AjogbaJesu Twins: Wọ́n ti kéde ètò ìsìnkú Tope AjogbaJesu àti ọjọ́ tí wọn yóò sin ín

Awọn Ibeji AjogbaJesu

Oríṣun àwòrán, Ajogbajesutwins/instagram

Awọn ẹbi Tọpẹ AjogbaJesu ti kede bi eto isinku rẹ yoo ṣe lọ o.

Ni ọjọ Ẹti ọgbọn ọjọ oṣu keje ọdun 2021 ni iroyin iku ọkan lara awọn gbajumọ akọrin ẹmi lorilẹede Naijiria Tọpẹ to jẹ Taiyelolu ibeji AjogbaJesu jade laye.

Ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria titi de oke okun si ni iku wọn ti da sinu ibanujẹ ọkan.

Awọn ẹbi Tọpẹ AjogbaJesu ti kede bi eto isinku rẹ yoo ṣe lọ o.

Ninu ọrọ to ṣe ni alaye fun BBC News Yoruba, Ọgbẹni Oyedepo Adetoyeṣe to jẹ alamojuto ọrọ iroyin ori ayelujara fun awọn Ibeji AjogbaJesu, ni awọn ẹbi akọrin ẹmi naa ti ṣalaye pe ọjọ kẹwaa oṣu kẹjọ ọdun 2021 ni wọn yoo sin olorin naa.

O fi kun un pe ọjọ kẹsan oṣu kẹjọ naa ni wọn yoo ṣe isin aṣalẹ ẹyẹ ikẹyin "Artiste night "nibi ti awọn akẹrin ẹmi atawọn oṣere yoo ti ṣe ẹyẹ ikẹyin wọn fun un.

Ta ni Tope AjogbaJesu, akọrin ẹ̀mí tó jáde láyé lọ́jọ́ Ẹtì?

Oríṣun àwòrán, other

Nigba ti awọn mejeeji wa ni ọdun mejila ni wọn ni awọn ti bẹrẹ iṣẹ orin kikọ, gẹgẹ bi awọn mejeeji ṣe sọ ninu awọn ifọrọwanilẹnuwo ti wọn ti ṣe pẹlawọn ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ kan sẹyin.

Ni ọdun 2004 ni awo orin to gbe wọn saye, ti wọn pe akọle rẹ ni "Winner" jade sori atẹ.

Lara awọn olorin ti wọn ni awọn Ibeji AjogbaJesu ṣalaye pe o ko ipa ribiribi ninu aye ati iṣẹ orin wọn ni awọn agba akọrin bii Funmi Aragbaiye, Mega 99, Sẹnwẹlẹ Jesu ati Esther Igbẹkẹle.

Nipasẹ Iya awọn ni wọn ṣe ri orukọ AjogbaJesu ti wọn n jẹ nitori bi Mama ṣe kundun ijo jijo paapaa to ba ti niiṣe pẹlu ti Ọlọrun ati iṣẹ isin rẹ. Ninu eyi lawọn ọmọ ti mu orukọ inagijẹ orin wọn.

Àkọlé fídíò,

Bí ìjọba bá kọ̀ tí kò ṣèdájọ́, tí Ọlọ́pàá kọ̀ pé àwọn kọ́ ló paá, ẹni tó pa ọmọ mi, náà máa ...