti wọn ni awọn fara mọ pe ki orilẹede Naijiria wa ni ọkansoso, ti wọn si takete si idasilẹ Yoruba Nation.

Nigba to n sọrọ lori ipinnu awọn asaaju naa nibi ipade apero wọn to waye lọjọ Satide, Alaga fun ẹgbẹ Ilana Omo Yoruba naa ni ipinnu ti ko dara ni APC se.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"O ti foju han gbangba pe awọn asaaju APC nilẹ Yoruba naa yoo ge ika jẹ lori ipinnu wọn lati kọ ẹyin si idasilẹ orilẹede Yoruba.

Àkọlé fídíò,

A ti ń fẹ́ Hausa, Ibo, ó sàn ka jọ ṣe é ní tùbí-ǹ-nùbí lórí ọ̀rọ̀ Nàìjíríà ju ìjà ogun lọ - Ọba Alara

Adura mi ni pe nigba ti wọn ba n kabamọ lori ipinnu wọn naa, wọn yoo le ni igboya lati tun ara wọn pe pada si ookan aya awọn ọmọ Yoruba ati ireti wọn."

Bẹẹ ba gbagbe, saaju ni ẹgbẹ Ilana Omo Yoruba ti fesi lori ipinnu awọn asaaju ẹgbẹ APC naa pe itan ko ni sọ ohun to dara nipa wọn.

Tinubu, Bisi Akande, ìtàn kò ní sọ rere nípa yín- Ẹgbẹ́ Ilana Oodua yarí

Oríṣun àwòrán, Facebook/Asiwaju Bola Tinubu

Bi awuyewuye ti n lọ lori ọrọ awọn to n pe fun ki iran Yoruba yapa kuro lara orilẹede Naijiria, awọn ẹgbẹ Ilana Oodua ti kilọ fun eekan ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu.

Ẹgbẹ naa kilọ pe itan ko ni sọ daadaa nipa Aṣiwaju Bola Tinubu atawọn eekan oṣelu nilẹ Yoruba mii ti wọn tako pipe fun Odua Nation.

Lọjọ Aiku to lọ ni Tinubu ati Gomina ipinlẹ Osun tẹlẹ, Oloye Bisi Akande atawọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC ṣepade nibi ti wọn tako pipe fun orilẹede iran Yoruba.

Tinubu sọ nibi ipade naa pe oun atawọn to wa nibi ipade naa fọwọ si atunto Naijiria ati fifi ofin de dida maalu kiri ni gbangba.

Ṣugbọn ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu awọn akoroyin, agbẹnusọ Ilana Oodua, Maxwell Adeleye, sọ o ṣenu pe Tinubu tako pipe fun Odua Nation.

O ṣalaye pe awọn Yoruba ko pe fu ki Naijiria ko daru, amọ wọn fẹ da duro ni eyi to ba ofin ajọ iṣọkan agbaaye ati iwe ofin orilẹede Naijiria mu.

''Ẹtọ wa ni lati sọ pe a fẹ da duro gẹgẹ bi ẹya Yoruba.

Oun to ba wu Tinubu ati awọn mii ni wọn le maa sọ kiri, ti ẹ ba dibo lori ọrọ yii ni ẹ o mọ pe ọpọ ọmọ ilẹ Yoruba lo fẹ daduro.

O ṣeni laanu pe Oloye Akande naa wa nibi tawọn eeyan kan ti n tako ati da orilẹede Yoruba silẹ,'' Adeleye ṣalaye.

O ni ohun ti ko ye Tinubu ati Akande ni pe lai si awọn eeyan, wọn ko le wa ni ipo aṣaaju ti wọn wa.