Travelogue on Abeokuta: Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún yònbó ìbùdó àti èèyàn pàtàkí tó wà ní Abeokuta

Travelogue on Abeokuta: Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún yònbó ìbùdó àti èèyàn pàtàkí tó wà ní Abeokuta

Yoruba ni ọmọ ti yoo ba jẹ Asamu, kekere ni yoo ti maa jẹnu samusamu.

Asamu ọmọ si la le pe Grace nitori bo se n jẹnu samusamu lati yonbo ilu abinibi rẹ, Abeokuta, to si salaye yekeyeke nipa awọn ibudo pataki to wa nilu naa.

Lara awọn ibi manigbagbe ti Grace mẹnuba ni Apata Olumo, Aafin Alake tilẹ Egba, Gbọngan ti wọn fi sami ọgọrun ọdun ti wọn tẹ Abeokuta do ati ile ijọsin onigbagbọ akọkọ to wa nilu naa.

Bakan naa ni Grace, tii se ọmọ ọdun mẹẹdogun, tun sọ awọn ibudo igbafẹ atawọn eeyan pataki to jẹ ọmọ bibi ilu Abeokuta.

Ko tan sibẹ, ọmọde yii tun sọ nipa itan bi wọn se da ilu naa silẹ ati awọn eeyan jankanjankan to ti se ribiribi fun agbaye, ti wọn jẹ ọmọ bibi ilu Abeokuta.

Lara awọn to mẹnuba ni Ọjọgbọn Wole Soyinka, Oloye Olusegun Obasanjo, Fela Anikulapo Kuti, Oloye MKO Abiola, Ernest Sonekan ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Grace wa ke sawọn onile ati alejo pẹlu awọn eeyan lagbaye to n wa ibi igbafẹ ti wọn fẹ lọ, paapaa awọn ọdọ lati wa silu Abeokuta.

Koda, o fikun pe wọn yoo ge ahọn jẹ ti wọn ba fi ẹnu kan irẹsi Ọfada ati amala Lafun, tii se ounjẹ ibilẹ wọn nilu Abeokuta.

Itan aye awọn ọmọ bibi ilu Abeokuta to laami laaka ni agbaye: