Blessing Okagbare at Tokyo 2020 Olympics: Àjọ eré ìdárayá lágbáyé lé Blessing Okagbare kúrò ní Tokyo 2020 Olympics

blessing okagbare

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ajọ to nboju wo ayẹwo ogun lilo laarin awọn elereidaraya ti paṣẹ lọ rọọkun nile naa fun eekan elere ije ọlọgọrun mita(100 meters) ati igba mita ( 200 meters) ọmọ Naijiria ni, Blessing Okagbare nibi idije Tokyo 2020 Olympics to n lọ lọwọ bayii lorilẹede Japan.

Ọpọ ọmọ Naijiria ti inu wọn n dun lọjọ Ẹti lori iroyin pe elere ije ọmọ Naijiria meji lo moribọ wọ ipele to kangun si aṣekagba ere ije onimita ọgọrun ni idunnu naa ko pẹ fun pẹlu iroyin pe ayẹwo fihan pe Okagbare to jẹ ọkan ninu awọn meji naa lo ogun amuṣẹya HCG eleyi to jẹ ara awọn ogun ti ajọ naa fi ofin de pe kawọn elere idaraya jina sii.

Àkọlé fídíò,

Bí ìjọba bá kọ̀ tí kò ṣèdájọ́, tí Ọlọ́pàá kọ̀ pé àwọn kọ́ ló paá, ẹni tó pa ọmọ mi, náà máa ...

Bi ẹ ko ba ni gbagbe lọjọ diẹ sẹyin lawọn ajọ yii kan naa yọ awọn elere idaraya ogun bi ẹni yọ jiga lori ẹsun pe wọn eto ayẹwo ogun oloro ti wọn ṣe fun wọn ko kun oju iwọn to yẹ fun elere idaraya to fẹ kopa ni idije agbaye bii Olympics. Mẹwaa ninu awọn elere idaraya naa lo jẹ ọmọ orilẹede Naijiria.

Blessing Okagbare jẹ ọkan gboogi ireti orilẹede Naijiria lati ri ami ẹyẹ gba ni idije Tokyo 2020 Olympics.

Ni idije Olympics ti ọdun 2008 ni Beijing lorilẹede China, Okagbare gba ami ẹyẹ Fadaka lẹyin to ṣe ipo keji ni idije ilẹ fifo ti a mọ si Long jump. Lẹyin eyi lo tun gba ami ẹyẹ miran ni idije ilẹ fifo ti a mọ si Long jump yii kan naa ati ere ije igba mita (200 meters) ni idije ere idaraya agbaye, World Championships lọdun 2013.

Àkọlé fídíò,

Igi Ọ̀pẹ abàmì tó dá ní orí 42 l'Ekiti rèé o, 'bí mo ṣe ríi l'orí mi ń dìde fììì'