Abuja Cholera Outbreak: Ìjọba ní gbogbo agbègbè tó wà ní Abuja ní Kọ́lẹ́rà dé

Awọn eeyan to n gba itọju nile iwosan

Oríṣun àwòrán, Ministry of Health

Iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii ti fidi rẹ mulẹ pe arun onigbameji ta ms si Kọlẹra, tun ti gbode ni olu ilu ilẹ wa Abuja.

Oludari ẹka eto ilera araalu fun ilu Abuja, Dokita Sadiq Abdulrahman fidi rẹ mulẹ fun BBC lasiko ifọrọwanilẹnuwo pe eeyan mẹrindinlaadọrin lo ti jade laye lati ipasẹ arun naa.

Bakan naa lo fikun pe ajalu arun Kọlẹra naa ni ọwọja rẹ ti tan de ẹkun mẹfẹẹfa to wa nilu Abuja gẹgẹ bi ayẹwo ti wọn n se fawọn araalu se fidi rẹ mulẹ.

"Lati ọjọ Kinni osu Karun ọdun 2021, la ti n ri ami pe arun yii n bọ, amọ a ko le fidi rẹ mulẹ titi di igba to n mu awọn araalu, ti ayẹwo wa si fidi rẹ mulẹ pe arun onigbameji ni.'

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Abdulrahman ni titi di ana Ọjọbọ, ọjọ kejilelogun osu Keje, eeyan bii ọrinlelẹgbẹrin o din meje, 873 , ni awọn le fidi rẹ mulẹ pe o ti ni arun Kọlẹra naa.

"Ọwọja arun yii ti tan de gbogbo agbegbe to wa nilu Abuja. Ni agbegbe AMAC, eeyan marundinniirinwo, 395, lo ti ni arun naa nigba ti ojilenirinwoati mẹfa, 246, ni arun ọhun ni agbegbe Gwagwalada.

Àkọlé fídíò,

Travelogue on Abeokuta: Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún yònbó ìbùdó àti èèyàn pàtàkí tó wà ní Abeokuta

Eeyan marunlelaadọjọ, 152 lo ni Kọlẹra ni Bwari, ti eeyan ogoji, 40, si ni ni Kuje nigba ti eeyan mẹtadinlogoji, 37 ni ni Kwali.

Amọ eeyan mẹta pere lo ni Kọlẹra ni Abaji."

Dokita naa ni iwadi awọn ti fidi rẹ mulẹ pe ọwọja arun naa n tan kalẹ nitori bawọn eeyan se n pọ si nilu Abuja amọ aayan ti n lọ lati kawọ rẹ ko.

"A ti gbe oniruuru igbimọ kalẹẹ labẹ awọn ileesẹ ti ọrọ ilera yii kan lati gbogun ti arun Kọlẹra nilu Abuja, tawọn osisẹ wa si n lọ kaakiri lati abule si ileto lati sayẹwo omi ti wọn n mu.

Bakan naa lati ti se ifilọlẹ ẹka pajawiri ti yoo maa se itọju awọn alaisan Kọlẹra, gẹgẹ ba se maa n se ti arunkarun kan ba bẹ silẹ."

Àkọlé fídíò,

Rashidi Ladoja: Ẹ jẹ́ kí Bùhárí gbá'pòtí ìbò, bóyá yóò borí