Jeleosinmi Art Centre: Ibùdó yìí ló ń tọ́ ọ̀dọ́ sọ́nà nípa iṣẹ́ ọnà àti àṣà dípò ìwà àìda

Jeleosinmi Art Centre: Ibùdó yìí ló ń tọ́ ọ̀dọ́ sọ́nà nípa iṣẹ́ ọnà àti àṣà dípò ìwà àìda

Oniruuru awọn ibudo ikẹkọ lo wa paapaa fun awọn ogo wẹẹrẹ, lara rẹ ni ibudo Jeleosinmi tawọn ọmọde ti maa n kọkọ ẹkọ iwe.

Amọ ibudo ikẹkọ Jẹleosinmi ti Abolore Sobayo da silẹ yatọ nitori o n kọ awọn ọdọ ni ede Yoruba ati isẹ ọna lapapọ.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori idi to fi da ibudo naa silẹ, Sobayo ni ọpọ ọdọ lo n fi ẹsẹ gbalẹ kiri, ti esu si n bẹ wọn nisẹ, lo mu ki oun da ibudo ti wọn yoo ti kọ nipa isẹ ọna ati asa wa silẹ.

O fikun pe ọna lati fi pada fun awujọ ti oun ti jade wa, eyiun Oshodi, lo mu ki oun gbe ibudo jẹleosinmi naa kalẹ sibẹ.

Ni ibudo yii si ni awọn ọdọ ti n kọ nipa oniruuru ara ti wsn le fi isẹ ọna da ati ọpọ ohun to jẹ mọ asa wa nilẹ Yoruba.

Sobayo wa rọ awọn obi lati maa kọkọ fi ede abinibi kọ awọn ọmọ wọn nitori ko si anfaani ninu ki ọmọ wa ma gbọ ede wa.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: